Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ni nnkan bii aago mejila aabọ oru ojọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa yii, ti i ṣe ayajọ Ominiria Naijiria, awọn olugbe Odomalasa Estate, n’Ilese-Ijẹbu, ko foju kan oorun. Awọn adigunjale lo n da wọn laamu, ti wọn n gba tọwọ wọn.
Nigba ti olobo si ta awọn ọlọpaa, ti wọn debẹ, ọkunrin ti oju rẹ wu kungbun-kungbun latari lilu ti wọn ti lu yii ni ọwọ ba, Bọlanle Ọjọmu lo n jẹ.
Gẹgẹ bi alaye Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe, o ni nigba ti ikọ ọlọpaa Ilese-Ijẹbu, eyi ti CSP Amuda Bọlaji n dari debẹ, awọn adigunjale naa pọ, ṣugbọn bi wọn ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn fi ere ge e, ti wọn n sa lọ.
Awọn agbofinro naa bẹrẹ si i le wọn, Bọlanle Ọjọmu yii nikan lọwọ wọn pada tẹ ṣa pẹlu iranlọwọ awọn eeyan agbegbe naa, ni wọn ba fọwọ ofin mu un.
Ibọn ilewọ ibilẹ ti Bọlanle mu dani yii ati ọta ibọn kan ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa gba lọwọ rẹ.
Fun itẹsiwaju iwadii lori ọrọ rẹ, Adele ọga agba ọlọpaa tuntun nipinlẹ Ogun, DCP Abiọdun Alamutu, paṣẹ pe ki wọn gbe ọkunrin yii lọ sẹka to n ṣewadii iwa ọdaran nipinlẹ yii, ki wọn si wa awọn to sa lọ naa lawaari.