Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii, ki i ṣe eyi ti yoo ṣee gbagbe bọrọ fawọn eeyan Kajọla, nijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo, latari rogbodiyan to waye laarin awọn ọlọpaa abule ọhun atawọn ọdọ ilu lori iku baalẹ kan atawọn meji mi-in.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, baalẹ ọhun, David Olowofoyeku, pẹlu awọn meji yooku, Gbenga Abayọmi ati Kọla Akinduro, ni wọn pade iku ojiji lati ọwọ awọn ọlọpaa lasiko ti wọn n pada bọ lati oko wọn lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja.
Awọn ọlọpaa da wọn duro lojiji lati fipa gba owo lọwọ wọn, bi ọlọkada to gbe wọn ti n gbiyanju ati duro ni awakọ Toyota Hilux kan kọlu wọn nibi to ti n pẹwọ fawọn ọlọpaa, to si ran awọn mẹtẹẹta sọrun ọsan gangan.
Pẹlu ibinu nla lawọn ọdọ fi ko oku awọn mẹtẹẹta sinu ọkọ, ti wọn si mori le teṣan ọlọpaa to wa labule Kajọla lati fẹhonu han ta ko iṣẹlẹ naa.
Wọn ni ṣe lawọn ọdọ naa yari kanlẹ, ti wọn si ni dandan ni ki ọga ọlọpaa teṣan ọhun yọnda ọkan ninu awọn ọmọ abẹ rẹ, ẹni ti wọn mọ si Major fun awọn nitori pe oun gan-an lo ṣaaju awọn agbofinro to da awọn oloogbe naa duro nibi ti wọn ti pade iku ojiji.
Ọkan ninu awọn olufẹhonu ọhun to porukọ ara rẹ ni Funmi Olowogboye sọ fawọn oniroyin pe o ti to bii ọdun mẹtadinlogun ti wọn ti gbe Major wa si teṣan Kajọla.
O ni ọpọ igba lawọn ara abule ọhun ti beere fun gbigbe ọkunrin naa kuro lọdọ awọn latari iṣẹ ibi to n fi aṣọ ọba to n wọ sọrun ṣe lagbegbe naa, ṣugbọn ti ileeṣẹ ọlọpaa kọ eti ikun si ẹbẹ awọn.
Ohun tawọn tinu n bi ọhun fẹẹ ṣe ni ki wọn dana sun teṣan naa ti wọn ba fi kọ lati dahun si ẹdun ọkan wọn, ṣugbọn awọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Oyediran Oyeyẹmi, ko sodi, ti wọn de si asiko ko jẹ ki wọn le mu erongba wọn ṣẹ.
Alaga ijọba ibilẹ Odigbo, Abilekọ Margret Akinsurọju, parọwa sawọn ọdọ tinu n bi naa lati gba alaafia laaye, ki wọn ma si ṣe dabaa ati ṣe idajọ lọwọ ara wọn.
O ni oun loun sare pe awọn ẹṣọ alaabo lati tete lọ sibi iṣẹlẹ naa ni kete ti oun gbọ nipa rẹ.
Akinsurọju ni oriṣi iroyin meji ọtọọtọ loun gbọ nipa ohun to ṣẹlẹ, ati pe awijare awọn ọlọpaa ni pe awakọ elere asaju kan lo gba awọn mẹtẹẹta lori ọkada ti wọn wa, to si ṣe bẹẹ sa lọ.
O ni awọn ọlọpaa ṣe e laaye pe awọn gbiyanju ati le awakọ naa, ṣugbọn awọn ko ri i mu, wọn ni bi awọn ṣe n pada sibi ti ijamba ti waye lawọn eeyan gbe ija ko awọn loju, ti wọn si fẹẹ dana sun awọn lori ẹsun pe awọn lawọn ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Alaga ọhun ni inu oun dun nigba ti oun gbọ pe awọn tinu n bi ti gba alaafia laaye, ti ẹbi awọn to ku si ti gba lati lọọ sinku wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni ko si ododo ninu ẹsun tawọn ara abule naa fi kan awọn ọlọpaa nitori pe awọn oloogbe ọhun gan-an ni wọn ṣokunfa iku ara wọn nibi ti wọn ti n gbiyanju lati sa mọ awọn agbofinro lọwọ.