Nibi tawọn eleyii ti n jale loru ni wọn ti mu wọn ni marose Ṣagamu s’Ekoo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta                  

  Ni nnkan bii aago kan aabọ oru Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keji, yii, lọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọkunrin meji yii ni Ṣagamu Interchange.

Wọn n da awọn to n rin irinajo oru lọna lọwọ ni ikọ ọlọpaa ka wọn mọ, orukọ wọn ni Solomon Aghofure, ẹni ọgbọn ọdun, to jẹ ọmọ ipinlẹ Delta, ati Emmanuel Matthew, ẹni ọdun mẹtadinlogoji to wa lati ipinlẹ Abia.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe ṣalaye pe awọn ikọ adigunjale yii ti pin ara wọn kaakiri agbegbe naa, nitori marun-un ni wọn.

Nibi ti wọn duro si ni wọn ti ri mọto ọlọpaa to n bọ lọọọkan, ni wọn ba yinbọn si wọn.

Bawọn ọlọpaa naa ṣe doju ibọn kọ wọn niyẹn, ti ibọn ba ọkan ninu wọn. Ibọn ba ọlọpaa kan naa lẹsẹ, niṣe ni wọn sare gbe e lọ sọsibitu fun itọju.

Eyi ti ibọn ọlọpaa ba ni wọn kọkọ ri mu, awọn yooku sa wọgbo lọ, wọn si fi bọọsi ti wọn gbe wa silẹ. Awọn agbofinro paapaa ko fi wọn lọrun silẹ, wọn tu gbogbo igbo naa yẹbẹyẹbẹ ni ọwọ wọn tun fi ba ẹni keji, ti awọn mẹta si sa lọ raurau.

Nigba ti wọn n ṣalaye fọlọpaa, awọn meji yii sọ pe Uche ti inagijẹ n jẹ ‘Two million, Arinze ati Uzor ni awọn mẹta to sa lọ.

Wọn fi kun un pe awọn mẹta to sa lọ naa ti ṣẹwọn ri ni Okitipupa, nipinlẹ Ondo, ati ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun. Wọn ni nigba ti wọn de ni wọn da ikọ adigunjale silẹ, ti wọn si n ṣoro kiri.

CP Edward Ajogun gboriyin fawọn ikọ ọlọpaa to ṣiṣẹ yii, bẹẹ lo ni ki wọn ri i daju pe wọn ri awọn mẹta to sa lọ naa mu.

Bakan naa lo ni bawọn araalu ba kofiri ẹni to gbe ọgbẹ ibọn wa si ọsibitu tabi ile iwosan ibilẹ fun itọju, ki wọn tete fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ko ma lọọ jẹ lara awọn atilaawi to sa wọgbo lọ naa ni.

 

Leave a Reply