Nibi tawọn afurasi ọdaran yii fara pamọ si, lọwọ ajọ NSCDC ti tẹ wọn l’Omu-Aran   

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Akolo ajọ ẹọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ni awọn afurasi ọdaran yii, Olanrewaju Adesoye, a.k.a Konfu, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Isaac Abraham, a.k.a Akube, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Tọpẹ Fadeyi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ati Abdulateef Wasiu, ẹni ọdun mẹtadinlogun wa bayii. Ni ibuba wọn ti wọn fara pamọ si ni wọn ti ko wọn niluu Omu-Aran, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ NSCDC, ẹka tipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti alaye pe lasiko ti oṣiṣẹ ajọ naa n yide kiri ni wọn kan awọn afurasi ọdaran ọhun ni ibuba wọn pẹlu ibọn ilewọ agbelẹrọ meji lọwọ wọn, toun ti ọta ibọn marun-un atawọn egboogi oloro, awọn oogun abẹnugọngọ ati ẹrọ ibanisọrọ mẹfa lọwọ wọn.

Adari ajọ ẹọ naa ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, ti ni ki wọn ṣe iwadii lẹkun-unrẹrẹ lori awọn afurasi ọhun, ki wọn si wa awọn to sa lọ lawaari ti obinrin n wa nnkan ọbẹ.

Leave a Reply