Nibi ija agba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, eeyan  marun-un ku, ọlọpaa ko mẹwaa ninu wọn n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ti mu eeyan mẹwaa nibi ija agba laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji, Ẹiyẹ ati Aiye, niluu Ilọrin, ti awọn marun-un si ti dero ọrun lẹnu ọjọ mẹta ti ija naa bẹrẹ.

Ileesẹ ọlọpaa sọ fun ALAROYE pe ni bii, ọjọ mẹta sẹyin ti ija naa ti bẹrẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mejeeji ọhun lawọn ti n gbe oku lawọn agbegbe bii Opopona ile Ọba (Emir’s road), Ita- Kudimọ, Akerebiata, to jẹ arin gbungbun Ilọrin, bakan naa ni awọn ti mu mẹwaa ninu awọn ọmọ ẹlẹlẹgbẹ okunkun naa.

O fi kun un pe laaarin ọjọ kọkandinlọgbọn, osu kẹfa, si ọjọ keji, oṣu keje ti a wa ninu rẹ naa ni awọn ikọlu ọhun waye.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa, paapaa ju lọ, awọn eeyan Ilọrin, lati fọwọ sowọ pẹlu ẹsọ alaabo lati gbe igbesẹ kiakia, ki ọrọ a n rẹ ra ẹni danu bii ila yii le wa so pin. O ni ọlọpaa nikan ko le da a ṣe, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ki i ṣe ẹmi airi, awujọ eniyan naa ni wọn n gbe, fun idi eyi, bi awọn eniyan ba ti kẹẹfin iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn maa fi to awọn ẹsọ alaabo létí.

Leave a Reply

%d bloggers like this: