Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979

*Idi abajọ ree o (2)

Afi bii ẹni pe awọn eeyan naa ti ni Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ sinu tẹlẹ ni. Abi nigba ti eeyan sọrọ loni-in, to ni ẹgbẹ oun, UPN, yoo ṣe daadaa fawọn oṣiṣẹ ijọba, ti awọn agbaagba NPN si sare forikori laarin ara wọn, ti wọn ti MKO Abiọla ṣaaju pe ko da baba naa lohun kia, ko ma jẹ ohun ti agbalagba oloṣelu naa yoo fi ko awọn lọbẹ jẹ niyẹn. N ni Abiọla naa ba pe awọn oniroyin jọ, o ni ki wọn pade oun ni ibi apejẹ ikowojọ kan ti ẹgbẹ awọn, NPN, fẹẹ ṣe n’Ibadan, ki wọn waa gbọ ọrọ ẹnu oun. Ọjọ Jimọ ni Awolọwọ sọrọ pe ẹgbẹ oun yoo fowo kun owo-oṣu yii, ọjọ Satide si ni apejẹ awọn NPN ipinlẹ Ọyọ yii naa bọ si, nibi ti wọn ti fi Abiọla ṣe olukowojo agba ati alejo pataki wọn. Abiọla ko doju ti wọn, nitori nibi apejẹ naa, ẹgbẹrun lọnaa aadọta Naira (N50,000) lo fun wọn lẹsẹkẹsẹ. Owo nla leleyii lọjọ naa lọhun-un, nitori ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 1979, ni.

Lẹyin ti Abiọla fun wọn lowo tan lo tẹnu bọrọ bii alejo pataki, o fẹẹ ṣalaye ohun ti yoo ṣẹlẹ si ẹgbẹ wọn lọjọ idibo. Gẹgẹ bi ẹni gbogbo ti mọ ninu ọrọ oṣelu, alatako to ba ju ni lọ naa leeyan n sọrọ ẹ ni gbangba, nitori ohun ti yoo fa okiki ba alatako naa niyẹn: wọn aa ni lagbaja sọrọ buruku si Awolọwọ, orukọ Awolọwọ ni yoo si jẹ kawọn eeyan maa wa ẹni to sọrọ buruku si i lọ. O jọ pe ohun ti Abiọla ṣe niyi, nitori kaka ko sọrọ nipa bi ẹgbẹ wọn yoo ṣe wọle tabi eto ti NPN ni fun wọn nilẹ Yoruba, ọrọ ti Awolọwọ ti sọ lati ana lo mu dani, oun naa lo si fi ṣe koko ohun to sọ. O ni Awolọwọ sọ ni gbangba, nibi ipolongo ẹgbẹ oṣelu rẹ pe oun yoo fun awọn oṣiṣẹ ni ọgọrun-un meji bii owo-oṣu, pe ko si ohun meji to fa iru ọrọ yii ju pe Awolọwọ fẹẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba gbogbo ni abẹtẹlẹ ki wọn le dibo fun un lọ.  

Abiọla ni lati sọ iru ọrọ ti Awolọwọ sọ yii, o fi han pe baba naa ko nigbagbọ pe awọn eeyan yoo dibo foun, nitori ẹ lo ṣe di pe o n fi ẹkunwo owo-oṣu bẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe o mọ pe ohun ti ko ṣee ṣe, ti oun ko si ni i ṣe ni. O ni nigba ti wọn ba ti dibo tan, ti awọn oṣiṣẹ ti rọ lu irọ yii, ti wọn sare tẹle wọn lẹyin, ti wọn wọle, wọn yoo pada waa sọ fun wọn pe eto ọrọ aje ko dara, awọn ko le san iru owo bẹẹ fun oṣiṣẹ kankan. Ni tootọ, nigba naa, owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ ko wọ ọgọrun-un Naira tan daadaa, lati waa gbe kinni naa lọ si ọgọrun-un meji Naira wuya bẹẹ, ohun ti yoo la ariwo pupọ lọ ni, ko si si oṣiṣẹ ijọba ti yoo gbọ iru rẹ ti ko ni i fẹẹ dibo fun ẹni to ṣe ileri bẹẹ fun wọn. Ohun to jo awọn NPN lara ree, to si mu ibẹru ba wọn, nitori wọn mọ pe ti awọn oṣiṣẹ ba gbọ iru ẹ, wọn yoo fẹẹ sare tẹle Awolọwọ lẹyin, ki wọn le dibo fun un.

Abiọla ni bi Awolọwọ ba ti le ri owo naa to san an fawọn oṣiṣẹ loootọ, ko si ohun ti kinni naa yoo mu wa ju iyan gidi lọ. O ni iya ati idaamu ni yoo mu wa fawọn eeyan, aibalẹ-ọkan ti yoo si wa ninu owo naa yoo ju ibalẹ-ọkan tawọn eeyan foju si lọ. O ni iru ẹ ti ṣẹlẹ ri nigba ti  ijọba ologun fawọn eeyan ni owo Udoji ni 1974, ti owo lọ tabua lọwọ awọn eeyan, ṣugbọn ti ko si ọja ti wọn yoo fi ra, ti kaluku waa bẹrẹ si i ra irakura jọ, ko si pẹ lẹyin naa ni gbogbo ọja gbowo lori, to lọ soke pata, to jẹ lẹyin ti owo Udoji yii tan lọwọ awọn eeyan, wọn ko lowo lati ra awọn ọja ti wọn n ra lowo pọọku tẹlẹ mọ, owo Udoji ti ba ọja jẹ fun wọn. O ni ohun ti yoo ṣẹlẹ ree bi Awolọwọ ba fi agidi gbe owo kan jade fawọn oṣiṣẹ ijọba. Abiọla ni Awolọwọ ko le sọ loju awọn kan pe oun fẹran awọn mẹkunnu ju awọn to ku lọ. O ni ko le sọ bẹẹ rara.

Alaga ileeṣẹ ITT to ṣe tẹlifoonu yii ni idi ti Awolọwọ ko ṣe le sọ pe oun fẹran awọn mẹkunnu ni pe nigba ti baba naa n ṣejọba, wọn da ileeṣẹ kan silẹ ti wọn pe ni NIPC. Ileeṣẹ ijọba Western Region ni, ileeṣẹ naa ni wọn si fi ni awọn ile nla bii Cocoa House, n’Ibadan, Western House, l’Ekoo, Investment House, l’Ekoo, ati Bristol Hotel, ṣugbọn ohun ti awọn eeyan ko mọ ni pe jibiti to pọ ninu gbogbo ohun ti wọn ṣe ati awọn ohun ti wọn ni yii, ko si iru ẹ ni gbogbo Afrika, ko tun si ibi ti iru ẹ ti ṣẹlẹ laarin awọn alawọ-dudu rara. O ni loootọ, Awolọwọ le jade loni-in pe oun ko mọ nipa ẹ, ṣugbọn awọn eeyan ti wọn n sare tẹle e lẹyin yoo tun ero wọn pa, nigba ti wọn ba mọ awọn jibiti to wa nidii gbogbo ohun ti Awolọwọ n sọ pe oun ṣe fun wọn. O ni bawo ni Awolọwọ yoo ṣe jade ti yoo ni oun ko mọ ohun to ṣẹlẹ nigba naa, nigba to jẹ oun lolori ẹgbẹ Action Group to ṣejọba.

Bi Abiọla ti sọ niyi, nigba to si jẹ aarin awọn eeyan tirẹ ti i ṣe olori ẹgbẹ NPN lo wa, niṣe ni kaluku n rẹrin-in a-rin-digbo-lura-wọn. Ohun ti wọn n sọ naa ni pe alaṣeju ni baba naa, ẹni to kapa ẹ lo jade sita yii, yoo foju ẹ ri mabo. Ṣe ko si ohun ti awọn oloṣelu ko le sọ, ko si si ara ti wọn ko le da bi ọti oṣelu ba n pa wọn. Nigba ti ọrọ naa jade sita pe Abiọla sọ bayii, o sọ bayii, ko jọ pe ọrọ naa fi bẹẹ dun Awolọwọ, boya nitori o mọ pe gbogbo ohun ti ọkunrin naa darukọ pe awọn ṣe nnkan amuyangan ni. Ṣugbọn Awolọwọ mọ ohun to n ṣe Abiọla, o mọ pe ọmọde ni, ṣe Abiọla ko ju ọmọ ogoji ọdun lọ nigba naa, o si ti lọ sile Awolọwọ, nitori ọrẹ Oluwọle ọmọ rẹ ni, bo tilẹ jẹ pe ọrẹ wọn naa ki i ṣe kori-kosun. Awolọwọ mọ pe ko si ohun kan to n ṣe Abiọla ju owo buruku to wa lọwọ rẹ lọ, ko si bi owo bẹẹ yoo ṣe wa lọwọ ọmọde ti ko ni i sọrọ sẹni to ju u lọ.

Ṣugbọn Awolọwọ mọ nnkan mi-in ti awọn to ku ko mọ, o mọ ohun tawọn oloṣelu NPN ko mọ nigba naa rara. O mọ ọna ti Abiọla gba ni owo rẹ, o mọ iru iṣẹ to n ṣe, o mọ ọna tileeṣẹ ITT fi di ileeṣẹ to lowo ju lọ ni Naijiria, ati iṣẹ ti wọn n ṣe gan-an. Nibi yii naa lo si ba wọle, nitori ọjọ keji ti Abiọla sọrọ naa lo ti gba esi ọrọ to sọ. Ṣugbọn Awolọwọ ko bu u o, o kan sọ pe bi UPN ba wọle, awọn yoo wadii iṣẹ tẹlifoonu kan ti ileeṣẹ ITT gba lọwọ ijọba apapọ, iṣẹ ẹlẹgbẹrin miliọnu owo Naira (N800milion), nitori wọn fi iṣẹ naa lu Naijiria ni jibiti ni. O ni bi UPN ba ti wọle, awọn yoo wadii iye ti wọn gba fun iṣẹ naa, ati iru iṣẹ ti wọn ṣe gan-an ti owo fi to bẹẹ, nitori iṣẹ ti ko yẹ ko to ida mẹta iye ti wọn gba lọwọ ijọba Naijiria ni. O ni nigba tawọn ba wadii owo iṣẹ tẹlifoonu ti wọn gba owo rẹ, ti wọn ko ṣe yii, Naijiria yoo mọ ileeṣẹ ole ati awọn ti wọn ja wọn lole ni orilẹ-ede wọn.

O ni aṣiri bi gbogbo ọrọ iṣẹ tẹlifoonu naa ti jẹ wa lọwọ oun, oun yoo si tu u fawọn ti wọn yoo ṣewadii ẹ to ba ya, wọn yoo le mọ ohun ti wọn yoo doju kọ. O ni bi ITT ba gba iṣẹ ni Naijiria, ko si ohun to buru nibẹ, ṣugbọn eyi ti ko dara ni ki wọn maa gba iru iṣẹ kan naa ni ọgọrun-un Naira ni awọn orilẹ-ede mi-in, ṣugbọn ki wọn de Naijiria, ki wọn ni ẹgbẹrun kan lawọn yoo ṣe e, ki wọb si gba owo naa, ki awọn eeyan pin in mọ ara wọn lọwọ, ki iṣẹ ti wọn tun waa ni wọn ṣe yii ma wulo fun awọn eeyan ni Naijiria. O ni ohun  ti ITT n ṣe ree, asiko si ti to ti awọn yoo tudii wọn wo, ki wọn le mọ pe ko si ọbọ kan n’Idere, eyi to wa nibẹ bayii, ife oyinbo lo fi n mẹmu. O ni ki ITT ati awọn ti wọn jọ n lu Naijiria ni jibiti fi ọkan ara wọn balẹ o, ijọba UPN n bọ waa ba gbogbo wọn.

Ọro ti Awolọwọ sọ yii da nnkan ru, paapaa aṣiri to lo wa lọwọ oun. Ọkan awọn eeyan nla ninu NPN ko balẹ mọ; ọkan awọn olori ijọba ologun pupọ ni ko balẹ, nitori wọn mọ pe ti wọn ba fa gburu lọrọ naa, gburu yoo fa igbo, bi Awolọwọ ba wọle, to ba bẹrẹ iwadii ITT loootọ, ohun ti yoo ti idi kinni naa jade ko ni i rọgbọ.

Ṣugbọn aṣiri wo lo wa lọwọ Awolọwọ nigbanaa, ki lo si de ti ọrọ naa ka awọn oloṣelu NPN at iijọba ologun lara gan-an?

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

One thought on “Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979

Leave a Reply