Nibo lawọn irunmọlẹ wa lọjọ ti won ji ọpa-aṣẹ Ọba Akiolu lọ

Aderounmu Kazeem

Ọjọbọ, ọsẹ yii, iyẹn ana Tọsidee, gan-an ni Olowo Eko, Ọba Rilwan Akiolu, ṣọjọobi ayẹyẹ ọdun kẹtadinlọgọrin to ti pe laye. Ọdun yii gan-an naa ni kabiyesi, si pe ọdun kẹtadinlogun to ti wa lori apere awọn baba nla rẹ.

Bi Kabiesi ṣe n dupẹ wi pe oun tun le ọdun kan si i loke eepẹ, ti gbogbo aye n ba a adupẹ ayẹyẹ ọdun tuntun, ohun kan tawọn eeyan n sọ ni pe, Olowo Eko ko ni i gbagbe ọdun 2020 pẹlu ohun to ṣẹlẹ laafin ẹ lọjọ tawọn ọdọ wọnu aafin gbe ọpa aṣẹ oun Akiolu lọ.

Ọjọ yẹn ni wọn lawọn eeyan buruku kan fọrọ rogbodiyan to ṣelẹ kẹwọ, nigba ti awọn ọdọ bẹrẹ ifẹhonu han lati tako idaamu ati ipakupa tawọn ẹṣọ agbofinro SARS n ko ba wọn.

Ni tododo, ko si ẹnikẹni to fẹran aṣa ati iṣẹṣe Yoruba ti inu rẹ yoo dun, ti wọn ba ri bi awọn eeyan to yẹ ki wọn kọlu awọn to ya wọ aafin yii, ti wọn si sọ agbala ọba alaye di ibi ti wọn iba sọ pe wọn ko ogun ja ni, ṣe kawọ gbera, ti awon mi-in si n rẹrin-in ninu wọn.

Lasiko ti ọrọ ọhun n gbona janjan lawọn eeyan ri fidio kan lori ikanni ayelujara, okunrinn kan lo sọrọ akin nibẹ, ọmọọba gan an ni wọn pe e, bo tilẹ jẹ oun gan an alara ko darukọ ara ẹ, ṣụgbọn ẹnikan to mọ tifun tẹdọ ilu Eko ni, bo ti ṣe bẹrẹ gan-an fi i han gẹgẹ bi araale, nitori bo ti ṣe ki ọpa, lo ki apena, bẹẹ ni ko fi ọrọ awọn iyamọpo paapaa ṣere, to si kan si gbogbo awọn oloye onifila funfun Eko pẹlu.

Ọrọ ọpa aṣẹ ti wọn gbe laafin gan-an lo tori ẹ ṣe fidio ọhun, ki wọn too bẹrẹ si ba a pin kiri ori ikanni ayelujara loriṣiiriṣi.

Ohun to si sọ ni pe, ọpa aṣẹ, Olowo Eko, Ọba Rilwan Akiolu, tawọn ọmọọta gbe salọ, o lọrọ ọhun ni nnkan repẹtẹ ninu.

Ninu ọrọ ọkunrin yii lo ti fidi ẹ mule wi pe ko daju pe aarin Ọba Eko atawọn oloye ẹ gun rege, nitori kani ohun gbogbo ba n lọ bo ti yẹ ni, irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko ni i waye nigboro Eko, ki awon oloye si maa woran bi wọn ti ṣe n fi ọpa aṣẹ ọba Eko ṣẹlẹya bẹẹ yẹn.

O fi kun un pe bi wọn ti ṣe gbe ọpa ọhun kuro ni Iga Idunganran, iyẹn laafin ọba alaye naa, laarion gbungbun Isalẹ Eko, aimọye ojude awọn oloye nla nla l’Ekoo ni wọn gbe e gba, ti wọn n ṣe yẹyẹ ọba, ti wọn si n fi oju aṣa ilu Eko gbolẹ.

Okunrin yii ni, “Ohun ti a maa n gbọ ni pe ti oju ko ba ti ẹyin igbẹti, oju ko le ti Eko, ati pe ilu Eko naa ni wọn tun maa n pe ni arọdẹdẹ-ma-ja, ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ bayii fi i han wi pe loju awọn to yẹ ko pọn aṣa le gan-an lo ti ja mọ wọn lọwọ.

“Gbogbo awọn ti wọn ba ọba yii jẹ pata ni wọn ko wo ọrọ yii mọ Olowo Eko lara, ti aafin atawọn ohun iṣenbaye Eko si di ohun tawọn ọmọ keekeke adugbo fi n ṣere ni tiwọn.  Ti wọn si n fi ọpa aṣẹ ṣe yẹyẹ kaakiri Eko.”

O ni, ko fẹe ma si adugbo naa l’Ekoo ti wọn ko gbe ọpa aṣẹ Ọba Eko de, tawọn onile atawọn onilẹ si n woran, paapaa awọn to ti ba ọba yii jẹ lori erewe, ti wọn si n pera wọn loju ati igi lẹyin ọgba fun Ọba Rilwan Akiolu.

Ọmọoba to ṣe fidio yii naa ti ke si Olowo Eko, ohun to si sọ ni pe, ki Ọba alaye naa ṣatunṣe, ki ajọṣepọ to yẹ le pada saarin oun atawọn oloye ẹ, kirufẹ ohun itiju yii ma tun kọlu aṣa ati iṣẹṣe ilu Eko mọ.

Ṣa o, Ọba Rilwan Akiolu, Olowo Eko, ti pada s’aafin pẹlu ọpa aṣẹ  to rẹwa daadaa, bẹẹ ni kabiyesi tun ṣajọyọ ayẹyẹ ọdun kẹtadinlọgọrin to ti dele aye.

Ibeere tawọn eeyan n bira wọn bayii ni pe, ọpa aṣẹ ti kabiesi gbe pada saafin yii, ṣe eyi ti awọn janduku ọmọota ji gbe laafin ni wọn da pada ni, abi ịjoba lo fun kabiesi ni mi-in?

One thought on “Nibo lawọn irunmọlẹ wa lọjọ ti won ji ọpa-aṣẹ Ọba Akiolu lọ

Leave a Reply