Ni Iragbiji, awọn adigunjale kọlu banki Wema

Florence Babaṣọla
Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii fidii rẹ mulẹ pe awọn adigunjale n pitu ọwọ wọn lọwọ ninu banki Wema to wa niluu Iragbiji nijọba ibilẹ Boripẹ nipinlẹ Ọṣun.
A gbọ pe awọn eeyan naa ṣi wa ninu banki ọhun ti ko jinna si aafin Aragbiji tiluu Iragbiji, lọwọlọwọ bayii.
Alukooro ajọ Sifu Difẹnsi l’Ọṣun, Daniel Adigun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Ẹkunrẹrẹ nbọ laipẹ.

Leave a Reply