Nibi tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti n ṣepade lawọn ọlọpaa ti ko wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Meje lara awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun to wa lagbegbe Morogbo, nipinlẹ Eko, ti bọ sakolo ọlọpaa. Nibi ti wọn ti n ṣe ipade wọn lọwọ ni nnkan bii aago meje alẹ ni wọn ka wọn mọ.

Orukọ ati ọjọ-ori awọn mejeeje tọwọ tẹ ọhun ni: Hameed Salami, ẹni ọdun marundinlogoji, Sunday Ogbemudia, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, Ṣẹgun Okekunle, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Imọlẹ Kingsley, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Rasaki Ọlalekan, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.

Awọn meji to ku ni Innocent Osuya, ẹni ọdun mẹtalelogun ati Ogunlade Adewale toun jẹ ẹni ọgbọn ọdun.

Wọn ni otẹẹli House 2 Hotel, to wa ni Igbẹkẹle, ni Morogbo, lawọn afurasi ọdaran naa gba lọ ni nnkan bii aago meje ku diẹ lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, wọn sọ pe awọn fẹẹ ṣe apero kan ninu ọgba wọn, wọn si sanwo.

Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa fura si wọn, ni wọn ba yọkẹlẹ lọọ sọ fawọn alaṣẹ ileetura ọhun, lawọn ọga wọn ba kan sileeṣẹ ọlọpaa lori aago pe ki wọn waa ba awọn wo awọn alejo ọran to n ṣepade lọdọ awọn yii.

Kia lawọn ọlọpaa ẹka teṣan Morogbo ti debẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn.

Nigba ti wọn n tu ẹru wọn wo, oriṣiiriṣii nnkan ija bii aake, ada, ọbẹ, oogun abẹnugọngọ, iṣana ati katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin ni wọn ba nibẹ. Wọn tun ba ibọn agbelẹrọ meji lọwọ wọn.

Ọrọ ko pariwo mọ, wọn rọ gbogbo wọn da sọkọ ọlọpaa, ko si pe ti wọn fi balẹ si ẹka awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iwadii.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, loun ti paṣẹ pe ki wọn tete pari iwadii lori wọn, kawọn afurasi wọnyi ati ẹru ofin ti wọn n ko kiri le lọọ ṣalaye ara wọn niwaju adajọ, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Muyiwa Adejọbi, ṣe sọ f’ALAROYE.

Leave a Reply