Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (11)

*Idi abajọ ree o

Ọjọ nla kan ni ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 1974, jẹ ninu itan ijọba Naijiria, fun awọn ti wọn ba mọ itan naa daadaa. Ọjọ Aje, Mọnde, lọjọ naa, ọjọ ti igbimọ apaṣẹ ijọba ologun Naijiria igba naa n ṣe ipade wọn ni. Ohun kan ṣoṣo pataki naa ti wọn tori ẹ pepade yii ni ọrọ ija to n ṣẹlẹ lori iṣẹ ti ileeṣẹ eleto ibanisọrọ labẹ Ọgagun Muritala Muhammed gẹgẹ bii minisita fẹẹ gbe fun ileeṣẹ ITT to jẹ ileeṣẹ awọn MKO Abiọla. Muritala ti fi dandan le e pe wọn gbọdọ gbe iṣẹ naa fun awọn ITT, ṣugbọn ọga ẹka to n ri si eto ọrọ ibanisọrọ yii, Theophilous Akindele ni kinni naa ko le ṣee ṣe, nitori iṣẹ naa ko le ṣe Naijiria ni anfaani, bii ẹni to fowo ṣofo lasan ni. Ọrọ yii ti de ọdọ Yakubu Gowon ti i ṣe olori ijọba apapọ ati ti igbimọ yii, Gowon si ti paṣẹ pe ki wọn da iwe iṣẹ naa pada fun Akindele ko lọọ yẹ ẹ wo, nigba ti tọhun sọ pe oun ko mọ nipa ẹ rara.

Ni bayii, Akindele ti yẹ iwe wo, o si ti tun iwe mi-in kọ, ṣugbọn ibi kan naa lọrọ dori kọ, o ni iṣẹ naa ko ṣee ṣe ni. Ki ipade too bẹrẹ ni wọn ti fi iwe yii ranṣẹ si Gowon ati gbogbo ọmọ igbimọ to ku, nitori bẹẹ, ki i ṣe ohun tuntun fun gbogbo wọn, wọn ti mọ ibi ti ọrọ n lọ. Bi ẹsẹ igbimọ si ti pe ni ipade bẹrẹ, ohun kan naa ti wọn si fẹẹ sọ niyẹn: ọrọ iṣẹ ITT. Awọn ti wọn wa lori ijokoo nijọ naa ni Yakubu Gowon ti i ṣe alaga ati olori ijọba, Ọmọwe D. N. Graham Douglas ti i ṣe minisita fun eto idajọ; Ọmọwe R. A. B. Dikko ti i ṣe minisita fun eto igbokegbodo ọkọ; Shetima Monguno ti ṣe minisita fun eto iwakusa ati ina ijọba; Ọmọwe J. A. Adetoro ti i ṣe minisita fun eto idaṣẹsilẹ; Ọmọwe J. O. Okezie ti i ṣe minisita fun eto iṣẹ ọgbin; Oloye A. Y. Eke, minisita fun eto ẹkọ; ati Alaaji Kam Salem ti i ṣe ọga awọn ọlọpaa pata ati minisita eto ọrọ abẹle.

Awọn to ku nijokoo lọjọ ipade naa ni Ọgagun Hassan Katsina, ẹni ti i ṣe igbakeji olori oṣiṣẹ ni ọfiisi olori ijọba, to si tun jẹ minisita fun ọrọ awọn ileeṣẹ ọba; Ọgbẹni T. A. Fagbọla, igbakeji ọga awọn ọlọpaa pata, Ọmọwe Okoi Arikpo, minisita fun ọrọ ilẹ okeere; Alaaji Aminu Kano, minisita fun eto ilera; Ọgagun Muritala Muhammed ti i ṣe minisita fun eto ibanisọrọ; Ọgbẹni Lateef, Okunnu, minisita fun ọrọ iṣẹ tijọba n ṣe, ati Alaaji Shehu Shagari, minisita fun eto inawo. Awọn yii ni wọn peju sibi ipade naa, lọjọ naa ni wọn si mura lati fi ẹnu ọrọ jona lori iṣẹ ti ITT ni ki ijọba Naijiria gbe fawọn, pe awọn yoo ṣe iṣẹ naa daadaa. Nigba ti iwe iwadii awọn Akindele ti wa lọwọ gbogbo awọn ọmọ igbimọ to jokoo, alaye kan ko tun si mọ, ki wọn bẹrẹ ijiroro lori ọrọ naa ni. Ṣugbọn Gowon ko fi aaye ijiroro lori ọrọ naa silẹ, o doju kọ Akindele, o si wi bayii pe:

“Ọgbẹni Akindele, gbogbo ohun ti o sọ lori ọrọ iṣẹ yii ti o fi sọ pe ko ṣee ṣe la ti ri. A ti ka a ninu iwe ti o kọ. Ohun akọkọ ti o sọ ni pe irinṣẹ ti awọn araabi yii fẹẹ ko wa ko ba eyi to ti wa nilẹ mu, ko si ni i jẹ ki irinṣẹ tuntun wọnyi ṣiṣẹ pẹlu eyi ti a ti n lo tẹlẹ laelae. O tun sọ pe iye ti wọn ni awọn fẹẹ fi ṣe iṣẹ naa ti pọ ju, pe iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe ko to iye ti wọn fẹẹ gba rara. Lọna kẹta, o ni asiko ti wọn fẹẹ fi ṣe iṣẹ naa ti wọn da yii, pe wọn ko le pari iṣẹ ọhun nigba naa, wọn kan sọ bẹẹ ki wọn fi le ri iṣẹ yii gba ni. Awọn ohun to ṣe koko ti o ko fi fẹ ki a gbe iṣẹ naa fun awọn ileeṣẹ yii niyi. O jẹ yaa tete gba iwe ti o kọ yii pada, ki o lọọ tun un kọ ti yoo fi ba iṣẹ naa mu, ti igbimọ yii yoo si fi le fọwọ si iṣẹ ti a fẹẹ ṣe naa lai si idaduro mọ.” Gowon duro fungba diẹ, nigba to si ṣiju soke, o doju kọ, Akindele, o ni, “Abi o tun fẹẹ sọ nnkan kan!”

Akindele naa ko jẹ ko tutu, o yaa lo anfaani naa daadaa, o ni oun ni ọrọ ti oun yoo sọ. Lo ba tẹnu bọrọ tirẹ naa, o ni, “Ọlọla julọ, ẹ ṣe ti ẹ fun mi ni anfaani lati sọrọ niwaju yin. Bi alaye akọkọ ti ẹ wi yii ba ti le jẹ ootọ (iyẹn pe irinṣẹ ti wọn n ko bọ yii ko le ṣiṣẹ pẹlu awọn irinṣẹ tiwa ni Naijiria) o maa jẹ pe gbogbo igbesẹ to ku ti a ba gbe lori ẹ, igbesẹ asan ni. Atako keji ati ẹkẹta ti mo ṣe si aba yii naa fihan pe gbogbo ohun to wa nilẹ yii, ọgbọn jibiti ni. Bi wọn ṣe n sọ pe awọn fẹẹ pari iṣẹ naa ni oṣu mejidinlogun yii, wọn fẹẹ lo ọrọ naa ki wọn le fi gba owo ni, iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe yii, wọn ko le pari ẹ laarin ọdun mẹrin. Ṣugbọn nitori ki wọn le ri alaye ṣe lori owo ti wọn fẹẹ gba, owo to to ilọpo mẹwaa iye to yẹ ki wọn ṣiṣẹ naa gan-an, ni wọn ṣe ni awọn yoo pari ẹ ni aarin oṣu mejidinlogun yii, ni ohun ti awọn naa mọ pe ko ṣee ṣe.

“Amọ o, ko tilẹ waa jẹ iye ti wọn fẹẹ gba naa ree, ti mo ba ri i pe iṣẹ naa yoo yọri si rere, pe irinṣẹ ti wọn n ko bọ fun wa yii yoo ṣee lo, n ko ni i tẹsẹ duro rara lati mu aṣẹ ti ẹ pa lori ọrọ yii ṣẹ.” Nigba ti Akindele pari ọrọ yii, Gowon tun da a lohun pe, “O ṣe pupọ pẹlu gbogbo alaye ti o ṣe ati aṣiri ti o tu nidii ọrọ yii fun wa. Sibẹ naa, afi ki o ṣe ohun ti mo wi yii. Ki o mọ bi o ṣe fẹẹ lọọ tun iwe naa kọ, ki o si yọ gbogbo ohun ti a oo fi ṣe atako yii kuro nibẹ, inu iwe ipade wa nikan si ni gbogbo ohun ti o sọ yii yoo wa, ko ni i jade sita rara. Bi iṣẹ naa ba bẹrẹ, ti ko pari ninu oṣu kejidinlogun ti awọn araabi yii da, a jẹ pe iwọ lo jare, ti kọmiṣanna naa jẹbi niyẹn. Bo ba si jẹ iṣẹ naa pari nigba ti awọn ti wọn fẹẹ ṣe e yii ni yoo pari, a jẹ pe iwọ lo jẹbi, ti kọmiṣanna ẹ jare, ṣugbọn ko si ẹni kan ti a fẹẹ mu si eyi, lori iyẹn rara.”

Akindele mọ pe ọrọ to wa nilẹ yii ko daa, o si mọ pe Gowon naa mọ pe ko daa. Ṣugbọn Gowon ti ha si aarin awọn ṣọja ti wọn jẹ ọmọọṣẹ rẹ, ko fẹ ki wọn ri oun bii ẹni ti ko le paṣẹ fun oṣiṣẹ ijọba, bẹẹ ni ko si fẹ ki Muritala wo oun bii ẹni to n gbe si ẹyin oun Akindele. Ṣugbọn o mọ pe iṣẹ naa ko ṣee ṣe, ti wọn ba ṣe e, bi yoo ti ri naa loun wi yii. N lo ba dakẹ gbari, o n ronu lori ọrọ naa. Nibi to ti dakẹ yii naa ni Gowon ti tun pe e pada, o ni, ‘‘Ọgbẹni Akindele, iwọ la n duro de. Fun wa lesi o!” Ni Akindele ba fọ ọrọ loju. O ni, “Ọlọla ju lọ, pẹlu gbogbo ohun aiṣe-deede to wa ninu iṣẹ (ITT) yii, o maa ṣoro fun mi lati yọ gbogbo ẹ si ẹgbẹ kan ki n fọwọ si iwe yii fun gbogbo Naijiria, nigba ti mo mọ pe ohun ti ko ni i ṣee ṣe ni.  Bi a ba tilẹ ni ti owo ko ṣoro, ti a ni ti akoko ko ṣoro, ohun ti mo mọ ni pe irinṣẹ ti ITT fẹẹ ta fun wa yii ko ni i ṣiṣẹ nibi, ifowoṣofo ni.

Inu bi Gowon wayi, lo ba ni, “Ti o ba mọ pe o ko le fọwọ sowọ pọ pẹlu wa lori iṣẹ yii, ko si ohun meji ti mo le ṣe ju ki n da ẹ jokoo sile fun igba diẹ na lọ, bi minisita ẹ ati awọn to ku ba le pari iṣẹ naa, nigba ti wọn ba ṣe e tan, ti wọn yanju ẹ, wa a le pada sẹnu iṣẹ ẹ, igbakigba ti wọn ba too ṣe e tan ni ṣaa o!” Akindele ni oun fara mọ idajọ Gowon, nitori o mọ pe ko si ohun ti Gowon le ṣe ni. Bẹẹ ni Akindele jade nipade, ti wọn da a duro lẹnu iṣẹ fungba diẹ, nitori iṣẹ ITT, iṣẹ awọn Abiọla. Bo ti fẹẹ jade ni Yakubu Gowon tun pe e pada, o ni ọrọ to ṣẹlẹ nibi yii, eewọ ni o, ko gbọdọ jade ninu iwe iroyin, bi oun ba ri i ninu iwe iroyin kankan, oun Akindele yoo ri pipọn oju oun. Ṣe ẹni ti ori rẹ bajẹ mọ, ẹni ti yoo sọ fun un ti yoo dija lo n wa. Gowon mọ pe ohun ti awọn n ṣe ko daa, ṣugbọn nitori ibẹru awọn Muritala, o fọwọ si ohun ti ko dara. Ṣugbọn ọrọ naa jade lọjọ keji ninu Daily Times, ni gbẹgẹdẹ ba gbina!

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply