Ni itẹsiwaju lati yan igbakeji rẹ, Tinubu lọ si orileede France

Ọrẹoluwa Adedeji
Ni itẹsiwaju ifikunlukun lori ẹni ti yoo lo gẹgẹ bii igbakeji aarẹ ninu eto idibo to n bọ, oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti fi orileede Naijiria silẹ lọ si ilẹ France bayii.
Idaji ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, la gbọ pe Tinubu tẹ ọkọ leti lọ si orileede France. Wọn ni irinajo yii ni i ṣe pẹlu ati ba awọn alatilẹyin rẹ to wa ni orileede naa fikunlukun lori ọrọ igbakeji rẹ ti wọn ni wọn ko ti i mọ ẹni ti wọn fẹẹ mu gẹgẹ bi iweeroyin Vanguard ṣe gbe e jade.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Tunde Rahman, fọwọ si lo ti sọ pe o lọ si ilu Paris, lorileede France, fun awọn ipade pataki kan, yoo si pada si Naijiria laipẹ jọjọ.
Lẹyin to ṣepade pẹlu Aarẹ Buhari tan la gbọ pe o tẹ ọkọ leti lọ si irinajo .

Leave a Reply