Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979

*Idi abajọ ree o (3)

Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ pe oun yoo wadii ọrọ ileeṣẹ ITT wo, oun yoo tudii iṣẹ olowo-nla ti ileeṣẹ yii gba lọwọ ijọba apapọ wo, bi ijọba Naijiria ba fi le bọ sọwọ ẹgbẹ oṣelu oun ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 1979. Oloye Moshood Kaṣimaawo Abiọla ni alaga ileeṣẹ ITT ni Naijiria, boya ni ileeṣẹ kan si wa nigba naa to tun lowo to wọn, nitori gbogbo ohun to ba jẹ tẹlifoonu ati ẹrọ ibanisọrọ loriṣiiriṣii, paapaa eyi to ba ti jẹ ijọba apapọ lo ni in, tabi to fẹẹ lo o, ileeṣe ITT yii leeyan yoo ba nidii ẹ. Nitori pe ileeṣẹ yii lowo, Abiọla naa lowo; nitori awọn ọga pata nidii iṣẹ ologun ati ijọba nileeṣẹ yii n ṣiṣẹ fun, Abiọla mọ awọn ọga ṣọja, o si mọ awọn ọga ijọba gbogbo. Ko sẹnikan to mọ bi Abiọla ṣe ni owo rẹ ninu awọn araalu, ọpọ wọn ko mọ ohun to n ṣe, afi nigba to bẹrẹ oṣelu, ti oun atawọn ẹgbẹ oṣelu rẹ doju kọ Awolọwọ.

Abiọla ti sọrọ si Awolọwọ nitori pe iyẹn ni oun yoo san ọgọrun-un meji fawọn oṣiṣẹ ti oun ba wọle, Abiọla si ni abẹtẹlẹ lo fẹẹ fi kinni naa ṣe, o lo fẹẹ fun awọn oṣiṣẹ lowo ẹyin ki wọn le dibo fun un ni. Ọrọ yii lo dun Awolọwọ, to waa ran awọn eeyan leti pe Abiọla sọ ninu ọrọ rẹ nibi to ti n kampeeni fun ẹgbẹ oṣelu NPN pe ko si ilu nla kan ni orilẹ-ede aye yii, boya Paris ni, boya London ni, boya New York ni o, tabi Washington, boya Berlin ni o, tabi Swistzerland, ti oun Abiọla ko ni yara si, ti oun ko si ni aṣọ nibẹ lati wọ ti oun ba debẹ. Awọlọwọ ni iru ẹni to ni owo to to bẹẹ lọwọ, o yẹ kawọn eeyan le mọ iṣẹ to n ṣe. O ni iṣẹ ti ITT gba ti owo rẹ jẹ miliọnu lọna ẹgbẹrin (N800m), awọn aṣiri kan wa nidii iṣẹ naa to wa lọwọ oun, bi ijọba UPN ba si wọle, wọn yoo wadii awọn kinni naa daadaa, nitori owo awọn ọmọ Naijiria ni.

Loootọ ni Abiọla jade, to ni Awolọwọ ko mọ ohun to n sọ ni, pe ko si awo kan ninu awo ẹwa nidii iṣẹ ti awọn gba lọdọ ijọba apapọ, nitori iwe awọn pe perepere, sibẹ, ọrọ naa ko wahala ọkan ba a. Bẹẹ ni ki i ṣe oun nikan, oun pẹlu awọn ti wọn jọ jẹ ọga ileeṣẹ ijọba ati awọn ọga ologun ni. Ọrọ naa ba wọn lojiji, nitori o ti wa lara ohun to n ba awọn ọga ṣọja yii lẹru tẹlẹ pe ṣe bi Awolọwọ ba gbajọba, ko ni i ni oun n tudii ẹnikankan wo ninu awọn, tabi pe o fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ laye ijọba ologun. Gbogbo awọn bii Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Shehu Musa Yaradua, Yakubu Danjuma, ati awọn mi-in bẹẹ bẹẹ lọ ni ọrọ naa n kọ lominu tẹlẹ, nigba ti ariwo naa si n le ju, Awolọwọ ni oun ko ni i tudii ijọba ṣọja kan wo ninu wọn. Ṣugbọn ti ileeṣẹ ITT to sọ yii naa, oun ko mọ pe ọrọ naa yoo kan pupọ ninu awọn ologun.

Bẹẹ ni tododo, aṣiri ileeṣẹ ITT wa lọwọ Awolọwọ digbidigbi, ko si si ohun to ṣẹlẹ laarin ileeṣẹ yii ati ijọba apapọ ti Awolọwọ ko mọ, nitori gbogbo bo ṣe n lọ ni wọn n sọ fun un. Ọrọ naa si kan Abiọla gbọngbọn, koda, o kan Ọbasanjọ paapaa daadaa. Bi ọrọ ṣe jẹ ni pe nigba  tileeṣẹ ITT yii kọkọ de si Naijiria, awọn ologun ni wọn n ba ṣiṣẹ wọn, lara awọn ileeṣẹ ti wọn de si Naijiria lasiko ogun abẹle ni. Ileeṣẹ naa ṣiṣẹ fun ijọba ologun, wọn ko si rowo iṣẹ ti wọn ṣe gba, nigba naa ni wọn gba Abiọla gẹgẹ bii agbowoka ati aṣeto inawo ileeṣẹ wọn. O ti de ibi iṣẹ naa tan ki wọn too sọ fun un pe ko sowo gidi kan lapo awọn o, ṣugbọn awọn ijọba ologun Naijiria jẹ awọn lowo rẹpẹtẹ, bo ba le ri owo naa gba, ko maa fi dari ileeṣẹ naa lọ. Muritala Muhammed ni ọga fun ẹka ileeṣẹ ologun to n ṣeto ibanisọrọ, oun naa lo si yẹ ko sanwo fun ileeṣẹ ITT.

Owo yii l’Abiọla lọọ sin ti ọrọ yii dija laarin wọn, ko too waa di pe wọn pari ẹ, ti Abiọla si rowo ileeṣẹ rẹ gba jade. Lati ibi yii ni Abiọla ati Muritala ti di kori-kosun, ọrẹ wọn si jinlẹ gan-an. Lati igba naa lo ti jẹ gbogbo iṣẹ eto ibanisọrọ ti awọn ologun ba fẹẹ ṣe, ileeṣẹ Abiọla ni iṣẹ naa yoo bọ si lọwọ. Bi wọn ti ṣe niyi titi ti ogun fi pari. Nigba ti ogun pari tan, awọn alagbada pọ ninu ijọba Yakubu Gowon igba naa ju ti tẹlẹ lọ, ọpọ iṣẹ paapaa lo yatọ si bi wọn ṣe n ṣe e tẹlẹ, awọn ọga nileeṣẹ ijọba gbogbo lo ku to n paṣẹ. Nigba naa ni orukọ ọkunrin kan jade, baba naa wa laye sibẹ, o kan ti di agbalagba daadaa ni, Theophilous Oluwọle Akindele lo n jẹ. Akindele yii, ọmọ Naijiria akọkọ ti yoo jẹ olori ileeṣẹ to n ṣeto ibanisọrọ, awọn ni wọn n ṣe redio, ti wọn n ṣe tẹlifoonu ati gbogbo ohun to ba jẹ mọ ẹrọ ibanisọrọ laye ọjọ naa. Bẹẹ ni ko si kọmiṣanna kan ti awọn ologun gbe de ti ko jẹ oun ni yoo fi ọna han gbogbo wọn.

Gẹgẹ bii ẹni to mo ohun to n ṣe, ko si ọga kan to wa nileeṣẹ eto ibanisọrọ ti Abiọla ko mọ, bo si tilẹ jẹ pe Akindele yii ju u lọ ni ọjọ ori, o wa gbogbo ọna lati fi di ọga rẹ, lẹyin ti ipo olori ileeṣẹ eleto ibanisọrọ naa ti bọ si i lọwọ. Abiọla a maa lọ sile Akindele, koda, a maa ba awọn ọmọ rẹ sere debii pe ko si ohun ti ọkunrin yii n ṣe ti Abiọla ko ni i fẹẹ kun un lọwọ. Iṣoro to wa nibẹ ni pe Abiọla ko ri iṣẹ gba fun ITT mọ bi wọn ti ṣe n gba iṣẹ naa tẹlẹ, nitori awọn sifilian, awọn alagbada, lo wa nileeṣẹ naa bayii. Joseph Tarka ni kọmiṣanna, Akindele si ni ọga agba pata fun ileeṣẹ naa. Bẹẹ ni ki i ṣe pe Akindele ko fẹẹ fun Abiọla niṣẹ, ṣugbọn iṣoro to wa nibẹ ni pe o loun ko le fun awọn ITT niṣẹ nitori owo ti wọn maa n fẹẹ gba fun iṣẹ ti wọn ba ṣe ati awọn ohun eelo ti wọn ba ko wa maa n pọ ju iye ti awọn to ku maa n gba lọ.

Ki i waa ṣe pe owo wọn n pọ nikan kọ, awọn irinṣẹ ati eelo ti wọn maa n fẹẹ ti mọ ijọba lọrun, awọn eyi to ti pẹ nigba tabi ti ọjọ ti lọ lori rẹ ni. Eleyii ni Akindele ko fi fẹran ileeṣẹ ITT, a si maa sọ fun Abiọla idi ti awọn ko se le gbe iṣẹ fun ileeṣẹ rẹ ati awọn oyinbo ẹ. Nigba ti Abiọla fa Akindele titi to da bii pe ko ri i fa, o bẹ ọrẹ rẹ kan ko jẹ ki awọn jọ dowo pọ, ki oun naa si maa gba ohun to ba kan an ninu iṣẹ to ba ṣe fun ileeṣẹ awọn. Ọrẹ Abiọla to bẹ lọwẹ yii, Godwin Daboh lo n jẹ, ọmọ adugbo kan naa ni oun ati awọn Gowon to n ṣejọba, ọrẹ timọtimọ si loun ati Joseph Tarka to jẹ kọmiṣanna eto ibanisọrọ fun ijọba apapọ. Ni bi nnkan ba ṣe yẹ ko ri, Tarka lọga fun Akindele, ṣugbọn kọmiṣanna ko le deede paṣẹ fun ọga agba, ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe, wọn yoo jọ fikunlukun lori ẹ ni.

Idi ni pe ọga agba yii lo ni imọ kikun nipa iṣẹ ti wọn n ṣe nileeṣẹ naa, kọmiṣanna kan wa bii oloṣelu lati dari lasan ni, ọpọ wọn ko ni imọ nipa ileeṣẹ ti wọn fẹẹ dari, awọn ọga agba yii ni yoo maa tọ wọn sọna ninu ohun gbogbo. Ati pe ko si ninu agbara kọmiṣanna kan lati yọ ọga agba, Permanent Secretary, danu lẹnu iṣẹ ijọba apapọ, olori orilẹ-ede funra rẹ nikan lo le yọ akọwe-agba yoowu lẹnu iṣẹ wọn. Ṣugbọn nibi ti awọn kọmiṣanna ti wọn n pe ni minisita yii ati ọga agba ti wọn n pe ni akọwe agba bayii ba ti gbọ ara wọn ye, ki i si wahala kankan. Loootọ, gbogbo ọna ni Tarka n wa lati fi kowo jẹ ni tirẹ, nigba to jẹ oloṣelu ni, o si mọ pe ọjọ diẹ loun ni, nitori ko mọ ọjọ  ti wọn le yọ oun. Ṣugbọn Akindele ko jẹ. Ki i ṣe pe o n ba a ja lori eyi, yoo kan ṣalaye fun un idi ti awọn kinni naa ko fi ṣee ṣe, nitori ohun ti yoo di wahala bo ba dọla ni. Bi Tarka ba ti gbọ alaye bẹẹ, yoo sa sẹyin, yoo ni oun ko fẹẹ daran ijọba.

Ṣugbọn nijọ kan, Godwin Daboh ati ọrẹ rẹ, Abiọla, fẹẹ fi ori Akindele ati Tarka gba ara wọn. Nitori iṣẹ ITT yii naa ni o.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply