Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (10)

*Idi abajọ ree o

Bi iṣẹ ko pẹ ni, a ki i pẹṣẹ; iroko to si wo si ile agb’ọpọn ni, iṣẹ de fun baba agbẹdo pẹrẹwu niyẹn. Bi ọrọ ti ri fun Theophilous Akindele ree nigba ti Ọgagun agba Yakubu Gowon gbe iṣẹ tuntun le e lọwọ. Ọgbọn ni agbalagba fi i yanju ọrọ ni Gowon ṣe lori ọrọ yii, nitori o mọ pe oninufufu eeyan kan ni Ọgagun Muritala Muhammed ti i ṣe kọmiṣanna fun eto ibanisọrọ, bakan naa lo si mọ pe eeyan lile gbaa ni Akindele ti i ṣe ọga agba pata fun ileeṣẹ to n ṣeto ibanisọrọ yii, o mọ pe awọn mejeeji ni wọn le bii apaara. Ṣugbọn ni ti ọrọ to wa nilẹ yii, Gowon mọ pe Akindele ko jẹbi rara, bi ẹnikan ba wa to jẹbi ọrọ naa, Muritala ni. Muritala lo n fẹẹ fi agbara ti pe oun ni ọga, oun ni minisita eto ibanisọrọ, agbara yii lo si fẹẹ maa fi gun Akindele garagara, pe gbogbo ohun ti oun Muritala ba fẹ ni Akindele gbọdọ ṣe.

Akindele si ree, oun ki i ṣe ẹni ti wọn le maa fi iru ọrọ bẹẹ lọ, oun naa yoo binu rangbọndan ni, paapaa nigba to ba ti mọ pe ori are loun wa. Ọrọ ileeṣẹ ITT to da wahala silẹ yii naa, ọrọ to gba ẹlẹgẹ ni. Gowon mọ pe ọrẹ timọ ni MKO Abiọla ti i ṣe alaga ileeṣẹ yii ni Naijiria ati Muritala, ohun gbogbo si ni Muritala yoo ṣe lati ri i pe iṣẹ naa bọ si ọwọ ọrẹ oun. Ati pe ninu awọn ọga ṣọja ti wọn n ṣejọba igba naa, ṣaaṣa ni ẹni ti Abiọla ko mọ ninu wọn, tabi ti ko ti i ṣe nnkan fun, ko si sẹni ti yoo ta ko ohun yoowu to ba jẹ tirẹ laarin awọn ologun yii, paapaa nigba ti iyẹn ba ti ni ọwọ Muritala ninu. Nidii eyi, gbogbo awọn ti wọn n ṣejọba oloogun yii ni wọn gba pe iwe ileeṣẹ ITT ti Muritala gbe wa siwaju awọn igbimọ ologun naa, iwe daadaa ni, awọn gbọdọ fọwọ si i kia ko maa lọ. Akindele nikan lo ta ku pe iwe naa ko dara.

O ni ko dara ki ijọba fọwọ si i bẹẹ, nitori gbogbo ayẹwo to yẹ ki awọn ṣe lawọn ko ṣe. Bi ọrọ ba di eto ibanisọro, boya ti ileeṣẹ tẹlifoonu ni tabi ileeṣẹ ifiweranṣẹ lapapọ, ko si ẹni ti Gowon i maa fẹẹ gbọrọ lẹnu rẹ ju Akindele lọ. O mọ pe Akindele mọ ohun to n ṣe: to ba sọ pe kinni kan ko dara, kinni naa ko dara ni. Ati pe iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe yii, iyẹn ohun eelo ibanisọrọ tawọn ITT ni awọn fẹẹ ta fun ijọba apapọ yii, owo iṣẹ naa pọ ju ohun ti eeyan gbọdọ fi ọwọ dẹngbẹrẹ mu lọ. Owo to din diẹ ni ẹẹdẹgbẹta miliọnu owo naira (N465,686,708) ni. Bẹẹ nigba naa, dọla Amẹrika meji ni Naira kan. Owo naa ki i ṣe owo kekere rara, ibi yoowu ti ijọba ba si fẹẹ na iru owo bẹẹ si, ibi to yẹ ko ṣee tọka si ni. Gowon mọ pe ki i ṣe pe Akindele fẹẹ gba kinni kan ninu owo yii, ṣugbọn ki owo naa ma ṣegbe ni gbogbo ohun ti oun n ṣe.

Ogagun Yakubu Gowon

Ṣugbọn ko tun fẹẹ ṣẹ Muritala ati awọn ọga ṣọja ti wọn yi i ka ninu igbimọ ologun, iyẹn naa tun lewu. Nitori ẹ lo ṣe da a bii ọgbọn, to ni ki wọn ko gbogbo iwe iṣẹ naa fun Akindele, ko lọọ tun un yẹwo, ko si gbe abajade iwadii rẹ, ati ọna ti wọn yoo fi gba ṣe iṣẹ naa jade fun igbimọ ologun to ga ju lọ yii laarin ogunjọ pere. Iyẹn ni iṣẹ naa ṣe le koko, nitori lẹsẹkẹsẹ ni akọwe ijọba apapọ, C. Lawson, gbe iwe iṣẹ awọn ITT yii ti awọn Muritala ti n bo hẹhẹ le e lọwọ, to ni ko tete maa ba iṣẹ rẹ lọ. Bẹẹ ni Akindele fo jade, oun naa mọ pe iṣẹ kekere kọ ni iṣẹ ọhun, iṣẹ to yẹ ko na wọn bii oṣu mẹta ni. Ṣugbọn o mọ pe oun ko gbọdọ ja Gowon kulẹ, oun ko si gbọdọ doju ti i, oun gbọdọ ṣe iṣẹ naa bii iṣẹ ni. Bo ti de ọọfiisi rẹ lo tu iwe naa yẹbẹyẹbẹ, aisun bẹrẹ, nigba ti yoo si fi di ọjọ keji, o ti ṣeto lati ha iwe iṣẹ naa fun gbogbo ẹka to yẹ ko de.

Bo ti n ha iwe naa fun awọn ẹka yii lo n sọ pe wọn yoo da a pada foun laarin ọsẹ kan, bi gbogbo wọn ti n ṣiṣẹ lọ loun naa n da ṣe iṣẹ tirẹ labẹle, o fẹẹ wo o ko ma jẹ oun loun ṣe aṣiṣe, ati ko ma jẹ ọna mi-in wa ti irinṣẹ ti wọn n wi naa fi le ṣiṣẹ fun Naijiria, bi oun ba si ti ri iru ọna bẹẹ, ki oun le fọwọ si i fun wọn. Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun un pe iwadii ti oun ṣe, ati eyi ti awọn ẹka to n gbe iṣẹ fun alagbaṣe ni ọdọ wọn nibẹ ṣe, bakan naa ni kinni naa ku si, esi ti wọn si mu wa naa ni pe irinṣẹ naa yoo ṣoro lati lo ni Naijiria, ati pe ko yẹ ko jẹ ITT nikan ni wọn yoo gbe iru iṣẹ bẹẹ fun. Lẹyin naa ni igibmọ to n gbe iṣẹ iru eyi jade pepade nla, wọn ni ki wọn waa yẹ iwe iṣẹ ITT yii wo, bo ba jẹ eyi to ṣee ṣe ni. Kaakiri ẹka ileeṣẹ naa ati lati ọdọ awọn ṣọja, ati lati ọdọ ijọba apapọ lawọn aṣoju ti wa, wọn si fi ipade naa si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, 1974.

Ọjọ ti igbimọ yii yoo yẹ iwe ileeṣẹ Abiọla wo ni, ohunkohun ti igbimọ naa ba si ti gbe jade ni abẹ ge, koda ko si ohun ti kọmiṣanna, iyẹn Muritala funra rẹ, le ṣe si i. Bi ara ile ẹni ba lẹnu, oluwarẹ naa yoo lẹsẹ ni; ẹni ti ko ba si ni i jẹ keeyan jẹun yo, niṣe la oo kọ ọka iru ẹni bẹẹ mọ ounjẹ ẹni. Gbogbo bi Muritala ti buru to, to n ṣe oju koko si Akindele, oun naa jade, o si mu awọn eeyan tirẹ ti yoo lọ sipade naa, ti wọn yoo le fibo rẹyin Akindele. Muritala paṣẹ fẹni to wa lati ileeṣẹ ologun, bẹẹ lo paṣẹ fun darẹkitọ to n ri si iṣẹ ibanisọrọ, ẹni to jẹ bi ki i baa ṣe ohun to de, abẹ Akindele lo wa, ko sohun to kan oun ati Muritala rara. Ṣugbọn ija ti de, orin dowe, ọkunrin naa gan-an ni Muritala n lo lati rẹyin Akindele, oun naa si n ṣe iṣẹ rẹ bẹẹ, Ọgbẹni Lasọde ni. Muritala tun wa ẹni kan si meji mi-in, o dẹ wọn sipade naa, pe toun ni ki wọn ṣe.

Ni owurọ ọjọ ipade naa, Muritala ti ki i ba Akindele sọrọ tẹlẹ pe e, o si sọ fun un pe ipade to n lọ yii o, ko ri i pe awọn fi ọwọ si iwe iṣẹ ITT, nitori bi wọn ko ba fọwọ si i, ọrọ naa yoo di wahala gidi fun un. Nigba ti wọn de ipade yii loootọ, gbẹgẹdẹ gbina. Akindele ṣalaye gbogbo ọrọ, o si gbe awọn iwe ti wọn ti ko jọ lori iṣẹ ITT yii kalẹ, o waa sọ awọn idi ti ipade naa fi waye ati awọn ohun to fa ọrọ naa lati ilẹ, bo si ti n sọ ọ lo n ko ẹri kalẹ fun wọn. Awọn eeyan Muritala ninu ipade naa ja fitafita, iṣoro wọn ni pe awọn ootọ ọrọ to foju han pe iṣẹ naa ko le dara, bẹẹ lawọn irinṣẹ ti wọn n ko bọ ko le wulo, ti pọ ju ohun ti wọn le gba si abẹ ewe lọ. Gbogbo alaye ti kaluku ti ṣe lori ọrọ iṣẹ yii ni wọn yẹ wo nikọọkan, ko si si alaye kan to sọ pe ki wọn gbe iṣẹ naa fun ITT, tabi ki wọn ra irinṣẹ wọnyi lọwọ wọn.

Nigba tawọn ọmọ ti Muritala to wa ninu igbimọ ri ibi ti ina ọrọ yii n jo lọ, wọn ni ki awọn dibo si i, ohun ti ibo ba mu wa ni wọn yoo ṣe. Ni wọn ba dibo. Ṣugbọn nigba ti wọn dibo naa tan, awọn ti wọn ni ki wọn ma gbe iṣẹ yi fun ITT, pe wahala ni yoo mu wa, pọ ju awọn ọmọ Muritala ti wọn fẹ ki wọn gbe iṣẹ naa fun wọn ni gbogbo ọna lọ. Wọn tun tun kinni naa da silẹ, wọn tun yẹ ẹ wo, nitori awọn ọmọ Muritala yii ko mọ bi wọn yoo ṣe pada lọọ ba ọga wọn pe kinni naa ko ṣee ṣe. Ṣugbọn gbogbo bi wọn ti ṣe e to, ibi kọọ naa lo ja si fun wọn, awọn ti wọn wa nipade ta ku pe iṣẹ naa ko le ṣee ṣe, nitori pe ko yatọ si bii igba tawọn ITT fẹẹ waa lu wọn ni jibiti, bi wọn ba si lu jibiti naa tan, wọn yoo so ọwọ ijọba mọgi, wọn yoo maa ṣe wọn bo ṣe wu wọn lori ọrọ ati eto ibanisọrọ ni, nitori gbogbo iṣẹ naa ni yoo bọ si wọn lọwọ.

Nibi ni ipade naa pari si, ṣugbọn bo ti pari ni awọn darekitọ to di aṣoju Muritala yii ati Kọnẹẹli to wa lati ileeṣẹ ologun sare taara, o di ọdọ Muritala, nibẹ ni wọn wa ti wọn tilẹkun mọri, ni akọwe agba paapaa ba lọọ ba wọn. Ipade to yẹ ki wọn pe Akindele si, ko ṣẹni to darukọ ẹ nibẹ, nitori ẹjọ rẹ ni wọn n ro, ohun ti wọn n sọ ni pe oun lo ba nnkan jẹ, oun ni ko jẹ ki wọn fọwọ si iwe naa, oun lo n tapa si ofin Muritala, oun lo n sọ ara rẹ di Ọlọrun le minisita naa lori. Inu bi Muritala gidigidi, o n wa ọna ti yoo fi le Akindele danu nileeṣẹ naa kiakia. Nibi ipade ti oun ati awọn eeyan yii n ṣe lo ti paṣẹ pe ki wọn kọwe kan, ki wọn si gbe iwe naa jade. Ohun to wa ninu iwe yii ni pe yoo fun awọn darekitọ gbogbo laṣẹ lati maa lọọ ba Muritala ṣepade funra wọn, ti wọn yoo kuro labẹ Akindele, ti ọrọ kan ko si ni i gba iwaju rẹ kọja mọ.

Akindele gbọ gbogbo ọrọ yii, nitori wọn pada waa fun un ni lẹta pe bi eto iṣẹ wọn yoo ṣe maa lọ niyẹn. Ṣugbọn oun gẹgẹ bii ọga agba, ẹni to si ti pẹ lẹnu iṣẹ ijọba, oun mọ pe ko si ofin to faaye gba iru ohun ti wọn ṣe yii, eewọ patapata gbaa lo jẹ. Nitori bẹẹ, o mura lati ja ija naa, o ni ki i ṣe nitori ti ara oun, ṣugbọn nitori awọn mi-in ti wọn yoo tun wa nipo bẹẹ lọjọ iwaju ni. O mọ pe Ọgbẹni Lasọde, darẹkitọ to sọ ara rẹ di ọmọ Muritala yii lo wa nidii ọrọ yii, ọpọ awọn aṣiri ohun ti ko yẹ ko ṣe to ṣe pẹlu Muritala lo si ti tu si i lọwọ nibi ipade ti wọn ṣe. Ni Akindele ba ki gege mọlẹ, o si kọwe naa o kun, o fi ẹjọ Lasọde sun ọga wọn pata nileeṣẹ ijọba, iyẹn olori awọn oṣiṣẹ ọba. Ko da iwe naa duro lọdọ oun nikan o, o ha iwe na de ileeṣẹ olori ijọba ologun, o ha a de ọdọ awọn akọwe ijọba apapọ, o si fun Muritala ati akọwe agba rẹ, Lasọde naa si gba tirẹ.

N lọrọ ba di ariwo rẹpẹtẹ, aya Lasọde ja, nitori o mọ pe oun n lọ nidii iṣẹ ijọba ree, nitori oun naa kuku mọ pe awọn iwa ti oun hu ko dara, ṣugbọn ero pe ti wọn ba le yọ Akindele danu, Muritala yoo fi oun si ipo Akindele ni gbogbo ohun to n ṣe. Ṣugbọn lẹta yii ba nnkan jẹ, o si da wahala silẹ kaakiri. Nigba ti Muritala ri i bẹẹ, o pe akọwe agba ni ileeṣẹ eleto ibanisọrọ wọn yii, iyẹn Ọgbẹni Williams, o ni ki oun naa kọ lẹta ibinu, ko fi ẹjọ Akindele sun akọwe ijọba apapọ, ko ṣalaye pe ko fi ọwọ sọwọ pọ pẹlu awọn lati le mu ilọsiwaju ba ileeṣẹ awọn, kaka bẹẹ, gbogbo ohun ti awọn ba ti ṣe lo n ba jẹ, bẹẹ lo si n ri minisita fin. Akọwe agba to n jiṣẹ ti Muritala ran an yii ni ki wọn ṣeto ifiyajẹni to ba tọ si Akindele laarin ọjọ kan sikeji, nitori bo ba ṣe ohun to n ṣe yii ni aṣegbe, apẹẹrẹ buruku ni yoo jẹ fun awọn ọga keekeekee to n bọ lẹyin rẹ.

Lẹsẹkẹsẹ ni iwe ti de lati ọdọ akọwe agba fun ijọba ologun, wọn ni ki Akindele ṣalaye idi ti wọn ko ṣe ni fi iya jẹ ẹ pẹlu awọn ohun to ṣe yii, ni wọn ba fi awọn iwe ti Ọgbẹni Williams to jẹ akọwe ni ileeṣẹ eleto ibanisọrọ yii fi ranṣẹ si wọn ranṣẹ soun naa, wọn ni ko wo o, ko ri ohun ti awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ kọ ranṣẹ nipa rẹ. Ẹnu ya Akindele lati ri ohun ti Williams kọ nipa oun, paapaa nigba to jẹ ọrẹ ni wọn, ti wọn si ti jọ n ṣiṣẹ lati bii ọdun mẹrin sẹyin ki Muritala too de rara. Nigba ti Akindele ri i pe ọrẹ oun lo kọwe yii, to si ri gbogbo irọ to pa mọ oun, oun naa mura lati fesi ṣọwọ, n lo ba jokoo, ile ko ṣee lọ mọ, o sa gbọdọ fesi ni kutukutu owurọ ni. Awọn ohun aṣiri kan wa ti akọwe agba yii ati Muritala ti jọ n ṣe lẹyin ti Akindele ko mọ, ninu faili to ti fẹẹ fesi ọrọ rẹ lo ti ri i, n lo ba to gbogbo rẹ jọ, o si kọ iwe naa ni akọkun. Nigba ti iwe naa balẹ si ọdọ akọwe ijọba apapọ, niṣe lọrọ na wọlẹ ṣẹn-ẹn.

Akindele reti ki wọn pe oun, tabi ki wọn kọ iwe ifiyajẹni soun, tabi ki wọn tilẹ wi nnkan kan lori ọrọ yii, ko si kinni kan to jade nibẹ mọ, nitori to ba jẹ ohun kan yoo jade ni, Ọgbẹni Williams ni yoo jiya ibẹ, nitori aṣiri ti tu pe ko si ohun ti Akindele ṣe ti ko daa, oun Williams, ati awọn ti wọn n ba Muritala ṣepade idakọnkọ ni wọn n ṣe ohun ti ko dara. Fun odidi ọsẹ meji, Akindele ko gbọ kinni kan mọ, afi lojiji ti tẹlifoonu rẹ dun nijọ kan, ni ẹni to n pe e ba di Ọgbẹni George Ige, ẹni to jẹ akọwe agba ni ileeṣẹ to n ri si awọn iṣẹ gbogbo to ba jẹ tijọba, o ni kọmiṣanna oun ni ko waa ri oun kiakia. Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni kọmisanna, abi minisita, fun ileeṣẹ ode yii, ọkan ninu awọn alagbara ninu ijọba Gowon ni. Ẹnu ya Akindele nigba to gbọ pe Ọbasanjọ n pe e, ko si mọ idi to fi n pe oun, lo ba lọ.

Nigba to debẹ lo ri i pe nitori ọrọ to wa nilẹ, ọrọ iṣẹ ITT ati ti Muritala ni Ọbasanjọ ṣe ranṣẹ pe oun. O ya a lẹnu pe ọrọ naa ti di ohun ti gbogbo eeyan mọ, ṣugbọn inu rẹ dun lẹgbẹẹ kan pe oun yoo ri eeyan gidi kan ṣalaye ọrọ naa fun, ati bi ohun gbogbo ṣe ri. Nigba ti Ọbasanjọ gbẹnu le ọrọ naa, Akindele ko alaye balẹ, lati igba ti ọrọ naa ti bẹrẹ titi di igba ti wọn n kọwe ibinu si i, ti oun naa si n da esi pada fun wọn. Ni Ọbasanjọ ba ni ki Akindele sare lọ si ọfiisi rẹ, ko lọọ gbe faili to fi kọwe si ọdọ akọwe ijọba apapọ lori ọrọ lẹta ti akọwe agba naa kọ si wọn lọhun-un waa foun, oun fẹẹ yẹ ẹ wo daadaa ki ọrọ naa le ye oun. Ni Akindele ba sare lọ, nitori o ti ri onilaja ti yoo da si ọrọ naa bo ṣe yẹ. Ṣugbọn lẹyin ti faili naa ti de ọwọ Ọbasanjọ, ọtọ lọrọ ti oun naa bẹrẹ si i sọ, iyẹn lori iṣẹ ITT naa.

O sọ fun Akindele pe, “Ẹgbọn, ṣe ẹ mọ pe ti a ba ni ki a bẹ igi, a le bẹẹyan mọ. Ṣe e mọ pe ti ẹ ba diju jalẹ lori ọrọ yii, ṣe ẹ mọ pe araale yin, aburo yin, le n ṣe nibi yẹn!” Itumọ ọrọ naa ni pe bi Akindele ba n ba ileeṣẹ ITT ja, ti ko jẹ ki wọn gbe iṣẹ naa jade, ṣe o mọ pe Abiọla to jẹ araale oun loun n ṣe ni aidaa ṣaa. Akindele ṣalaye pe bẹẹ kọ, pe ti awọn ITT ba ti le wa irinṣẹ mi-in to ba eyi ti awọn ni nilẹ mu, ti owo rẹ si ba iye ti awọn to ku n ta tiwọn naa mu, oun yoo fọwọ si i pe ki wọn gbe iṣẹ naa fun un lai sọsẹ rara. O ni ohun ti oun n ja fun ni pe ko si bi iṣẹ yii yoo ṣe jade ti ko ni i pa Naijiria lara, gbese ni yoo da sọrun ijọba apapọ, bii ẹni to fi owo jona gan-an ni. Ọbasanjọ ni ko buru, o ni ki Akindele jẹ ki oun yẹ faili naa wo finnifinni, oun yoo gbe e lọ sile, oun yoo si ri awọn ohun to wa nibẹ. Bẹẹ ni Ọbasanjọ gbe faili naa lọ.

Ọlọrun lo yọ Akindele, bo ba ṣe pe ko ni ẹda awọn ohun to wa ninu faili naa, ti ko jẹ pe mẹta faili naa lo ṣe to ko meji si ọọfiisi to gbe ọkan lọ sile ara rẹ, nibẹ ni faili naa yoo poora si, nitori Ọbasanjọ gbe faili lọ, ko gbe e pada mọ. Akindele paara ọfiisi rẹ, ṣugbọn ko ni ri i, koda ko wa nile, nigba to su u lo yọnda faili ọrọ naa fun un. Bẹẹ ni gbogbo igba yii, ipade ti Gowon ni oun n reti esi iṣẹ ti oun gbe fun Akindele ti wọle tan, ka si ni ko si faili yii lọwọ rẹ, yoo ri pipọn oju Gowon ati ti awọn to ba ba pade nibẹ. Ṣugbọn faili wa lọwọ rẹ, ohun to si n reti ni ọjọ ipade naa ti wọn yoo kede. Ni ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, lo deede gba lẹta lojiji, ipade naa yoo waye lọjọ keji, ọrọ iṣẹ awọn ITT yii si lo ṣe pataki ju lọ ninu ohun ti wọn fẹẹ sọ nibẹ. Iroyin ti kan oun naa pe lọjọ naa ni wọn yoo le e lọ kuro nidii iṣẹ ijọba, wọn ni Muritala ti pari eto gbogbo, pe nibi ipade naa ni wọn yoo ti fẹyin Akindele ti, ko si sẹni ti yoo le da a pada sinu iṣẹ ijọba.

Kin ni yoo waa ṣẹlẹ si Akindele lọjọ ipade, ohun ti gbo bawọn ti wọn fẹran rẹ, ati awọn ti wọn ko fẹran rẹ paa n bi ara wọn leere niyen. Bẹẹ ipade ku ọla ni.

Ẹ maa ba a bọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply