Monisọla Saka
Ọjọ ti ko daa rara ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii, jẹ fawọn obi ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtala kan, Taiye Ojo, pẹlu bi ina ẹlẹntiriiki ṣe gbe ọmọ naa, to si gbabẹ jade laye lasiko to n sa fun aja kan.
Agbegbe Makoko, Yaba, nipinlẹ Eko, niṣẹlẹ yii ti waye. Aja to n gbo bii ẹni to ri ole ni ọmọ naa n sa fun ninu agbala ile ti wọn n gbe to fi lọọ pade iku ojiji ọhun.
Ile igbọnsẹ, to wa ninu ile naa ni wọn ni Taye n lọ nigba ti aja yii bẹrẹ si i gbo mọ ọn. Ẹru gbigbo aja yii lo ba a, bo ṣe di pe o ki ere mọlẹ lati le sa kuro ni sakaani aja ọhun niyẹn.
Wọn ni nibi to ti n gbiyanju lati sa lọ fun aja naa, lo ti ṣeeṣi fọwọ kan ibi idi ẹrọ amuletutu (Air Conditioner), to maa n wa lọwọ ita, to si n ṣiṣẹ lọwọ nigba naa. Nibẹ ni ina ti gbe e, tọmọ naa si ṣe bẹẹ dagbere faye.
Bo tilẹ jẹ pe wọn sare gbe e lọ sileewosan to wa nitosi ọdọ wọn, niṣe lawọn dokita sọ fun wọn pe oku ọmọ naa ni wọn gbe wa.
Lẹyin ti wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa teṣan Sabo, Yaba, nipinlẹ Eko, leti ni ọga ọlọpaa teṣan ọhun ko awọn agbofinro atawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣodi lọ sagbegbe iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe wi ninu akọsilẹ wọn, “Iroyin to to wa leti ni pe aja n gbo mọ ọmọ to ti doloogbe yii nigba to fẹẹ lọọ ṣe igbọnsẹ. Lasiko to n gbiyanju lati sa fun aja ọhun ni ọwọ ẹ lọọ ṣeeṣi kan ẹrọ amuletutu, to si ṣe bẹẹ gbẹmii mi’’.
Wọn ti pada sin oku ọmọ naa nilana ẹsin Musulumi.