Nibi ti ayederu ṣọja kan ti n da awọn eeyan lọna lawọn ọlọpaa yinbọn pa a si n’Ṣagamu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Eledumare ti ji gba alejo ọkunrin kan lọwọ oru mọju aarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii. Ole lọkunrin ọhun n ja lọwọ pẹlu awọn yooku rẹ ti wọn jọ wọṣọ ṣọja loju ọna marosẹ Ṣagamu si Benin, nibẹ lawọn pẹlu awọn ọlọpaa ti wọya ija, tiku fi ka oloogbe naa mọbi to ti n da awọn ero lọna.

Awọn ọlọpaa Ijẹbu-Ifẹ ni wọn gba ipe kan ni nnkan bii aago mẹta oru ku iṣẹju mẹẹẹdogun, pe awọn kan ti wọn wọṣọ ologun ilẹ wa ti ya bo ọna ẹspirẹẹsi to lọ lati Ṣagamu si Benin, wọn si n da awọn ero lọna pẹlu ibọn atawọn nnkan ijamba mi-in ti wọn dihamọra ni.

Eyi ni DPO teṣan naa, CSP Rapheal Ugbenyo, fi sare ko awọn ikọ rẹ atawọn SARS kan jọ, wọn gba ibẹ lọ loru naa. Bi wọn ṣe debẹ lawọn ayederu sọja ọhun ṣina ibọn bo wọn, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, si sọ pe ogun naa le pupọ pẹlu bawọn ole to wọṣọ ṣọja naa ṣe bẹrẹ si i yinbọn sawọn ọlọpaa, tawọn agbofinro naa si n da a pada lai ṣojo. O ni o to ọgbọn iṣẹju ti ogun ọlọpaa atawọn ole naa fi waye.

Nibi ti wọn ti n fi ọta ibọn ja naa ni ibọn ti ba ọkan ninu awọn ole yii, to si ku lẹsẹkẹsẹ, awọn mi-in ninu wọn naa fara gbọta ninu wọn to jẹ wọn gbe ọta ibọn sa wọgbo lọ ni.

Eyi ni CP Edward Ajogun ṣe ni kawọn araalu tabi ileewosan to ba kofiri ẹnikẹni to n gbe ọta ibọn kiri fi to ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi leti. Bakan naa lo kilọ fawọn adigunjale pe ki wọn jinna sipinlẹ Ogun, nitori bi wọn sa wọ iho ilẹ, awọn yoo mu wọn jade.

Ibọn meji, foonu kan, oogun oriṣiiriṣii pẹlu ina atẹ-tan(Torch light) lawọn ọlọpaa ba nibi ti wọn ti digunjale naa.

Wọn ti gbe oku eyi to ku yii si ile igbokuu-si, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn yooku ti wọn sa lọ.

Leave a Reply