Nibi ti nnkan de duro, gbogbo araalu lo gbọdọ mu ọrọ aabo wọn lọkun-un-kundun- Ọọni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Arole Oduduwa, Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja 11, ti sọ pe pẹlu gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ kaakiri orileede yii bayii, a ko gbọdọ da ọrọ ipese aabo da awọn agbofinro nikan, bi ko ṣe ki gbogbo araalu joye oju-lalakan-fi-n-ṣọri sagbegbe wọn.

Lasiko ti Kabiyesi n gbalejo kọmiṣanna fun ileeṣẹ ọlọpaa to ṣẹṣẹ de Ọṣun, Wale Ọlọkọde, laafin rẹ lo woye pe atokeere lolojujinjin ti gbọdọ mu ẹkun eto aabo sun, eleyii to ni yoo le ṣeranwọ nigba ti ipenija eto aabo ba de.

Ọba Ogunwusi ṣalaye pe bi awọn eeyan ilu Ileefẹ ṣe ni agbekalẹ ilana ibilẹ ti wọn maa n lo lati daabo bo ara wọn lo ran wọn lọwọ lasiko wahala EndSars to waye kọja.

O ni bi wahala naa ṣe bẹrẹ, ti awọn ọdọ.n dana sun ile, dana sun dukia awọn eeyan kaakiri orileede yii lawọn agbaagba Ifẹ ti dide, ti wọn si gbe gbogbo igbesẹ to tọ lati gbe, idi niyi ti ko fi si biba dukia jẹ niluu naa.

Ọọni fi asiko naa sọ fun Ọlọkọde pe loootọ ifọkanbalẹ wa niluu Ileefẹ, o ni ipenija awọn ọmọ to n ṣe ẹgbẹ okunkun atawọn ti wọn n lo egboogi oloro jẹ eyi to n kọ gbogbo araalu lominu.

O ni oun mọ pe kọmisanna naa kunju oṣunwọn nitori o ni akọsilẹ rere lasiko to ṣiṣẹ gẹgẹ bii Aria Kọmanda niluu Ileefẹ, bakan naa ni Ọọni tun jẹjẹẹ atilẹyin to duro o re fun un.

Ṣaaju ni Ọlọkọde ti sọ pe wiwa oun sipinlẹ Ọṣun ki i ṣe ti awada rara, ṣe loun wa tijatija, o kilọ fun awọn ọdaran; yala ki wọn ronupiwada tabi ki wọn fi ilu silẹ fun oun, bẹẹ lo fi da awọn araalu loju pe ko sewu loko longẹ fun wọn.

Leave a Reply