Nibi ti Adewale atawọn ọrẹ ẹ ti fẹẹ ja awọn ọlọpaa lole lọwọ ti tẹ wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Mẹrin lara awọn adigunjale to n daamu awọn eeyan agbegbe Ketu si Ikorodu, ti ko sakolo ọlọpaa, ibi ti wọn ti fẹẹ ṣiṣẹ ibi wọn ni afẹmọju Ọjọbọ, Tọsidee yii, fawọn ero ọkọ kan to n lọ sagbegbe Abiọla Garden, Ọjọta, nipinlẹ Eko, lai mọ pe awọn ọlọpaa lo wa ninu mọto naa, ibẹ lọwọ ti tẹ wọn.

Orukọ awọn afurasi ọdaran ọhun ni Adewale Ismaila, ẹni ọgbọn ọdun, Chinedu Okafor, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Victor Tote, ẹni ọdun mọkandinlogun ati Abdulahi Ọlalere, toun jẹ ẹni ogun ọdun pere.

Ọga agba ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa (Rapid Response Squard, RRS), CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi sọ pe bawọn ṣe n gba ipe lojoojumọ nipa iṣẹ buruku tawọn ọmọkọmọ naa n ṣe, ti wọn n da awọn eeyan lọna, ti wọn n fọbẹ ati’bọn gba foonu, baagi ati dukia wọn lo mu kawọn maa patiroolu agbegbe Owode Onirin, Mile 12, Ketu si Ọjọta ati Ikorodu leralera.

Iṣẹ patiroolu yii lo lawọn ọmọọṣẹ oun n ṣe ni kutu-hai ọjọ Tọsidee yii, ti wọn si dọgbọn paaki ọkọ wọn si agbegbe Ọjọta, wọn dọgbọn ṣe bii pe mọto naa yọnu lojiji ni, ilẹ o si ti i mọ, nnkan bii aago mẹrin aabọ idaji ni.

Ẹgbẹyẹmi ni laarin iṣẹju marun-un ti wọn de’bẹ, awọn afurasi ọdaran mẹrin yii ti ya bo wọn, wọn fa ọbẹ aṣooro yọ, wọn si bẹrẹ si i paṣẹ ki wọn ko foonu ati owo ọwọ wọn fawọn, wọn tun fẹẹ yọ batiri mọto pẹlu. Ibi ti wọn ti n ṣe eyi lọwọ ni ọlọpaa to wa ninu ọkọ ti tan ina mọto mọ wọn, lawọn ẹruuku yii ṣẹṣẹ waa ri i pe awọn ti ṣi iṣẹ ṣe, awọn ọlọpaa si fi pampẹ ofin gbe wọn loju ẹsẹ.

Alukoro fun ikọ RRS Eko, Ọgbẹni Adebayọ Taofeek, to fọrọ yii ṣọwọ s’ALAROYE sọ pe ọkan lara awọn ọmọkọmọ ohun, Abdulahi Ọlalere, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Ọrọbọ’ jẹwọ fawọn agbofinro pe iṣẹ adigunjale loun n ṣe, pe oun wa lara ikọ adigunjale ẹlẹni marun-un kan, awọn ero ati onimọto lawọn maa n ja lole ni tawọn, agbegbe Ketu si ikorodu lawọn yan laayo tawọn ti n ṣiṣẹ awọn.

Wọn l’Ọrọbọ tun jẹwọ pe oun atawọn ikọ ọhun lawọn wa nidii idigunjale to waye laduugbo China Town, ati Tipper garaaji, lagbegbe Ketu, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii. Wọn lo sọ pe oun ti ṣẹwọn ri, aipẹ yii si loun jade ni lọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, ẹsun ole jija naa lo gbe oun de’bẹ.

Iṣẹ iwadii ṣi n tẹsiwaju, wọn o si ni i pẹ taari awọn afurasi mẹrẹẹrin siwaju adajọ

Leave a Reply