Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (13)

*Idi abajọ ree o (13)

Lọjọ ti Theophilus Akindele yoo pada si ẹnu iṣẹ ẹ, nnkan mi-in ṣẹlẹ si ọfiisi wọn. Loootọ ni ile iṣẹ ITT tawọn Abiọla ti gba iṣẹ ti wọn fẹẹ gba lọwọ ijọba apapọ nipa agbara Ọgagun Muritala Muhammed gẹgẹ bii kọmiṣanna (minisita) eto ibanisọrọ, ṣugbọn ọrọ naa ko tan ninu Muritala rara, ko fẹ ki Akindele pada sẹnu iṣẹ naa, nitori bo ba pada, o mọ pe ija awọn yoo tubọ maa gbilẹ si i ni. Nidii eyi, lọjọ to yẹ ki Akindele pada sẹnu iṣẹ  yii, niṣe ni Muritala ko awọn ṣọja si ẹnu geeti ati ayika ileeṣẹ wọn yii, to si paṣẹ pe bi wọn ba ri Akindele lọọọkan to ba n bọ, ki wọn gbebọn fun un ni. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ kọọkan ṣi wa ti wọn fẹran ọkunrin naa, wọn fẹran ọga wọn yii debii pe gbogbo ohun to n lọ ni wọn n pada sọ fun un. Bo ti fẹẹ gbera lati maa lọ sibi iṣẹ ẹ ni wọn pe e lati ibi iṣẹ naa, ni wọn ba sọ fun un pe awọn ṣọja ti kun ọfiisi ẹ o.

Awọn ṣọja kẹ, bawo lo ti jẹ. Wọn sọ fun un pe Ọgagun Muritala lo ni ki awọn ṣọja lu u, tabi ki wọn yinbọn fun un to ba fi le yọju sibẹ. Akindele naa gbọ, o yaa jokoo sile. Ṣugbọn ko jokoo bẹẹ, o pe akọwe ijọba ologun apapọ igba naa, o si sọ ohun to n lọ fun un. Iyẹn ni ko ni suuru, oun yoo fi ọrọ naa to Ọgagun agba Yakubu Gowon ti i ṣe olori ijọba leti. Nigba to sọ fun Gowon, ọrọ naa ya a lẹnu, o si ni oun ko mọ ibi ti Muritala ti ri awọn ṣọja to n lo, nigba ti ko si ninu baraaki kan to ti n ṣiṣẹ, to jẹ minisita ni, iṣẹ ijọba lo ku to n ṣe. Lẹyin naa ni Gowon paṣẹ, awọn ṣọja naa si kuro nibi ti wọn wa lọgan, o waa ku ẹyọ meji ti wọn n ṣọ Muritala funra ẹ, lẹyin naa ni wọn si pe Akindele pe ko maa lọ. Nigba ati Akindele ba ọna ẹyinkule wọle, to kan awọn ṣọja meji, o ti ro pe nnkan kan yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn ko sohun to ṣẹlẹ, awọn yẹn dide, wọn ki i lasan ni.

N loun naa ba wọle, o si jokoo si ọfiisi rẹ. Ẹni to kọkọ pe naa ni ọga rẹ, iyẹn Muritala ti i ṣe minisita, oun ṣaa ni olori pata fun ileeṣẹ ibanisọrọ ilẹ wa. Akindele pe e, o si ki i, o ni oun Akindele loun n sọrọ, oun fẹẹ fi ara oun han pe oun ti pada sẹnu iṣẹ ni. Muritala ki i ṣe ẹnikan ti i fi ibinu tabi aidunnu rẹ pamọ rara, bi ọrọ ba ti ri ni yoo wi, ko si kọ ohun ti ọrọ naa yoo da silẹ rara. Bi Akindele ti ki i pe oun ti pada si ẹnu iṣẹ, bẹẹ loun naa dahun pe o kaabọ, ṣugbọn ko fi sọkan ara rẹ pe fun igba diẹ loun yoo fi wa nileeṣẹ naa, nitori ko ni i pẹ ko ni i jinna ti yoo fi lọ patapata. Ọrọ naa ya Akindele lẹnu pe iru ọkunrin wo leleyii, to n ṣe ohun ti ko dara, to si ro pe ohun to dara loun n ṣe, to n lo agbara to ni nilokulo, to si n ṣe iṣe ‘ta ni yoo mu mi’. Ṣugbọn ko si ohun ti Akindele yoo ṣe nidii ọrọ yii, o gba kamu, o si jokoo jẹẹ, pe ohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ yoo ṣẹlẹ naa ni, gbogbo aye ni yoo si foju ri i.

Ni ọjọ kẹta ti Akindele debi iṣẹ, o n mura lati ba awọn ọga ẹka to wa labẹ rẹ ṣepade, ṣugbọn o beere gbogbo wọn, ko rẹni kan. Nibi to ti n beere idi ti wọn ko fi ti i debi iṣẹ ni iye aago naa ni akọwe agba ileeṣẹ wọn ti yọju si i, lo ba beere pe ki lo de ti oun Akindele ko lọ sibi ti Muritala ti n sọ ọmọ rẹ lorukọ. Akindele lanu, nitori Muritala ko kuku wi nnkan kan fun un, o si sọ bẹẹ fun akọwe agba yii, Ọgbẹni Williams. O ni bo ba ṣe pe Muritala pe oun ni, pe oun iba kuku lọ. Ṣugbọn bi oun ba fẹẹ lọ naa, oun ko ni i lọ lasiko iṣẹ, nitori gẹgẹ bii aṣa isọmọlorukọ nilẹ Yoruba, awọn ẹbi baba ati iya ọmọ to sun mọ wọn daadaa ni wọn maa n lọ sibẹ ni aarọ kutu, alẹ tabi ọwọ irọlẹ, lẹyin ti kaluku ba ti pari iṣẹ ẹ ni wọn yoo too lọ fun ariya isọmọlorukọ. Akindele lo ya oun lẹnu pe awọn ọga ileeṣẹ awọn fiṣẹ silẹ, wọn lọọ pe sibi isọmọlorukọ.

Theophilus Akindele

Ọrọ yii de eti Muritala gbẹyin, o si tubọ koriira Akindele si i, o ni o han pe ọkunrin naa ko ni i gbọran, ẹni kan ni yoo si fi ileeṣẹ naa silẹ fẹni kan ninu awọn mejeeji, ṣugbọn o ti daju pe ko ni i ṣee ṣe ki awọn mejeeji jọ maa ṣiṣẹ yii, ọga meji ko ṣaa ni gbe inu ọkọ kan ṣoṣo. Nitori ẹ lo jẹ nigba ti ọrọ ilu oyinbo ṣẹlẹ, ti Muritala n lọ siluu oyinbo ninu oṣu keje ọdun, to si yẹ ko mu Akindele dani nigba to jẹ ọrọ nipa iṣẹ ẹrọ ibanisọrọ lo n ba lọ, ko mu Akindele dani, kaka bẹẹ, o mu igbakeji akọwe ijọba, Festus Adesanoye, atawọn mi-in, o ni ki wọn jẹ ki awọn jọ lọ. Ninu oṣu keji ni wọn lọ, eto ti wọn si ṣe ni pe wọn yoo lo bii ọsẹ mẹrin, ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ni 1975 yii, naa ni wọn yoo si pada de. Ki i ṣe pe Muritala dagbere fun Akindele taara bẹẹ, o kan gbọ lilọ yii lati ẹnu akọwe agba ni. Oun naa si dakẹ, o ni alọ yoo dara, abo yoo sunwọn.

Bẹẹ ni Muritala gbera to lọ, wọn si n reti rẹ ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, 1975. Ṣugbọn ni ọsan ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, Muritala tẹlifoonu si ọfiisi wọn, o fẹẹ ba Williams ti i ṣe akọwe agba sọrọ. Ṣugbọn Williams ko si nibẹ, n lo ba sọ pe ko lọọ pe Akindele waa foun. Akindele ko fẹẹ lọ, ṣugbọn nigba ti akọwe naa bẹ ẹ, o gba lati lọọ ba minisita wọn yii sọrọ. Ko fẹẹ lọ nitori ko kuku mọ kinni kan nipa irin-ajo naa, wọn ko si dagbere fun un, ki waa ni toun lati gbọ ohun ti wọn yoo jọ sọ laarin ara wọn. Paapaa nigba to ṣe pe lasiko naa, ko si Gowon nile, oun ti lọ sibi ipade awọn ajọ iṣọkan orilẹ-ede Afrika ti wọn n pe ni OAU, o si mọ pe bi Muritala ba gbe iṣe rẹ de, ko si ẹni ti yoo gba oun. Nitori awọn nnkan yii ni ko ṣe fẹẹ lọ. Ṣugbọn nitori pe akọwe yii bẹ ẹ, o lọọ gbe tẹlifoonu naa, o si ṣe ọkan akin lati ba Muritala sọrọ.

Ohun to n reti ọtọ ni o, ṣugbọn ohun to ba yatọ pata. Ohun ti oun n reti ni ki Muritala ba a sọrọ lati ilu oyinbo, nibi to wa lọhun-un, ṣugbọn nigba to gbe foonu, niṣe ni Muritala sọ fun un pe Kano loun ti n sọrọ o. Ọrọ naa ya Akindele lẹnu gan-an. Ohun to si tun ya a lẹnu ju ni pe Muritala to maa n binu, to si maa n sọrọ laulau si i ko ṣe bẹẹ, suuru nla lo fi ba a sọrọ pẹlu ọwọ. O ni, ‘Ọgbẹni Akindele, ṣe daadaa ni o. Jọọ, ba mi sọ fun Ọgbẹni Williams pe mo ti de si Kano, to ba si di aarọ ọla, mo maa pada wa sibi iṣẹ!’ Ni Akindele ba ki oun naa daadaa, o si beere lọwọ rẹ pe ṣe ko si nnkan kan, pe ipari ọsẹ to n bọ lọhun-un lawọn ṣi n reti rẹ, ṣe ko si kinni kan to fi de ni pajawiri. Muritala ni ko si, alaafia ni, bi oun ba de lọla, awọn yoo maa sọ ọ. Bẹẹ ni wọn jọ sọrọ bii ọmọluabi meji, wọn si kira pe o digbooṣe.

Ni bii aago marun-un aarọ ni Akindele ji ni ọjọ keji, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 1975, ọjọ keji ti oun ati Muritala sọrọ ni, ti Muritala si sọ pe Kano ni oun wa. Bi oun ti ji ni aago marun-un yii, bẹẹ ni ọkan ninu awọn maneja ileeṣẹ wọn pe e, to si sọ fun un pe awọn ṣọja ti gba ileeṣẹ tẹlifoonu yii, ohun ti oun si n gbọ ni pe awọn ṣọja kan ti fibọn gbajọba o. Ko si Gowon nile, akọwe ijọba apapọ naa ko si nile, ko si si ẹni ti Akindele le sare pe ko sọ ohun to n lọ fun un. Nigba to ronu bẹẹ lo ranti akọwe agba ileeṣẹ wọn, o si tẹlifoonu si i. Ṣugbọn tọhun ko gbe e. Nigbẹyin, o ranti lati gbọ redio ilu oyinbo, BBC, n lo ba gbe e sibẹ, aago mẹfa owurọ ni. Awọn yii ni wọn royin pe awon ṣọja kan ti Muritala jẹ olori wọn ti fibọn gbajọba kuro lọwọ Yakubu Gowon, ati pe Muritala Muhammed ni olori wọn. Muritala kẹ! Akindele fidi janlẹ!

Murtala Muhammed

Nigba ti ilẹ yoo fi mọ daadaa, iroyin naa ti kari igboro, kaluku si ti mọ pe Muritala ti gbajọba. Ọjọ naa ni Muritla funra ẹ jade lori redio lo sọrọ, to sọ idi ti awọn fi gbajọba kuro lọwọ Gowon. O ni nitori ti ọkunrin naa ko fẹẹ gbejọba fawọn oloṣelu ni, ati iwa ibajẹ loriṣiiriṣii ti awọn eeyan n hu labẹ ijọba rẹ. Akindele gbọ ọrọ naa, o poṣe ni. Bi awọn kan ba wa ti wọn n huwa ibajẹ, ti wọn jẹ akowo ijọba jẹ, ṣe ẹnu Muritala leeyan yoo ti gbọ ọ ni, Muritala to mọ pe ileeṣẹ olowo nla ti awọn ITT gba, wọn fi iṣẹ naa lu jibiti ni, wọn si fi ko owo Naijiria jẹ, to si jẹ oun gan-an lo wa nidii ẹ, ṣe o fẹẹ sọ pe oun ko mọ ni, abi ko ye oun. Akindele mọ pe ọrọ naa ju ohun ti Muritala n sọ fawọn eeyan lọ. O mọ pe nitori awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn jẹ ọga, ti Gowon si gbojule fun ohun gbogbo to ba fẹẹ ṣe, ati nitori oun gan-an alara ni wọn ṣe gbajọba yii.

Muritala ko fẹ ohun ti Gowon ṣe foun nipa ọrọ Akindele. O fẹẹ le Akindele ni, o si fẹ ki Gowon fiya jẹ ẹ gidi pe o ri oun ọga ṣọja fin. Ṣugbọn Gowon ko le ṣe bẹẹ, nitori o mọ pe Akindele ko ṣe kinni kan fun un, ati pe iṣẹ ọkunrin naa lo n ṣe. Eyi ko tẹ Muritala lọrun, nitori o ro pe abuku ni wọn fi kan oun loju awọn ologun to ku, agaga loju awọn ti wọn bẹru oun, ati awọn ti oun paṣẹ fun. Lọrọ kan, ọrọ Akindele wa ninu ohun to jẹ ki ifipagbajọba lọwọ Gowon yii ya kankan, koda, bo tiẹ jẹ pe awọn kan ti n gbero bẹẹ lọkan tẹlẹ. Nitori bẹẹ, gbogbo alaye ti Muritala n ṣe lori idi ti awọn fi gbajọba lọwọ Gowon, ko si eyi to wọ Akindele leti nibẹ, nitori o mọ lọkan ara rẹ pe irọ ni wọn n pa, ko si ootọ kan bayii ninu ọrọ naa. Nibẹ lo si jokoo si ṣulẹ ọjọ naa, to n reti ohun ti yoo ṣẹlẹ nidii ijọba tuntun to ṣẹṣẹ de naa.

Kinni kan waa ṣẹlẹ si i loru ọjọ ti Muritala gbajọba yii. O ti to aago kan oru ọgbọnjọ, oṣu keje yii, bẹẹ ni tẹlifoonu rẹ dun ganran-un, ganran-un, nigba ti oun naa ko kuku si ri oorun sun, lo ba sare gbe e. Ohun to ya a lẹnu ju ni pe Muritala to ṣẹṣẹ gbajọba, to si di olori orilẹ-ede lanaa yii lo pe e laarin oru. Ohun ti Muritala sọ bo ti ri i pe Akindele dahun ni pe, ‘Ọgbẹni Akindele, Muritala lo n sọrọ yii o. Nigba ti baba isalẹ ẹ si ti lọ bayii, kin ni iwọ naa n duro ṣe, abi nigba wo lo n lọ!’ Ọrọ naa jo Akindele bii ina, abi nigba toun naa mọ pe gbogbo agbara ijọba Naijiria pata, ọwọ ẹni to wa niyi, ara to ba si wu oun ni yoo fi oun da, ko si baba isalẹ kan loootọ mọ ti oun yoo fi ẹjọ sun, ohun ti Muritala ba ṣe foun, aṣegbe ni. Ṣugbọn Akindele ṣe bii ọkunrin, o bẹrẹ si i da ọrọ sile wẹẹrẹ, afi bi ẹni pe o ti ronu kinni ọhun tẹlẹ ni.

O sọ fun Muritala pe ipo agba lo bọ si yii, agba si ti kan an naa ree, ko ma jẹ ki awọn ṣoro bii ewe mọ. O ni ko gbagbe ọrọ atẹyinwa, ko gbagbe gbogbo ohun to ṣẹlẹ, ko lo ipo rẹ bii ti olori ijọba, ko si fi tun gbogbo Naijiria ṣe. O ni bi awọn ba jọ wa nidii eto idagbasoke ijọba rẹ, awọn yoo le ṣe nnkan to dara fun orilẹ-ede awọn. O ni bo ba jẹ ti igba ti oun yoo kuro ni, orilẹ-ede oun ni Naijiria, oun ko si ni ibikan ti oun fẹẹ lọ, bẹẹ ni oun ko ṣetan lati kuro nibi iṣẹ oun, afi ti ijọba ba ni awọn ko fẹ oun mọ, pe ohun to kan oun bayii ni bi oun yoo ṣe duro tọkantọkan, ti oun yoo si ri i pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ibanisọrọ gbogbo naa duro ṣinṣin lẹyin ijọba tuntun yii, ki gbogbo eto ti wọn ba dawọ le le jẹ aṣeyọri. Ọrọ naa ja bọ leralera ni, ko si jọ pe Muritala paa mura silẹ fun iru ọrọ bẹẹ, n lo ba sọ tẹlifoonu silẹ lọhun-un, ko si tun pe e pada mọ. Ni Akindele naa ba fẹyin lelẹ, ṣugbọn oorun ko wa o.

Ogagun Yakubu Gowon

Ko pẹ rara ti awọn Muritala gba ijọba ti wọn bẹrẹ si i le gbogbo awọn ọga iṣẹ ijọba danu, gbogbo ẹni ti wọn ba si ti daju sọ, wọn yoo le e lọ lẹnu iṣẹ ọba ni, wọn yoo fẹyin wọn ti ni tipatipa. Lojoojumọ ni wọn n le wọn bẹẹ, ojoojumọ ni wọn n da awọn ọga wọnyi duro. Akindele taku, ko lọ. Ki i ṣe pe ko fẹẹ lọ, ṣugbọn faili ti wọn ni ki wọn fi wadii ọrọ rẹ wo, gbogbo ohun ti wọn sọ pe ki wọn maa wadii, to jẹ ti wọn ba ti ri ẹyọ kan pe ninu iwe awọn oṣiṣẹ yii, wọn n le tọhun lọ ni, ko si ẹyọ kan bayii ti wọn ri ninu faili Akindele, nitori bẹẹ ni wọn ko ṣe le le e lọ. Nigba ti wọn wadii iwe naa lakọọkọ ti wọn ko ri ibi ti wọn yoo gba le e, wọn tun ni ki wọn yẹ ẹ wo lẹẹkeji, wọn tun ṣe bẹẹ, wọn ko ri i, nitori ẹ lo ṣe jẹ pe bo tilẹ jẹ pe wọn ti le gbogbo awọn ẹlẹgbẹ ẹ kuro lẹnu iṣẹ yii, ko si ẹsun ti wọn ri ka si i lẹsẹ, wọn ko si le le e lẹnu iṣẹ ọba.

Ṣugbọn lọjọ kan ninu bi Muritala, lo ba pe awọn onṣẹjọba rẹ, o ni oun ko fẹ ẹ mọ, boya Akindele ṣe kinni kan tabi ko ṣe kinni kan o, wọn gbọdọ le e kuro lẹnu iṣẹ ijọba naa gan-an. Njẹ kin ni ki wọn kọ sinu iwe ẹ pe o ṣe? Ọjọ naa jẹ ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun 1975. N ni won ba ṣe bẹẹ le Akindele, bo tilẹ jẹ wọn ko ri ẹsun ka si i lẹsẹ. Akindele wo ọrun titi, ko si ibi ti yoo gba, o si ya a lẹnu pe ile aye buru to bayii, nibi ti wọn ti n fi ibi san iṣe rere. Ṣugbọn ohun to tun ya a lẹnu ju ni pe Muritala to ṣe gbogbo eleyii paṣẹ ki wọn san owo-oṣu ati gbogbo owo ti wọn jẹ Akindele fun un laarin ọsẹ kan pere, bo tilẹ jẹ pe awọn mi-in ti wọn ti fẹyinti lati bii ọdun kan ko ti i ri owo tiwọn gba, owo ti wọn si san fun un ki i ṣe kekere o. Yatọ si eyi, Muritala ni ki wọn sọ fun Akindele pe ile ijọba to n gbe n’Ikoyi, o le wa nibẹ titi di oṣu mẹfa tabi ju bẹẹ lọ, titi ti yoo fi ri ile tirẹ.

Ko si ẹlomiiran ti wọn n ṣe eyi fun ninu awọn oṣiṣẹ ijọba, ko si si idi ti wọn fi n ṣe eleyii ju pe Muritala funra rẹ mọ pe ko si idi kan ti wọn fi gbọdọ le Akindele kuro lẹnu iṣẹ, ati pe ohun ti wọn ṣe fun un ko dara. Paripari rẹ ni pe laarin ọsẹ kan ti wọn le Akindele kuro nibi iṣẹ yii, awọn ajọ orilẹ-ede agbaye to n jẹ United Nations kọwe si i pe awọn gbọ pe wọn ti le e kuro nibi iṣẹ ijọba, ṣugbọn iṣẹ wa lọdọ awọn ni ilu oyinbo to le ṣe fun eto ibanisọrọ, awọn fẹ ko maa bọ ko waa ṣe e. Owo ati okiki, ati agbara ileeṣẹ ti wọn ti pe Akindele si yii pọ ju ti Naijiria to ti n ṣiṣẹ tẹlẹ lọ, nigba to jẹ ileeṣẹ agbaye ni. Ṣugbọn iṣoro kan wa nibẹ, iṣoro ibẹ na si ni pe ijọba Naijiria gbọdọ fọwọ si i. Bawo ni olori ijọba to n ba oun ja, to si jẹ oun lo le oun nibi iṣẹ yoo ṣe fọwọ si i pe ki wọn gbe iṣẹ agbaye foun, o mọ pe bi ọrọ naa ba de eti Muritala, yoo fa iwe naa ya ni.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ, nitori nigba ti kinni naa de eti Muritala, ohun to sọ fawọn ti wọn kọkọ gbe iwe naa pamọ ni pe oun ti sọ fun wọn pe Akindele ko ṣe kinni kan foun o, awọn ko kan le jọ ṣiṣẹ ni nitori oninu-fufu lawọn mejeeji. Bayii ni Muritala fọwọ si i ki wọn gbe iṣẹ agbaye naa fun Akindele, to si kuro niluu oyinbo, to gba Geneva lọ, gẹgẹ bii oṣiṣẹ United Nations. Iruu eleyii ko ṣẹlẹ si oṣiṣẹ miiran lasiko naa, o si fi iru eeyan ti Akindele i ṣe han, ati bo ṣe mọ iṣẹ rẹ bii iṣẹ to. Ṣugbọn nnkan mi-in tun ṣẹlẹ.

Nigba to di oṣu kẹfa geere ti Muritala gbajọba, o ran Ọgagun Henry Adefowope si Geneva, o ni ko lọọ ba oun pe Akindele wa. Ẹnu ya Akindele lati ri oniṣẹ Muritala. O kọkọ fẹẹ ni oun o lọ, ṣugbọn nigba ti Adefowope ni ọga sọ pe afi ko maa ba oun bọ, o tẹle e. Nigba ti Akindele de Naijiria, o lọ si ọdọ Muritala. Nibẹ ni Muritala ti ṣalaye fun un pe nigba ti oun di olori ijọba, oun ti ri awọn ohun toun ko ri ri, oun ti ri awọn ohun to ṣẹlẹ, ko si si ohun meji ti oun fẹ ju ki Akindele waa pada sidii iṣẹ rẹ, ki awọn fun un ni oye tuntun, ko le waa ba oun tun ileeṣẹ naa ṣe. Loju Ọbasanjọ ni Muritala ti n bẹ Akindele bẹẹ, o si ya ọkunrin naa lẹnu gan-an. O ṣalaye fun un pe nigba to ba de, oun yoo pe awọn ti awọn jọ n ṣiṣẹ nigba naa siwaju ẹ, oun yoo si paṣẹ ki kaluku sọ irọ oriṣiiriṣii ti wọn waa pa fun oun nipa Akindele yii, nigba naa ni yoo mọ idi ti oun ṣe hu gbogbo iwa ti oun hu si i. Lọrọ kan, wọn bẹ Akindele ko waa gba iṣẹ rẹ pada, Akindele si ni ki wọn fun oun ni ọjọ kan si meji, ki oun tun ọrọ naa ro daadaa.

Ko si ohun meji to fa ironupiwada Muritala yii ju pe o ti ri i pe gbogbo ọrọ ti Akindele sọ nipa ITT lo ri bẹẹ. Wọn ko le pari iṣẹ nigba ti wọn ni wọn yoo pari ẹ, wọn tun n beere owo si i, Muritala si ni oun ti yiwa pada, oun ko fẹẹ ko owo Naijiria jẹ lasiko ti oun n ṣe olori ijọba. Idi niyi to fi jẹ awọn eeyan bii Akindele lo ku to n wa kiri lati ba awọn tun ohun to bajẹ ṣe. Ṣugbọn lọjọ keji ti Akindele ati Muritala sọrọ, ohun ti wọn ko ro ṣẹlẹ lojumọmọ. Irọlẹ lọjọ Alamisi ọjọ kejila, oṣu keji, 1976, ni wọn sọrọ, asiko ti Akindele si n mura lati lọọ pada ri Muritala ni owurọ ọjọ keji lori ọrọ ti wọn sọ ti, iroyin lo gbọ pe wọn ti pa Muritala danu pẹlu ibọn. Lọjọ naa lawọn Dimka fibọn gbajọba lọwọ ẹ. Nibẹ ni gbogbo ọrọ naa pari si.

One thought on “Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (13)

  1. Beeni ohun to sokunkun loju omo Aadama kedere lohan niwaju Oba-adeda.
    Tani eni na ti aafi owo si abiya re tiko nirun, emi ama so ninu oro mi pe kosi malaika nini awa eda eniyan.

Leave a Reply