Nibi tawọn Fulani ajinigbe yii ti fẹẹ gbowo itusilẹ ẹni ti wọn ji gbe lọwọ ti tẹ wọn l’Owode-Ẹgba

Faith Adebọla, Ogun

Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo So-Safe atawọn ọdẹ ibilẹ kan, awọn l’Ọlọrun lo lati doola ẹmi Ọgbẹni Oseni tawọn afurasi ọdaran kan ji gbe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ibi tawọn ajinigbe naa ti fẹẹ gba miliọnu mẹrin Naira ti wọn beere fun gẹgẹ bii owo itusilẹ lọwọ ti ba meji ninu wọn, wọn ni Fulani ni wọn.

Ọgbẹni Moruf Yusuf, oludari eto iroyin fun ajọ So-Safe, nipinlẹ Ogun, to fiṣẹlẹ yii to Alaroye leti lorukọ ọga wọn, Ọmọwe Sọji Ganzallo, sọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ogunjọ, oṣu yii, lawọn gba ipe idagiri kan, wọn fi to wọn leti pe awọn ajinigbe kan ti lọọ kọ lu Oseni to n sin maaluu lagbegbe Ọlọrunda-Lukosi, ni ilu Irọ, nijọba ibilẹ Owode-Ẹgba. Ibujẹ ẹran to maa n ko awọn maaluu ẹ si, toun naa si n gbe itosi ẹ, ni wọn lọọ ka a mọ ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ kọja iṣẹju diẹ lọjọ Tọsidee, ti wọn si ji i gbe.

Yatọ si jiji ti wọn ji i gbe, wọn tun jale, wọn tun gba ẹgbẹrun lọna aadoje Naira (N130,000) lọwọ onimaaluu yii, ati iwe alupupu to fi n ṣẹsẹ rin.

Lẹyin eyi lawọn afurasi naa ni kawọn mọlẹbi Oseni ko miliọnu mẹrin Naira wa gẹgẹ bii owo itusilẹ ti wọn ba fẹẹ ri ọmọ wọn pada, n lawọn mọlẹbi yii ba bẹrẹ si i sare owo kiri.

Lasiko tawọn atilaawi yii fẹẹ gba owo itusilẹ naa, laimọ pe awọn ẹṣọ ti yi igbo to wa ka, ibẹ lọwọ palaba wọn ti ṣegi, ni wọn ba ri i pe ọmọde Fulani ni wọn, ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn lawọn ti wa.

Mohammed Lawale ni ọkan porukọ ara ẹ, o lẹni ogun ọdun pere loun, adugbo Ṣharagi, ni Karaoke, n’Ibadan, loun n gbe, ẹni keji, Ṣarafa Aṣimiu, toun jẹ ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ni ile Amusa Yusuf, to wa l’Oke-Aje, n’Ibadan, loun n gbe, ibẹ lawọn ti waa ṣe ṣuta nipinlẹ Ogun.

Lẹyin tọwọ tẹ wọn ni wọn mu wọn lọ sibi ti wọn ji ẹni ẹlẹni pamọ si ninu igbo kijikiji ọhun, amọ bi awọn yooku wọn ṣe fura pe aṣiri ti tu, wọn fi Oseni silẹ ni dide lọwọ lẹsẹ to wa, wọn ta kọṣọ sigbo, n ni wọn ba na papa bora.

Ninu fọran fidio kan ti So-Safe fi lede, ede Fulani ni ọkan ninu awọn afurasi naa n sọ fatafata, nibi to ti n jẹwọ iwa laabi ti wọn hu.

Ganzallo ni bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ So-Safe ṣi n dọdẹ awọn to sa lọ naa lati mu wọn, o lawọn ti ṣe iwadii ranpẹ lori awọn afurasi meji tọwọ ba yii, awọn si ti fa wọn le ọlọpaa teṣan Irọ lọwọ, ki wọn le tete gbe igbesẹ to ba yẹ lori wọn.

Leave a Reply