Nibi to ti n wa ọkan ninu awọn agbẹ ti wọn ji gbe, awọn Fulani pa Daniel, ọmọ ẹgbẹ OPC, sinu igbo n’Iju

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọ ẹgbẹ OPC kan, Adejuyigbe Daniel, lawọn Fulani ajinigbe kan tun pa sinu igbo niluu Iju, nijọba ibilẹ Iju/Ita-Ogbolu, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọkunrin kan to jẹ ọmọ bibi ilu ọhun pe agbẹ kan, Solomon Akinmeji, lawọn Fulani ọhun kọkọ ji gbe nibi to ti n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko rẹ ni Okeji, eyi to wa lagbegbe aala Iju ati Ikẹrẹ-Ekiti.

Ọpọ awọn eeyan to wa pẹlu rẹ ninu oko lo ni wọn fara pa yannayanna nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn kawọn onisẹ ibi naa ma baa ji wọn gbe.

O ni iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa bawọn ọmọ ẹgbẹ OPC kan ṣe ko ara wọn jọ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lati lọọ wa gbogbo inu aginju to wa lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye wo boya wọn le ri baba tí wọn ji gbe ọhun gba pada lọwọ wọn.

O ni o ṣee ṣe ko jẹ apa ibi ti Daniel nikan ti n fọ igbo lawọn Fulani ọhun ti pade rẹ, ti wọn si fun un lọrun pa kawọn ẹgbẹ rẹ too de bẹ.

Ọgbẹni Ogundeji Ayọdeji to jẹ olori ọdọ ilu Iju ninu ọrọ tìrẹ ni o pẹ tawọn Fulani ti n yọ awọn lẹnu lagbegbe naa tijọba ko si rohunkohun ṣe si i.

Ainiye awọn araalu lo ni awọn darandaran naa ti ji gbe, nigba tawọn mi-in si ti ri iku ojiji he lati ọwọ wọn.

Leave a Reply