Ni 1965, wọn fẹẹ yọ Awolọwọ kuro ẹwọn, ṣugbọn awọn ẹgbẹ Dẹmọ ni afi ko tọwọ bọwe apapandodo

Ka sọ tootọ, Oloye Samuel Ladoke Akintọla, olori ijọba Western Region, mọ pe ibo ti wọn fẹẹ di ni 1965 ko le dara fẹgbẹ oun. O mọ bẹẹ ni. Idi ni pe oun paapaa mọ pe gbogbo aye lo koriira ẹgbẹ Dẹmọ, iyẹn ẹgbẹ ti oun n ṣe olori rẹ, ẹgbẹ to si fẹẹ fi du ipo olori ijọba lẹẹkeji. Ikorira yii pọ debii pe awọn araalu ki fẹẹ pe ara wọn ni ọmọ ẹgbẹ naa, bẹẹ, yatọ si awọn olowo ati alagbara oloṣelu, ko pọ ninu mẹkunnu ilu ti i jade si gbangba pe ẹgbẹ Dẹmọ loun n ṣe. Sibẹ naa, ẹgbẹ yii ni Akintọla mura lati fi du ipo, ẹgbẹ yii lo mura pe yoo gbe oun wọle lẹẹkan si i gẹgẹ bii olori ijọba West. Ohun to fa a niyi to jẹ lẹyin ti wọn ti dibo apapọ tan ni 1964, ti wọn si ti tun fi ibo naa gbe Balewa wọle, ibo to ku ti gbogbo Naijiria ranju mọ ni ibo Western Region, nitori wọn fẹ wọn kọ, lọdun naa ni wọn gbọdọ dibo naa dandan.

Ki lawọn Akintọla wa fẹẹ ṣe ti yoo gbe ẹgbẹ Dẹmọ niyi! Ko sohun ti wọn yoo ṣe ju ki wọn wa ọna lati fa oju ọpọ araalu mọra lọ. Ọlọrun si ba wọn ṣe e, ọrọ kan wa niluu to n ja ran-in ran-in nigba naa, ọrọ nipa Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lẹwọn ni. Awọn aṣaaju ọmọ Yoruba ti wọn wa lẹyin Akintọla mọ pe ko sohun ti yoo dun mọ gbogbo Yoruba ninu ju ki wọn yọ Awolọwọ jade lẹwọn lọ. Wọn mọ pe ti wọn ba yọ Awolọwọ jade lẹwọn, gbogbo ilu yoo fẹran wọn, nitori wọn yoo ni awọn ni wọn ṣe Awolọwọ loore. Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin ti awọn Moses Adekoyejọ Majẹkodunmi da silẹ ti bẹrẹ iṣẹ lori eyi, ṣugbọn awọn eeyan ko gba wọn gbọ, sibẹ wọn mura si kinni naa kankan. Wọn ni iṣẹ kan ṣoṣo to wa niwaju awọn bayii ni ki awọn yọ Awolọwọ jade lẹwọn, nitori awọn ko fẹ wahala nilẹ Yoruba mọ, awọn n wa iṣọkan to dara gan-an ni.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group bIi Bọla Ige ati Bisi Ọnabanjọ ti sọ pe awọn ko fẹ oore ti awọn ẹgbẹ Ọlọfin fẹẹ ṣe, wọn ni ṣebi Majẹkodunmi wa ninu awọn ti wọn ṣeto bi Awolọwọ ṣe de ẹwọn, oun lo si pada gbe ijọba fun Akintọla, kin ni ko lo agbara rẹ nigba naa si, to waa jẹ lasiko yii to n ṣe minisita fun Balewa, to jẹ oun ni pataki ti awọn oloṣelu ilẹ Hausa gbojule, to si jẹ awọn oloṣelu ilẹ Hausa yii, ọta Awolọwọ gidi ni wọn, ṣe asiko yii ni yoo waa ja fun Awolọwọ ko jade. Wọn ni oore ẹdẹ ni, awọn ko si fẹ iru oore bẹẹ rara. Sibẹ naa, awọn eeyan yii ko jawọ, nitori awọn mọ ohun ti wọn n wa, wọn si mọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe. Loootọ ni wọn fẹẹ gba Awolọwọ lẹwọn, ṣugbọn wọn fẹẹ sọ Awolọwọ yii di arọ, ti ko fi ni i ni agbara kankan mọ nigbakigba to ba jade. Ohun meji pataki ni wọn fẹ ki Awolọwọ ṣe.

Akọkọ ni pe wọn fẹ ki Awolọwọ sọ pe ti oun ba ti jade lẹwọn, oun ko ni i ṣe ẹgbẹ oṣelu mọ, oun o si ni i kopa ninu ọrọ oṣelu Naijiria fun igba pipẹ. Eyi ni pe ti wọn ba ti fi i silẹ to jade lẹwọn, yoo pada sidii iṣẹ lọọya to n ṣe, yoo si maa woran awọn oloṣelu ni. Boya wọn da ijọba ru tabi wọn tun ijọba ṣe, tabi boya ilẹ Yoruba n gbona nitori ọrọ oṣelu tabi o tutu, ko si eyi ti yoo kan oun Awolọwọ ti wọn ba ti yọ ọ jade lẹwọn, iṣẹ to ba n ṣe nikan ni ko gbaju mọ, ti yoo si fi awọn oloṣelu silẹ, ti wọn yoo maa ba iṣẹ tiwọn naa lọ. Lati mu ki eleyii ṣẹ, ki Awolọwọ too jade lẹwọn ni yoo ti kọwe, ti yoo si fọwọ si i, ti yoo ni oun gẹgẹ bii oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG) ti wọn n pe ni Ẹgbẹ Ọlọpẹ tu ẹgbẹ naa ka pata, ẹnikẹni ko si gbọdọ fi orukọ ẹgbẹ oṣelu naa ṣe oṣelu rẹ nibi kankan ni Naijiria mọ.

Bi eleyii ba ṣẹlẹ, idaamu gidi ni yoo ba awọn ọmọ ẹgbẹ yii, nitori ko ni i si ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn yoo fi maa ṣe oṣelu wọn, afi ki gbogbo wọn rọ lọ sinu ẹgbẹ NCNC, tabi ki wọn kuku pada sinu Ẹgbẹ Dẹmọ ti i ṣe ẹgbẹ Akintọla. Bi Awolọwọ ba ti fọwọ si i bẹẹ naa, pe oun tu ẹgbẹ Action Group yii ka, oun naa ko le ri ẹgbẹ kan ti yoo fi ṣe oṣelu, ka tilẹ sọ pe o fẹẹ ṣe e, wọn yoo kan ja a si okolombo ni. Eleyii ni wọn mu ni ọkunkundun fun un, awọn aṣaaju ẹgbẹ Ọlọfin, paapaa Adekoyejọ Majẹkodunmi, ẹni to da bii aṣoju fun Adajọ agba Adetokunbọ Ademọla ninu gbogbo ọrọ yii, si n sọ pe bi Awolọwọ ba ti gba eleyii ti awọn n wi yii, pe oun ko ni i ṣe oṣelu mọ, oun yoo si tu ẹgbẹ AG ka, ki wọn da gbogbo iṣẹ to ku da oun, oun yoo ri i pe ijọba Balewa dari ji Awolọwọ, wọn yoo si yọ ọ lẹwọn kia, yoo maa ba aye rẹ lọ.

Ohun keji to tun gbọdọ ṣe jẹ lati tu ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ka, ko ni i si ohun to n jẹ ẹgbẹ naa mọ, ẹgbẹ kan ṣoṣo ti yoo wa ni ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin. Wọn ni bi Awolọwọ ba jade, ti oun naa ba fẹ, o le wọ inu ẹgbẹ yii, nitori ẹgbẹ kan ṣoṣo ti yoo wa fun gbogbo Yoruba niyi, ẹgbẹ ti ko ni i jẹ ẹgbẹ oṣelu, ti ko si ni i ba wọn da si oṣelu, ti yoo kan jẹ ẹgbẹ idagbasoke ilẹ Yoruba nikan. Wọn ni ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ti di ẹgbẹ oṣelu, oun ni wọn fi ṣe ipilẹ ẹgbẹ Action Group, bi awọn ba si pa ẹgbẹ AG rẹ ti awọn fi ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa silẹ, bii ẹni ti ko ṣe nnkan kan ni, nitori ko le pẹ ko le jinna ti ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa yoo fi tun bi ẹgbẹ oṣelu mi-in, o si ṣee ṣe ko le ju ti tẹlẹ lọ. Wọn ni fun alaafia ati ifọkanbalẹ ni ilẹ Yoruba, Awolọwọ yoo pa Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa to jẹ olori rẹ rẹ, bo ba si ti jade, bo ba jẹ o fẹẹ ṣe ẹgbẹ kan, yoo maa bọ ninu ẹgbẹ ọmọ Ọlọfin.

Iṣẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọfin mura si ti wọn n ṣe ree, wọn si ni awọn yoo yanju ọrọ naa laipẹ, bi Awolọwọ ba ti gba ohun ti awọn wi. Ṣugbọn awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ ko gba, wọn ni ọrọ to wa nilẹ yii ko le, bo ba jẹ ohun ti wọn fẹ niyi, a jẹ pe bi wọn ba ti  pa ẹgbẹ Action Group rẹ, ki wọn maa pa ẹgbẹ Dẹmọ naa rẹ ni, a jẹ pe bi ko ba ti si Action Group mọ, ko ni i si ẹgbẹ Dẹmọ naa ni. Ati pe ohun yoowu to ba fi mu un ti Awolọwọ ko ba ṣe oṣelu mọ, Akintọla naa gbọdọ kọwe fi ipo tirẹ naa silẹ, ki oun naa pa oṣelu ti, ko maa ṣe iṣẹ lọọya to mu. Wọn ni nigba naa ni awọn yoo mọ pe ẹgbẹ Ọlọfin fẹẹ pari ija, wọn si ti ṣetan lati mu iṣọkan ba ilẹ Yoruba loootọ. Ṣugbọn ki ẹgbẹ yii ni ki Awolọwọ ma ṣe oṣelu mọ, ki Akintọla si wa lori aga ijọba ko maa ṣejọba lọ, iwa ti ko dara, ti ko si yẹ ki onilaakaye eeyan kan gbe jade ni. Wọn ni bo ba jẹ ohun ti wọn fẹẹ ṣe niyẹn, ki wọn ma ka ẹgbẹ awọn tabi Awolọwọ mọ ọn.

Nibi ti awọn ti n ṣe eyi, TOS Benson to ṣẹṣẹ wọle sile-igbimọ aṣofin naa gbe ikede nla dide, o ni oun loun yoo yọ Awolọwọ jade lẹwọn, gbogbo ohun to ba gba lawọn yoo fun un. Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 1965, loun yii kọkọ kọwe jade, o kọwe naa si awọn agbaagba ẹgbẹ UPGA, o ni ohun yoowu ti wọn ba n ṣe  lọwọ, ki wọn fi i silẹ, iṣẹ  kan to ku ti ki gbogbo wọn ṣe ni lati ri i pe Awolọwọ kuro lẹwọn, awọn o si gbọdọ duro mọ rara. Ni ti TOS Benson, o ni ohun ti awọn yoo ṣe ni lati ba awọn ijọba agbegbe to ku sọrọ, ki awọn ba ijọba West, East ati ti North, pẹlu ti Mid-West sọrọ, ki wọn gbe iranlọwọ dide lati ba ijọba apapọ sọrọ, ki wọn fi Awolọwọ silẹ lẹwọn, ko le maa ba iṣẹ rẹ lọ. Oun ko sọ pe ki wọn ma jẹ ki Awolọwọ ṣe oṣelu mọ, o ni ki wọn fi i silẹ lọgba ẹwọn ni.

Asiko naa ni awọn ẹgbẹ Dẹmọ jade pẹlu ibinu nla, nigba to si jẹ bi Dẹmọ ba sọrọ, Akintọla lo sọ ọ, wọn ni bi wọn ba fẹ ki wọn fi Awolọwọ silẹ lẹwọn, dandan ni ko tọwọ bọwe, bẹẹ lo gbọdọ ṣe awọn kinni kan. Ki waa ni awọn Akintọla fẹ ki Awolọwọ ṣe ki wọn too fi i silẹ lẹwọn? Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ!

Leave a Reply