Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, lọwọ ba awọn ọkunrin mẹta yii nibi kan ti wọn n pe ni Ajeonibudo, ni Mowe, nipinlẹ Ogun. Lasiko ti wọn n pete ati lọ soko ole jija, ti wọn n kọ ara wọn bi wọn yoo ṣe lọọ pa awọn ẹni ti ko ṣẹ wọn lẹṣẹ kan lẹkun lọwọ tẹ wọn.
Orukọ awọn mẹta ọhun ree gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe gbe e jade: Daniel Okereke, Henry Osagwe ati Wisdom Atuba.
Awọn kan ni wọn ta teṣan ọlọpaa Mowe lolobo, pe awọn gende kan ti wọn to meje wa ni ibuba wọn lagbegbe Ajeonibudo, wọn n dira ogun nitori oko ole ti wọn fẹẹ lọ.
CSP Saminu Akintunde, DPO Mowe, ko awọn ikọ rẹ lẹyin, wọn si gba ibẹ lọ, ṣugbọn bawọn afurasi naa ṣe ri wọn ni wọn bẹrẹ si i sa lọ, ọpẹlọpẹ awọn eeyan to wa nitosi ti wọn da si ohun to n ṣẹlẹ naa, awọn ni wọn kun awọn ọlọpaa lọwọ ti wọn fi ri awọn mẹta yii mu.
Ibọn ibilẹ danku kan to ni ọta meji ti wọn ko ti i yin ninu, ọbẹ meji ati awọn oogun abẹnugọngọ lawọn ọlọpaa gba lọwọ awọn mẹta tọwọ tẹ yii.
CP Lanre Bankọle, Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, ti ni ki wọn wa awọn mẹrin to sa lọ ri, ki wọn si ko awọn mẹta yii lọ sẹka itọpinpin.