Nibi ti Adedeji ti n gbẹjọ ro lọwọ laṣiiri ẹ ti tu pe ayederu lọọya ni n’Itori

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọpọlọpọ ẹjọ ni ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Adedeji Adelẹkan ti ba awọn eeyan gba ro nipinlẹ Ogun ti ko bu u lọwọ ri, afi kootu giga to wa lagbegbe Itori, nipinlẹ Ogun, to lọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ yii, ti aṣiri ẹ ti tu pe ki i ṣe lọọya gidi.

Koda, nibi to ti n gba ẹjọ ẹnikan to n jẹ Ọmọbọlaji Muri Kuti atawọn mẹrin mi-in ro ni lọọya keji to wa nibẹ ti bẹrẹ si i ta ko o pe ko kunju oṣunwọn, ki i ṣe lọọya gidi. Eyi lo mu adajọ beere iru iwe ti Adedeji ka atawọn ileewe to lọ.

Nibi ti wọn ti da ibeere bo o naa lo ti han pe ayederu pọnbele lọkunrin to n gbẹjọ ro naa, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ ẹjọ lo ti ba awọn onibaara ṣe nile-ẹjọ Majisireeti yii ati ile-ẹjọ giga.

Nigba ti ko sọna mi-in mọ ju ko jẹwọ lọ, Adedeji jẹwọ pe oun ki i ṣe lọọya tootọ, nitori oun ko paasi idanwo toun ko ba fi di lọọya gidi. Bẹẹ ni ẹka idajọ ko mọ oun bii lọọya, nitori wọn ko pe oun lati maa ṣiṣẹ amofin lọ.

 

Leave a Reply