Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (14)

*Idi abajọ ree o

Gbogbo ohun to ṣẹlẹ pata laye ijọba Yakubu Gowon ati ti Muritala nipa ileeṣẹ ITT ati Moshood Abiọla to ni in ni Naijria, gbogbo ẹ lo wa lọwọ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ to n du ipo Aarẹ Naijiria lorukọ ẹgbẹ oṣelu UPN ni 1979. Bi ọrọ naa si ṣe jẹ ni pe ọkan ninu awọn ti wọn ti Theophilus Akindele lẹyin to fi le fi gbogbo ọkan ati agbara rẹ ja, Awolọwọ ni. Ṣaaṣa ni ohun to n lọ nigba naa ti Akindele ko jẹ ki Awolọwọ mọ, ṣe Awolọwọ naa ti wa ninu ijọba Gowon tẹlẹ ki wahala Akindele yii too bẹrẹ. Nigba ti Awolọwọ fi wa gẹgẹ bii igbakeji olori ijọba apapọ, ati minisita fun eto inawo, Akindele mọ pe iru iwa palapala bẹẹ ko jẹ ṣẹlẹ, koda ko sẹni ti yoo hu u loju baba naa, nigba ti Awolọwọ lọ tan ni nnkan bẹrẹ si i daru loju gbogbo wọn. Nidii eyi, bi ọrọ naa ti n lọ ni Akindele n fi to Awolọwọ leti, ti Awolọwọ si  n fi i lọkan balẹ pe ko sohun to buru, tabi to lodi sofin ninu ohun to n ṣe.

Ṣugbọn pẹlu pe Akindele ko ṣe ohun to lodi sofin, pẹlu ẹ naa ni Yakubu Gowon le e kuro nibi iṣẹ fungba diẹ, nitori Muritala, ati awọn ologun to ku. Nigba ti wọn si le e nibi iṣẹ naa tan, awọn eeyan yii fi ailojuti ati iwa jẹgudujẹra gbe iṣẹ ti wọn tori rẹ ba a ja fun ileeṣẹ ITT, ileeṣẹ awọn Abiọla, pẹlu owo buruku ti ẹnikẹni ko gba iru rẹ ri ni Naijiria, ti ọrọ naa si jẹ laarin Abiọla ati Muritala, ati awọn ologun diẹ kan ninu ijọba Gowon. Bi wọn ti gbe iṣẹ naa fun Abiọla ati ileeṣẹ rẹ tan, bẹẹ ni awọn Gowon tun kọwe pada si Akindele pe ko maa waa ba iṣẹ rẹ lọ, awọn ti yanju ọrọ naa, awọn ti yanju ohun ti awọn ni ko ṣe to loun ko le ṣe. Bẹẹ ki i ṣe pe ko le ṣe e, o ni oun ko ṣe e nitori ko ba ofin mu ni, ati pe ileeṣẹ to fẹẹ gba iṣẹ naa lọwọ ijọba Naijiria, ileeṣẹ ITT, wọn kan fẹẹ fi iṣẹ ọhun lu ijọba ni jibiti ni, Muritala to jẹ minisita si mọ si i.

Theophilus Akindele

Nigbẹyin, lẹyin ti wọn ti gbe iṣẹ fun awọn ITT, ti wọn ti fun wọn lowo tan, wọn ri i pe gbogbo ọrọ ti Akindele sọ lo bẹrẹ si i ṣẹ. Akọkọ ni pe ITT ko bẹrẹ iṣẹ naa nigba ti wọn ni awọn yoo bẹrẹ, wọn ni awọn ṣẹṣẹ n ṣa awọn ojulowo irinṣẹ kan jọ ni, ko si pẹ lẹyin naa ni wọn kọ iwe beere aaye pe ki ijọba apapọ fun awọn ni aaye si i o, nitori iṣẹ ti awọn ro pe awọn yoo pari rẹ lasiko ti awọn da tẹlẹ, awọn o le pari rẹ mọ, awọn yoo tubọ maa fi gbogbo agbara awọn ṣiṣẹ naa lati ri i pe o pari kia. Iwe ti wọn kọ yii ko de ọdọ awọn ti wọn n ṣejọba apapọ mọ, iwọnba inu faili ileeṣẹ eto ibanisọrọ, labẹ Muritala ni iwe naa lọ, ko si si ẹni ti wọn bi daadaa ti yoo waa ni oun yoo gbe iwe naa sita, tabi ti yoo tu aṣiri iwe yii fun awọn oniroyin kankan. Ko tilẹ si ẹni ti yoo beere ibi ti awọn eeyan naa ba iṣẹ wọn de lọwọ Muritala, gbogbo wọn lo ṣa a mọ pe oun lo mu Abiọla ati ITT wa, wọn kan n wo o ni.

Ko tun pẹ lẹyin naa ni ITT tun kọwe mi-in, pe owo ti awọn kọ yii paapaa, awọn ṣi owo naa ṣẹ ni, awọn owo naa yoo maa le si i bi iṣẹ ba ti ṣe n lọ si, nitori awọn yoo fẹẹ maa lo irinṣẹ igbalode fun wọn si i. Ọrọ naa ko ni ariyanjiyan ninu mọ, nitori lẹyin ti Akindele ti pada de, wọn ko pe e si ọrọ kan to ba ti jẹ mọ ti ileeṣẹ ITT, tabi to jẹ mọ owo ti wọn n gba, wọn ko jẹ ki wọn gbe faili de ọdọ rẹ, bẹẹ lo jẹ oun lo yẹ ko maa fọwọ si i ko too lọ si ọdọ minisita yii, iyẹn Muritala funra ẹ. Nigba ti wọn ko si waa gbe faili fun un yii nkọ! Ṣugbọn ohun ti Muritala ko mọ ni pe ko si ohun to n lọ ti Akindele ko mọ, nigba to jẹ ọga iṣẹ ijọba ni, awọn ọmọ tirẹ naa wa nibẹ, koda ki wọn maa fi han Muritala loju pe tirẹ lawọn i ṣe. Gbogbo faili, gbogbo owo ti ITT ṣi n beere, gbogbo ẹ naa lo n de ọdo Akindele, to n ko o pamọ, awọn iwe yii si pada de ọwọ Awolọwọ.

Murtala Muhammed

Eyi to si waa buru ju ni pe lati inu ọdun 1974 si ibẹrẹ 1975 yii, lati igba naa ni ileeṣẹ ITT yii ti bẹrẹ si i rẹ Naijiria jẹ, ko si igba kan ti wọn ko ni i gbe iwe owo tuntun mi-in wa, yatọ si ojulowo iṣẹ ti wọn ni awọn fẹẹ ṣe ti wọn si ti gba owo rẹ. Boya eleyii ko ni i dun awọn eeyan ti wọn mọ nipa iṣẹ yii to ba jẹ iṣẹ ti ITT ni awọn yoo ṣe yii, wọn kuku ṣe e loootọ bi wọn ti wi, ti iṣẹ naa si jalẹ geere. Ṣugbọn iṣe naa ko lọ rara, awọn irinṣẹ ti wọn si ko wa da eto tẹlifoonu to wa nilẹ ru debii pe tẹlifoonu Naijiria ko ṣiṣẹ daadaa mọ lati igba naa lọ. Gbara ti Muritala di olori ijọba to bẹrẹ si i ri awọn aṣiṣe wọnyi naa lo pe Akindele pada pe ko waa ba oun tun nnkan ṣe, to si tọrọ aforijin lọdọ rẹ. Ṣugbọn Akindele ti gba iṣẹ mi-in niluu oyinbo, nigba ti Muritala si ti ku lojiji, ko wulẹ pada si ọdọ wọn mọ. Bo tilẹ pada, ko jọ pe Ọbasanjọ to ṣẹṣẹ gbajọba yoo gbe iṣẹ nla naa fun un, nitori ọrẹ Abiọla loun Ọbasanjọ nigba naa, o si mọ bi ọrọ naa ti jẹ.

Ṣebi faili ti Akindele fi sọ pe iṣẹ ti ITT fẹẹ ṣe fun Naijiria ko ni i dara ati pe wọn kan fẹẹ maa rẹ Naijiria jẹ ni wa lọwọ Ọbasanjọ, ti ko gbe faili naa pada fun Akindele nitori Abiọla, ṣe oun ni yoo waa ni ohun ti awọn Abiọla n ṣe ko dara lẹyin to ti gbajọba. Bẹẹ lo ṣe jẹ lati 1975 yii, titi ti awọn Ọbasanjọ fi gbajọba ni 1976, ati titi di asiko ti wọn fẹẹ dibo ni 1979, bi ileeṣẹ NITEL ti n bọ ninu wahala kan ni wọn n ko sinu wahala mi-in, bẹẹ ni ko si tẹlifoonu fun awọn ọmọ Naijiria lati lo gẹgẹ bii ileri ti ileeṣẹ ITT ti ṣe. Nibi ti wọn ba ti ri agolo tẹlifoonu, wọn yoo ni ko si nọmba ti wọn fẹẹ fun wọn. Nibi ti wọn ba ti ri nọmba, wọn yoo ni ko si agolo foonu ti wọn yoo gbe wa si ile wọn, awọn ti wọn si ti ni nọmba ati agolo tẹlifoonu nile, apoti naa le ma ṣiṣẹ fun ọpọlọpọ ọjọ, ti yoo kan lọ gbari ni. Bẹẹ ITT ko yee gbowo lọwọ ijọba.

Ogagun Yakubu Gowon

Awọn apoti tẹlifoonu ti wọn n ri mọlẹ kaakiri Naijiria, ti wọn ni eeyan yoo sanwo sinu rẹ, yoo si bẹrẹ si i sọrọ, nitori tẹlifoonu naa yoo maa ṣiṣẹ, iṣoro ni eleyii naa jẹ, nitori awọn mi-in yoo sọrọ, awọn mi-in ko si ni i sọrọ rara ni. Ko pẹ rara ti awọn ile-tẹlifoonu naa fi n bu, ti awọn apoti ti wọn gbe kalẹ si oju titi si n wo lulẹ funra wọn, kinni naa si bẹrẹ si i bajẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria ko ri i lo fun igba pipẹ. Bẹẹ lo jẹ lọdọọdun ni ijọba yoo ya owo kan sọtọ fun iṣẹ tẹlifoonu yii, ileeṣẹ ITT naa ni owo naa yoo si maa lọ, nitori wọn ti ṣee debii pe awọn nikan naa lo n ṣeto ati iṣẹ tẹlifoonu fun Naijiria yikayika. Bo tilẹ jẹ pe awọn ijọba yii mọ pe kinni naa ko dara, ati pe gbogbo ọrọ ti Akindele sọ lo n pada waa ṣẹ yii, ko si ohun ti wọn ri ṣe si i. Ohun to si fa a ti Awolọwo fi sọrọ naa jade pe awọn yoo yẹ iṣẹ ITT wo ree, ni ọrọ naa ba ka Abiọla lara.

Ṣugbọn ki i ṣe Abiọla nikan ni ọrọ naa ka lara. Gbogbo awọn ti wọn mọ nipa ohun to ṣelẹ nigba naa ni. Gbogbo awọn ti wọn mọ pe ti Awolọwọ ba tudii Abiọla ati ileeṣẹ ITT rẹ wo, ọrọ naa yoo kan awọn gan-an ni o, iyẹn awọn ologun ti wọn n ṣejọba. Bẹẹ ni tootọ, ko si bi wọn yoo ti tan ina sidii ọrọ yii ti wọn ko ni i mọ ibi ti owo buruku ti ile-iṣẹ ITT n gba n wọlẹ si, ati awọn ti MKO Abiọla pẹlu awọn oyinbo rẹ n fun lowo gidi ninu awọn ọmọ igbimọ ologun, ki wọn too le maa fọwọ si gbobo owo to ba fẹẹ gba, ati iṣẹ yoowu to ba gbe jade si wọn. Nidii eyi, awọn alagbara inu ijọba Ọbasanjọ igba naa, ati awọn oloṣelu kọọkan ninu awọn ẹgbẹ to ku mura gidigidi pe ohun ti yoo le daabo bo awọn ni ki Awolọwọ ma gbajọba lọwọ awọn ṣọja ninu oṣu kẹwaa, ọdun 1979, nitori to ba gbajọba naa, aṣiri buruku yoo tu jade.

Nibẹ ni awọn kan ti ronu pe ki wọn kuku gbe ijọba ọhun fun Azikiwe ti inu ẹgbẹ NPP, wọn ni oun ko ni i yọ ẹni kan lẹnu bo ba gbajọba. Ṣugbọn asiko ti wọn n ronu nipa eyi ni gbẹkẹ bu, ọrọ nla jade lati ọdọ awọn to n ṣeto idibo, wọn ni Nnamadi Azikiwe ko san owo-ori o, ẹni ti ko ba si sanwo-ori ko lẹtọọ lati ṣe olori ijọba Naijiria, eewọ ni. N lọrọ naa ba di ariwo rẹpẹtẹ

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply