Nibi ti obinrin kan duro si jẹẹjẹ rẹ ni ọkọ ayọkẹlẹ ti lọọ tẹ ẹ pa n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ki Ọlọrun ma jẹ ka rin arin-fẹsẹ-si, nibi ti abilekọ kan ti duro jẹẹjẹ rẹ ni ọkọ ayọkẹlẹ yii ti lọọ tẹ ẹ pa lagbegbe Arca Santa, l’Opopona Ajasẹ-Ipo, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii.

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn fi to ALAROYE leti pe lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni ọga arabinrin naa ran an niṣẹ lati gbọngan ayẹyẹ to ti n ṣiṣẹ, Arca Santa. Nibi to ti duro ni ẹgbẹ ọna ni ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry kan to ni nọmba Lagos AAA 261, ti lọọ kọlu u, to si ku loju-ẹsẹ. A gbọ pe awọn ọlọpaa to da si iṣẹlẹ ọhun ni ko jẹ ki awọn eeyan sakọlu si ọkunrin to wa ọkọ ayọkẹlẹ naa. Wọn ni o n gba ipe lọwọ lasiko to n wakọ lo ṣe ya bara, to si tẹ obinrin naa pa, o tun kọlu opo ina oju popo pẹlu.

Ọga ajọ ẹṣọ alaabo oju popo, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Jonathan Owoade, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni wọn ti gbe oku obinrin naa lọ si yara igbooku-si nileewosan jẹnẹra, niluu Ilọrin.

 

Leave a Reply