Nibi tawọn ajagungbalẹ ti n da awọn eeyan laamu labule kan l’Ewekoro lọwọ ọlọpaa ti ba mẹsan-an ninu wọn

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Biba ni wọn ni awọn ajagungbalẹ ya bo abule Agbogun, nijọba ibilẹ Ewekoro, nipinlẹ Ogun, lọjọ Satide to kọja yii ti i ṣe ọgbọnjọ oṣu kin-in-ni, ọdun 2021. Nibi ti wọn ti n gbowo lọna aitọ lọwọ awọn to n kọle lọwọ lawọn ọlọpaa ti de, wọn si ri mẹsan-an mu ninu wọn.
Awọn tọwọ ba naa ni: Gbenga Ọdẹniyi, Owolabi Shobayọ, Micheal Ramọni, Idowu Dauda, Fẹmi Fadahunsi, Rasmus Hammed, Ade Lukman, Yakubu Akinwande ati Sikiru Balogun.
Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe ṣalaye, o ni Baalẹ Abule Agbogun lo pe teṣan ọlọpaa Ọbada Oko, pe awọn ajagungbalẹ ti wọn wa lati Ifọ, Atan, Gasline ati Sango ti ya bo abule oun, wọn ba awọn eeyan ja, bẹẹ ni wọn n gbowo lọwọ awọn to n ṣiṣẹ ile lọwọ.
Ipe yii lo mu DPO Ọbada Oko, CSP Bernard Ediagbonya, ko awọn ikọ rẹ lẹyin lọ si abule yii, nibẹ ni wọn si ti ba awọn ajagungbalẹ naa ti wọn n fagidi gbowo lọwọ obinrin kan, Oniyide Fọlashade, ati obinrin mi-in ti wọn pe orukọ ẹ ni Abilekọ Agbogun.
Iṣẹ ile lawọn iya naa n ṣe lọwọ ni saiti wọn ti awọn ajagungbalẹ yii fi de, ti wọn si ni afi kawọn gbowo lọwọ wọn dandan bi wọn ba fẹẹ ri ohunkohun ṣe lori ilẹ wọn.
Nibi ti wọn ti n daamu awọn iya onile naa lawọn ọlọpaa ti de, kia lawọn ajagungbalẹ naa fere ge e bi wọn ṣe ri wọn, ṣugbọn awọn mẹsan-an tọwọ ba yii ko mori bọ, ọwọ ọlọpaa to wọn.
CP Edward Ajogun ti ni ki wọn wa awọn to sa lọ naa ri, o si kilọ fawọn ajagungbalẹ pe ki wọn fi ipinlẹ Ogun silẹ, nitori ibi ki i ṣe ile wọn.

Leave a Reply