Awọn Yoruba ti wọn maa n sọ pe ọlaja ni i gbọgbẹ ko ṣi ọrọ naa sọ o. Ṣugbọn ki i ṣe ọgbẹ lasan ni iyaale ile kan gba nigba to n la ọmọ rẹ ati iyawo rẹ nija. Niṣe nija to la naa ran an sọrun ọsangangan; bo tilẹ jẹ pe ọmo rẹ ko ni i lọkan pe oun fẹẹ pa a, o ṣeeṣi ni.
Ni Abule kan ti wọn n pe ni Zawiyya Tundunwada, ni Kontagora, nipnlẹ Niger, niṣẹlẹ naa ti waye laipẹ yii.
A ri i gbọ pe ọkunrin ti wọn ko darukọ rẹ yii ati iyawo re ni wọn jọ n ja, ti tọkọ-tiyawo naa si n lu ara wọn. Nigba ti wahala ija naa kuro ni kekere ni iya ọkọ iyawo ba jade sita pe ki oun ba wọn pari ija naa. Ni iya ba ko si wọn laarin. Ṣugbọn o jọ pe inu ti bi ọkọ iyawo yii kọja aala nitori gbogbo bi iya rẹ ṣe n bẹ ẹ, ko gbọ.
Afi bi ọkunrin naa ṣe lọọ mu ọbẹ o, o fẹẹ gun iyawo rẹ, ṣugbọn nitori inu buruku to n bi i, iya to bi i ninu lo gun lọbẹ dipo iyawo toun pẹlu rẹ jọ n ja to fẹẹ da sẹria fun.
Oju ibi ti wọn ti n ja naa ni a gbọ pe iya yii ṣubu lulẹ si, gbogbo akitiyan wọn lati tọju rẹ ko le wa lalaafia ko so eeso rere nitori ibẹ naa ni iya yii ku si.
Ni wọn ba gbe iyawo toun naa ti fara ṣeṣe nitori iya buruku ti ọkọ rẹ fi jẹ ẹ lọ sileewosan.
Oju-ẹsẹ tawọn agbofinro gbọ si iṣẹlẹ naa ni wọn lọọ mu ọkunrin to ṣeeṣi pa iya rẹ yii, o ṣi wa lọdọ awọn agbofinro to n ran wọn lọwọ lori iwadii wọn.