Ni Kaduna, awọn agbebọnrin tun paayan mọkanla, wọn dana sun’le rẹpẹtẹ

Faith Adebọla

 Iṣoro aabo to n ba ipinlẹ Kaduna finra tun ru soke lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee yii, pẹlu bawọn janduku agbebọrin ṣe ya bo ṣọọṣi Assemblies of God, to wa laduugbo Ungwan Gaida, niluu Kurmin Kaso, wọn ṣina ibọn bolẹ, eeyan mọkanla ni wọn pa nifọnna ifọnṣu.

Mẹjọ ninu awọn oloogbe naa jẹ awọn olujọsin ti wọn n gbe ninu ọgba ileejọsin ọhun, nigba tawọn mẹta jẹ awọn araalu, wọn nibi ti wọn ti n sa kijokijo ni wọn ti yinbọn mọ wọn.

A gbọ pe lẹyin tawọn agbebọn naa pa awọn to doloogbe yii tan ni wọn bẹrẹ si i wọn epo bẹntiroolu sawọn ile to wa laduugbo naa, ti wọn si dana sun wọn.

Kọmiṣanna fun ọrọ abẹle ni Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn agbofinro ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti n tọpasẹ awọn agbebọn naa.

Lara awọn to pade iku ojiji naa, bi kọmiṣanna naa ṣe wi, ni Samaila Gajere, Bawa Gajere, Gideon Bitrus, Samuila Kasuwa, Bitrus Baba, ati Solomon Samaila.

O sọ ninu atẹjade kan to fi lede lori iṣẹlẹ ọhun pe Gomina Nasir El-Rufai bawọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn ninu akọlu yii kẹdun, o si ṣeleri pe ijọba maa ṣe gbogbo ohun to yẹ lati bori akọlu awọn janduku agbebọn nipinlẹ ọhun.

Leave a Reply