Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Ọwọ palaba ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Yakubu Yisa, ti ṣegi pẹlu bi wọn ṣe mu un lasiko ti oun atawọn ẹgbẹ rẹ kan n gbiyanju lati digun ja awọn eeyan kan lole laduugbo Surulere, niluu Ondo, n’ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.
ALAROYE gbọ pe Yisa atawọn ẹmẹwa rẹ ni wọn ṣigun lọọ ba awọn olugbe ile ta a n sọrọ rẹ yii ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 ta a wa yii.
Oun nikan ni wọn lo kọkọ wọnu ile lọọ ba awọn eeyan, nigba tawọn yooku rẹ ṣi wa nita. Amọ bo ṣe n wọle lẹnikan ti ri i pẹlu ibọn to mu lọwọ, to si tete ta awọn araale to ku lolobo.
Awọn eeyan ọhun ṣọkan akin, wọn si yi ogbologboo adigunjale naa po, ni wọn ba gba ibọn to wa lọwọ rẹ.
Ninu alaye ti ọkan ninu awọn olugbe ile naa ṣe fun akọroyin wa, o ni oun loun kọkọ ri Yisa nigba to fẹẹ gba ọna ẹyin waa ka awọn mọle.
O ni loju-ẹsẹ loun ti sare pe awọn araale yooku, ti oun si tun fi foonu pe awọn to wa laduugbo lati waa ran awọn lọwọ lori ọrọ awọn ọdaran to waa ka awọn mọle.
O ni ibi tawọn ti suru bo o ni ibọn ọwọ rẹ ti ja bọ, leyii to fun awọn lanfaani ati ri i mu, ṣugbọn tawọn ẹgbẹ rẹ yooku raaye sa lọ ni tiwọn.
O ni wọn kọkọ lu ọdaran ọhun ni aludaku ki awọn too ṣẹṣẹ fa a le ọlọpaa lọwọ.