Nibi ti Ogunwusi ti n faṣọ ọlọpaa jale lọwọ ti tẹ ẹ l’Ẹfon-Alaaye

 Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan, Fẹmi Ogunwusi, ti wa ni galagala ọlọpaa nipinlẹ Ekiti bayii.

Ogunwusi ni ọwọ awọn ọlọpaa ayaraṣaṣa, RSS, tẹ niluu Ẹfon-Alaaye, nipinle Ekiti, nibi to ti lọọ fi aṣọ awọn Mopol jale.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ỌgbẸni Sunday Abutu, ṣalaye pe ni deede aago mẹwaa alẹ lọwọ tẹ ọkunrin naa lasiko ti wọn n ṣe ayẹwo ọkọ loju ọna to lọ lati ilu naa si Ile-Ifẹ.

Awọn agbofinro ni ki ọwọ awọn too tẹ ẹ, o ti fibọn ja ọkada kan gba lọwọ awọn ọlọkada, bẹẹ lo ti tun lọwọ si awọn idigunjale mi-in pẹlu aṣọ ọlọpaa lọrun.

Ẹsun mi-in ti wọn tun ka si i lẹsẹ nigba ti wọn n ṣe afihan rẹ lolu ileeṣẹ ọlọpaa ni pe o pa ọmọ bibi inu rẹ ti ko ju ọmọ oṣu mẹjọ lọ ninu oṣu keje, odun 2020, o si paro fawọn eeyan  pe ọmọ naa ja silẹ lati ori bẹẹdi ni.

Nigba ti wọn ṣe ayẹwo si ile Ogunwusi, wọn ba ibọn ilewọ kekere to ni ọta mẹtala ninu, aṣọ ọlọpaa meji, aṣọ awọtẹlẹ aọn ọlọpaa, fila ọlọpaa, owo naira atijọ, kaadi idibo awọn ohun eelo ileewosan, oogun dudu loriṣiiriṣii ati igbo.

Nigbati ALAROYE fọrọ wa ọkunrin yii lẹnu wo, o ni ọdọ ẹgbọn oun to ku ninu ijamba mọto ni ọdun diẹ sẹyin loun ti jogun awọn nnkan yii.

O ṣalaye pe ọmọ ilu Ileefẹ ni oun, ati pe iṣẹ igi lila loun wa wa si Ẹfon-Alaaye, o ni ilu Ẹrinyan gan-an loun n lọ lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ gan-an.

Leave a Reply