Nibi ti Kelechukwu atọrẹ ẹ ti fẹẹ lu mọtọ ti wọn ji gbe ta ni gbanjo lọwọ ti tẹ wọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ọrẹ lawọn mejeeji pe ara wọn, Kelechukwu Nnonyelu ati Godspower Okongi, ṣugbọn ọrẹ gbewiri ni wọn jọ n ṣe, mọto bọginni Lexus 2004 SUV kan ni wọn lọọ ji gbe l’Alaba, nipinlẹ Eko, ibi ti wọn ti n seto ati ta ọkọ ọhun danu ki wọn kowo ẹ sapo lọwọ ti ba wọn ni Festac.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, lo fi iroyin ọhun to ALAROYE leti lọjọ Abamẹta, Satide yii. O ni Furaidee, ọjọ Ẹti, lọwọ awọn agbofinro lati teṣan ọlọpaa Festac ba awọn igaara ọlọṣa mejeeji ọhun.

A gbọ pe awọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe niṣe lawọn lọọ foru boju ji mọto ọhun gbe nibi tẹni to ni i gbe e si, ni wọn ba wa ọkọ ọhun gba agbegbe Festac lọ, wọn fẹẹ ta a ni gbanjo.

Ibi ti wọn ti n wa onibaara to maa tete sanwo ọkọ ọhun lawọn eeyan ti wọn fi ọkọ naa lọ ti bẹrẹ si i fura si wọn. Miliọnu kan naira pere ni wọn lawọn fẹẹ ta a, bẹẹ wọn lọkọ ọhun to miliọnu mẹjọ naira, ṣugbọn ko lọ nilẹ ko dowo lawọn afurasi ọdaran fẹẹ fi mọto onimọto ṣe, lawọn ọlọpaa ti wọn ti ta lolobo ba yọju si wọn.

ALAROYE gbọ pe wọn kọkọ fẹẹ sa lọ, ṣugbọn ko ṣee ṣe nigba ti wọn gburoo ibọn ọlọpaa nipakọ wọn, eyi lo sọ wọn dero teṣan ọlọpaa, Lexus ti wọn fẹẹ ta ni wọn gun wa, ṣugbọn ọkọ ọlọpaa lo gbe wọn pada si teṣan.

Teṣan ni wọn ti jẹwọ pe awọn ji mọto naa ni, wọn ni eyi ni igba akọkọ tawọn maa jale nla bii eyi. Wọn lowo tawọn maa fi ṣe bisinẹẹsi lawọn n wa to mu kawọn lọọ jale.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti paṣe pe ki wọn taari wọn sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin, wọn si ti balẹ si Panti, ni Yaba, bayii. Lẹyin iwadii ni wọn maa foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply

%d bloggers like this: