Nibi tawọn afurasi yii ti fẹẹ tun mọto Oluṣesi ti wọn ji gbe kun sọda mi-in lọwọ ti tẹ wọn l’Abẹokuta

 Gbenga Amos, Ogun

Ooyi gidi ni wọn lo kọkọ da bo ọkunrin onimọto kan, Oluṣesi Akingbile, ẹẹmẹwaa lo n fọwọ bọju boya oju aye loun wa aboun n lalaa ni, nigba to de ibi to paaki ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Carina E rẹ si lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ti ọkọ naa ti poora bii iso kilẹ ọjọ keji too mọ, iwaju ile ẹ to wa laduugbo Ijẹmọ, nigboro Abẹokuta ni wọn ti i ji i gbe lọ tefetefe, amọ lẹyin bii oṣu kan ti wọn ti n wa dukia yii, ọwọ tẹ awọn mẹta to ṣiṣẹẹbi naa, ibi ti wọn ti n pa kadara ọkọ naa da lọwọ l’Abule Mẹko, iyẹn ọgba ti wọn ti n tun ọkọ ṣe l’Abẹokuta lọwọ ti tẹ wọn, wọn si ri ọkọ ayọkẹlẹ naa gba pada.

Orukọ awọn firi-nidii-ọkẹ, alọ-kolohun-kigbe ẹda naa ni, Moses Adewale Abiọdun, Ṣeyi Oyenẹkan ati Mọnsuru Majẹkodunmi.

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe f’ALAROYE nipa iṣẹlẹ yii, o ni gbara ti wọn ti ji ọkọ ayọkẹlẹ naa, ti onimọto ọhun si ti lọọ fẹjọ sun lẹka ileeṣẹ ọlọpaa Oke-Itoku, lawọn ti fi i to gbogbo awọn agbofinro leti pe ki kaluku wọn bẹrẹ si i fimu finlẹ, ki wọn si maa ṣọ ọkọ ayọkẹlẹ to pe nọmba rẹ ni AAB 576 TF  ọhun, iwakuwaa ṣaa n wa ohun to ba sọnu.

Wọn ti wa mọto yii titi, wọn o ri i, ki awọn ọlọpaa ẹka ti Kemta too taju kan-an ri ọkọ ọhun ninu ọgba awọn mẹkaniiki to wa lọna Ajebọ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, lasiko ti wọn n ṣe patiroolu kiri titi lọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla yii, ni wọn ri i, Moses lo wa a wọbẹ, ibi ti wọn ti n ṣa ọkọ si wẹwẹ lo gbe e lọ, ni wọn ba mu un.

Ni teṣan ọlọpaa, nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo, Moses ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, loootọ ni mọto naa ki i ṣe toun, awọn ji i ni, ṣugbọn ki i ṣe oun nikan o, awọn meji mi-in wa tawọn jọ n ṣiṣẹ adigunjale, o darukọ Ṣeyi ati Mọnsuru, o si juwe ile wọn ati ibi ti wọn maa n jẹ si, ni wọn ba lọọ ko wọn.

Nigba tawọn ọlọpaa n ba iwadii lọ, wọn tun ri ọkọ Toyota Carina E mi-in ti nọmba rẹ jẹ AAA 565 GJ lakata wọn,  ọda buluu ni wọn kun ọkọ naa si, wọn lawọn ji eleyii naa ni.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣewadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii, kawọn le tete rọ wọn da siwaju adajọ fun sẹria to ba tọ si kaluku wọn.

Leave a Reply