Ni bayii, ọrọ ile Oṣodi yii lo wa lọkan gbogbo wa

Mo mọ nnkan temi, mo mo bo ṣe maa n ri. Ti mo ba ti fẹẹ ṣe nnkan, to ba ti n ri bo ṣe n ri yii, mo ti mọ pe kinni naa maa bọ si i ni. Ohun to tun maa n ṣe mi lara bakan ni pe ko si ohun ti mo ni mo fẹẹ ṣe ti awọn eeyan maa ro pe n ko ni owo ti mo le fi ṣe e lọwọ. Ẹ ẹ gbọdọ ri i bi Sẹki ṣe ṣe, niṣe lo n ṣe bii pe owo yẹn ti wa lọwọ mi, to n jo silẹ, to n pariwo, o ti ṣee ṣe. Bẹẹ ni temi, ko si ohun to fẹẹ mu mi ra ile naa gan-an ju ọrọ ti Safu sọ lọ, pe ibẹ ba mi lọwọ mu, ati pe ti ẹlomi-in ba ra a, o le le wa jade nibẹ, ki oluwa ẹ ṣẹṣẹ maa wa ṣọọbu mi-in kiri.

Ohun kan ti mo maa n sa fun bi ọrọ ba ti da bayii ni ija, ori mi ki i pariwo rara. Nitori ẹ lo ṣe jẹ igba ti Aunti Sikira tun fẹẹ ba Safu ja, ti mo si mọ pe tọrọ naa ba ṣẹlẹ, yoo kan mi, mo yaa kilọ fun iyẹn pe ti mo ba gbọ ariwo kan lẹnu ẹ, mo maa fọ ọ leti ni. Niyẹn ba yaa sinmi. Gbogbo bi Aunti Sikira ṣe n leri, to n pariwo pe oun fẹẹ fi han an pe fada ni baba jẹ fọmọ, ọmọ yẹn o gbin o, o n wo ni tiẹ ni. Ohun to dun mi ni pe Alaaji to yẹ ko da Aunti Sikira nibẹẹnu, ko kilọ fun un ko yee fira ẹ wọlẹ, niṣe loun tilẹkun mọri, ṣugbọn mo mọ pe ti mo ba sọrọ, ọrọ le di temi.

Iwọ lo sọ fun ọmọ pe ko jẹ ko o ba oun sun, pe o n gbe idi sa fun ọ. O tun ni emi ni mo n kọ ọ, pe ko ma fara we emi, nitori ọrọ temi yatọ gedengbe. Gbogbo ẹ lọmọ yii kuku wa n sọ femi. Mo si sọ fọmọ pe eeyan ki i fi ibasun du ọkọ ẹ o, to ba ti jẹ ohun to fẹ ree, ko tete yaa fun un. Niyẹn ba si ni oun ti gbọ, lo ba ni ni ọjọ meji loun maa fun un, ọjo Ileya ati ọjọ keji ẹ. Oun ko ni i lọ sibi kan, oun naa ko ni i jẹ ki baba jade, Lẹyin ta a ba ti kirun ọdun tan, oun maa de e mọle ni, gbogbo nnkan to ba fẹẹ ṣe, gbogbo ere to ba fẹẹ ṣe, ko waa ṣe e foun.

Ni gbogbo igba ti mo n wi yii, Safu ti ra firisa kekere kan bayii sinu ile, ati maikroweefu to fi n gbe ounjẹ kana ninu ile wọn nibẹ. Nitori bẹẹ, o le ma de kiṣinni yẹn laarin ọsẹ kan, ọbẹ nikan lo n lọọ se nibẹ. O tun ni firiiji kekere to fi n ko ọti si fun Alaaji, ti oun naa si n ra miniraasi si i to ba fẹẹ mu. Gbogbo ile ẹ lo ti ṣe pe. Bẹẹ lo ṣe jẹ pe lọjọ ọdun ati ọjọ keji ẹ, ko jẹ ki Alaaji bọ sita. Ṣe wọn kuku ti ni ka ma ̀lọọ kirun, kaluku kirun nile ẹ ni. Bọmọ ṣe mu Alaaji mabẹ ninu ile niyẹn o. Alaaji naa to si laiki nnkan bii ifa bii ifa bẹẹ, bi iyẹn ṣe n fun un ni miliiki mu, to n fun un lẹran dindin, to n fun un ni sitaotu, to si n jẹ ko ba oun sun laimọye igba, niṣe ni inu ẹ n dun, to n ṣe faaji ẹ ninu ile.

Bi ẹnikẹni ba ti waa wa Alaaji wa, Safu lo maa dahun, o maa ni wọn n sun lọwọ. O jọ pe Aunti Sikira naa ti mura silẹ, o ti ro pe Safu maa lọ si ṣọọbu nijọ keji ọdun, nitori iyẹn naa, tiẹ wa lara ẹ, ko sigba ti ki i lọ si ṣọọbu, o le ni ki loun n ṣe nile, bo ba si lọ loootọ, yoo pa iye kan wale. Ohun ti Aunti Sikira ti fọkan si niyi, afi b’ọmọ o ṣe lọọ ṣọọbu, to tilẹkun mọ baba. Igba  temi n lọ ọdọ awọn Sẹki, mo ri aunti yẹn to ti wẹ, to wọ buresia to fi maa n ko ọmu soke bii tọmọde yẹn kiri ile, mo ti mọ pe baba lo pọn gbogbo ẹ fun, b’Alaaji ba ti le ri i, iṣẹ ọjọ naa pari niyẹn.

Ṣugbọn Safu ko jẹ ki baba yọju sita. Emi si ti jade, ọrọ rederede ki i ba ikun nile. Wọn waa ni bi Aunti Sikira ti n paara ẹnu ọna Alaaji lọ, bẹẹ lo n paara ẹ bọ. Igba mi-in, yoo maa rin kiri iwaju ibẹ, igba mi-in, yoo kan ilẹkun pe ṣe wọn ko ti i too ji naa ni, igba kan si wa to ni oun ni ọrọ pataki kan ti oun fẹẹ ba wọn sọ. Igba naa ni Safu sọ fun mi pe Alaaji da a lohun pe gbogbo ohun to ba fẹẹ sọ foun, o di ọjọ keji, nitori oun fẹẹ sinmi ni. Baba buruku. Isinmi wo lo fẹẹ sinmi, ẹni ti Safu n koṣẹ fun. Aunti Sikira naa si mọ iru ẹ, nigba to jẹ ohun toun naa n ṣe niyẹn, ohun to jẹ ki inu bi i si Safu ree.

Lọrọ kan, ko ṣẹni to foju kan Alaaji ninu ile yẹn ni Sannde, Safu jẹwọ fun gbogbo wọn pe oun niyawo kekere, oun ṣi wa loju ẹ. Amọ bi ilẹ ṣe n mọ lọjọ Mọnde, Safu ti mura ibi iṣẹ tiẹ, o kan wa soke lati waa sọ fun mi ni pe awọn ara banki ti mo ni wọn le wa mi wa laaarọ ọjọ yẹn ki n too de, ko le mọ ohun to maa sọ fun wọn bi wọn ba ṣaaju mi de. Afi bii pe Aunti Sikira ti n duro de e, o tiẹ ti n duro de e ni. Bo ṣe fo jade niyẹn, to n bi i ni kuẹṣan awọn oniwee mẹwaa, pe ki lo de to tilẹkun mọ Alaaji lanaa, ṣe o ro pe oun nikan loun ni ọkọ ni, ki i lo fẹ ki awọn to ku maa ṣe nigba ti oun mu baba to tilẹkun mọ ọn.

‘O ṣaarọ Mọnde, ẹ fi mi silẹ o, Ọlọrun o ni i di yin lọwọ o!’ Ohun ti Safu sọ niyẹn. Ohun tiẹ ti mo si gbọ ni mo fi jade, ni mo ba pariwo mọ ọn pe ti mo ba tun gbọ ohun ẹ nibẹ yẹn, mo maa fọ  ọ leti ni. Lo ba sare wa soke lọdọ mi, bo si ti ṣalaye ọrọ naa tan ni mo ni ko yaa maa lọ. Mo sọ fun un pe ẹni a ba na lara n ta, pe ṣe ko mọ ohun to n dun iyaale ẹ ni. Mo ni ko ma dahun o, ko yaa maa lọ si ṣọọbu kiakia, ko ma jẹ ki ẹnikẹni di i lọwọ iṣẹ aje ẹ. N lọmọ ba yaa n lọ. Ṣugbọn bo ṣe n lọ naa nkọ, lọjọ naa ni mo mọ pe aunti yẹn ko lojuti rara, ọmọọta kan bayii ni.

Orukọ tobinrin yẹn ko pe Safu tan lo n lọ yẹn, “Ruutu! Abọkọku! Ja-kinni-jẹ! ṣe o fẹẹ gbe e lọ ni! Wọn aa fi su ẹ! O jẹ di i mẹru lọ si ṣọọbu, Ṣaa ma pa baba fun wa o, ranti pe baba ti dagba o, nitori ki i ṣe bi awa to ku ṣe n jẹ ẹ ree o. Bo ba jẹ bi a ṣe n jẹ ẹ niyẹn, o o ni ba nnkan kan nibẹ mọ o. Ṣebi wọn ni iṣẹ lo laiki, bayii naa lo tun laiki kinni to ni!” Mo kan wa lori bankoni ti mo n rẹrin-in ni, mo mọ pe ka ni mo tu Safu silẹ fun un ni, yoo gba ṣẹnji ẹ. Ṣugbọn ohun to wa niwaju mi ko le jẹ ki n ṣe bẹẹ, kẹnikan ma ba mi fariwo le oriire mi lọ. Safu naa si mọ, nitori mo sọ fun un.

Mo ni ṣe o mọ pe awa la fẹẹ ṣe nnkan rere, bi eeyan ba fẹẹ ṣe nnkan rere, ki i pariwo o. N lọmọ yẹn ba lọ. Alaaji to yẹ ko jade ko gbeja ẹ, gbaga ni mo gbọ to tilẹkun lati igba ti Safu ti kọkọ jade lakọọkọ, gbogbo bi iyawo ẹ si ti n gbo bii aja to nibẹ yẹn, ko jade ko waa gba ọmọ yẹn silẹ lọwọ ẹ, oun si leku ẹda to da a silẹ. Emi naa ko pẹ ti mo fi yaa jade, ki wọn ma ko ba mi, nitori mo mọ pe ohun ti Safu ṣe fun Alaaji yẹn, ọjọ mẹta, ko ni i ba ẹlomi-in sun, ọmọ yẹn ti leri bẹẹ fun mi. Ohun to jẹ ko tilẹkun gbaga niyẹn. Inu temi dun pe Ọlọrun ti ba mi le eṣu lọ, nitori ohun rere kan ki i fẹ ka ṣe ohun, eeyan ni yoo mọ iwọn ara ẹ, ọrọ ile Oṣodi yii lo wa lọkan gbogbo wa.

Leave a Reply