Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (4)

*Idi abajọ ree o

Ohun to ṣẹlẹ ni pe lẹyin ti Moshood Kaṣimawo Abiọla ti gbiyanju titi lati ri iṣẹ tẹlifoonu gba fun ileeṣẹ rẹ, ITT, to ti rin mọ Theophilous Akindele to jẹ ọga agba pata ni ileeṣẹ onitẹlifoonu ilẹ wa ti iyẹn ko fun un, o sun mọ ***Joseph Tarka ti i ṣe kọmiṣanna, iyẹn minisita fun eto ibanisọrọ, ṣe oun ni ọga fun Akindele. Ṣugbọn iṣoro wa fun Abiọla nibi yii, nitori Tarka ko le ṣe ohun kan ko ma sọ fun Akindele, nigba to jẹ oun lọga ẹka to n ri si ọrọ tẹlifoonu. Bi Abiọla ba ti gbe ọrọ ITT dewaju Tarka, ti Tarka ba fi ọrọ lọ Akindele, nigba ti Abiọla yoo ba pada de, esi ti yoo gbọ ni pe ẹja lọrọ ọhun, ki i ṣe akan, pe iṣẹ naa ko bọ si i. Ohun meji naa ni Akindele maa n tẹnu mọ, akọkọ ni pe irinṣẹ ti ITT fẹẹ ta fun awọn ti gbe owo lori ju bi awọn to ku ti n ta a lọ, ekeji si ni pe awọn irinṣẹ naa ti pẹ nigba, ko si le wulo fun Naijiria.

Irinṣẹ to ba ti pẹ lori igba tabi ti ọjọ ti lọ lori rẹ, ITT yoo fi dandan le e pe Naijiria le maneeji rẹ, ṣugbọn Akindele yoo ta ku pe ko si idi ti Naijiria fi gbọdọ maneeji ohun ti ko dara, nigba tawọn onileeṣẹ to n ta irinṣe mi-in wa nitosi, to si jẹ owo awọn irinṣẹ tuntun tiwọn ko to iye ti Abiọla ati ITT rẹ n gbe wa. Ko si igbakigba ti Abiọla gbọ iru esi bayii lẹnu Tarka ti yoo dunnu, paapaa nigba to ti ba Akindele sọrọ titi to jẹ ohun kan naa lo n tẹnu mọ bii aditi, bẹẹ ITT ko ti i ṣe awọn irinṣe mi-in, eyi ti wọn  si ti ṣe kalẹ yii, tita naa ni. Nibi yii ni Abiọla ti ronu Godwin Daboh. Ọrẹ ni Abiọla ati Daboh, bẹẹ Daboh yii, ọmọ ilu kan naa loun ati Tarka, koda, ibatan kan naa ni wọn jọ n ṣe. Nidii eyi, Abiọla ti mọ pe ti oun ba ti ba Daboh sọrọ, yoo ba ẹgbọn rẹ sọrọ, bi awọn ba si fẹ kinni kan ni ileeṣẹ onitẹlifoonu ilẹ wa, awọn yoo ri iṣẹ naa gba kia.

Ṣugbọn Daboh naa ki i ṣe ọrẹ Akindele, oun pẹlu ẹ ti ja. Ohun to si fa ija wọn ni pe nigba ti Tarka ṣẹṣẹ di kọmiṣanna fun ijọba Gowon, ti wọn si gbe e wa si ileeṣẹ to n ṣeto ibanisọrọ yii, Daboh fẹẹ lo anfaani ipo ti ibatan rẹ yii wa lati gba iṣẹ nileeṣẹ ti wọn ṣẹṣẹ gbe e si. Ileeṣẹ naa fẹẹ ṣe irimọlẹ awọn waya kan, Daboh gbọ nipa ẹ, o ni kọntirakitọ gidi loun, iṣẹ ti oun le ṣe ni,  n lo ba sọ fun ẹgbọn rẹ, iyẹn Tarka. Ni Tarka ba sọ fun un pe o ni awọn eto ati ilana ti wọn fi maa n gba iru ohun to n wi yii, awọn kan ni wọn si n ṣe e, labẹ alaṣẹ wọn, ọga agba ẹka iṣẹ tẹlifoonu ti wọn n pe ni Akindele. Daboh ni ko si ọga agba kan nibi kan, ohun ti oun kọmiṣanna ba ti wi ni gbogbo ọga agba gbọdọ ṣe. O ni oun n lọọ ri ẹni ti wọn n pe ni Akindele naa funra oun. Ohun to gbe Daboh de ọọfiisi Akindele lọjọ naa ree o. Ṣugbọn pẹlu igberaga lo ba wọle.

Siga nla ti awọn ọlọla igba naa maa n mu, to maa n tobi gbangba bayii, ni Daboh mu wọ inu ọọfiisi Akindele, bẹẹ ni ko duro lọdọ sẹkitiri ki iyẹn tilẹ lọọ sọ fun ọga rẹ pe alejo kan fẹẹ ri i, o kan n ja lọ soose ni. Nigba to tun wọ inu ọọfiisi naa, ko yọ siga lẹnu, o kan sọ fun Akindele pe aburo kọmiṣanna loun ni. O ni oun waa ri i fun ọrọ iṣẹ pataki ti wọn fẹẹ ṣe ni, ẹgbọn oun to jẹ kọmiṣanna yii lo si ni ki oun waa ri i ko gbe iṣẹ naa foun. Akindele ti inu n bi nitori ọna ti Daboh fi ja wọle ko wo oju rẹ to fi ṣalaye fun un pe ọrọ a-n-gba-iṣẹ-ṣe lọdọ awọn ki i ṣe ọrọ ti awọn n fi ti ẹbi ṣe, ẹni to ba kun oju oṣuwọn lawọn n gbe iṣẹ fun. Akindele ni ko kọwe ẹ ki wọn ko o mọ inu tawọn to ku, ko sọ iye ti yoo ṣe iṣẹ ọhun fawọn ati iriri to ti ni nidii iru iṣẹ bẹẹ, pe to ba ti kọ gbogbo eleyii sinu iwe, bo ba jẹ tirẹ lo dara ju, awọn yoo gbe iṣẹ naa fun un.

Ọrọ naa bi Daboh ninu, iru palapala wo ree, nigba to jẹ kọmiṣanna lo ni ko gbeṣe foun, ki waa ni itumọ alaye gbọọrọ to n ṣe yii. O si sọ bẹẹ fun Akindele, o ni ṣe o ro pe oun ti dagba ju ẹni ti kọmiṣanna le paṣẹ fun lọ ni, tabi o fẹẹ sọ pe oun ko mọ pe kọmiṣanna yii lọga oun ni. “Ọga ẹ ni! Ọga ẹ ni!” Ohun to n fi ariwo sọ fun Akindele ni ori aga rẹ to jokoo si niyẹn. Ni inu ba bi Akindele, loun naa ba pariwo mọ ọn, pe ti ko ba jade loju ẹsẹ, oun yoo ni ki awọn mẹsenja waa gbe e jade pẹlu tipa-tikuuku. N ni Dabojh ba binu jade, o gba ọdọ minisita ẹgbọn rẹ yii lọ. O sọ fun tọhun pe abuku kan oun lọdọ ẹni to ran oun si. Ni Tarka ba ki foonu mọlẹ, o foonu Akindele pe aburo oun sọ pe o le oun jade lai gbọ tẹnu oun ni. Akindele da a lohun pe aburo rẹ ko huwa bii ọmọluabi ni o jare, o ro pe ọrọ famili ni wọn fi n gbe iṣẹ fun alagbaṣe lọdọ awọn ni. Nibẹ lọrọ naa pari si, ti Daboh ko  riṣẹ to fẹẹ gba lọdọ wọn gba.

Ọrọ yii ti wa nilẹ ki Moshood Abiọla too fẹjọ Akindele sun ọrẹ rẹ, Daboh. Ninu ọrọ ti wọn n sọ, Abiọla sọ fun Daboh pe akukuu-joye ni ẹgbọn rẹ ti wọn fi ṣe minisita yii, akukuu-joye san ju ka joye ki ẹnu ẹni ma ka ilu lọ. Abiọla sọ fun Daboh pe gbogbo aye lo ti mọ bayii pe ẹgbọn rẹ ti wọn fi ṣe minisita ko laṣẹ kankan lori ibi ti wọn ti fi i ṣe minisita, Akindele ni alaṣẹ ibẹ, wọn kan fi oun di gẹrẹwu lasan ni. O ni gbogbo iṣẹ loun fẹẹ gba ti oun ko ri ẹyọ kan bayii gba, bo tilẹ jẹ pe o wu Tarka lati gbe iṣẹ foun. N ni  Daboh ba gbe ọrọ yii lọọ ba Tarka, o ni ko gbọ ohun tawọn eeyan n sọ nipa rẹ nigboro, pe ṣe ko mọ pe nnkan itiju gbaa ni. Ọrọ naa dun Tarka gan-an debii pe o ranṣẹ si Akindele, o ni ki oun naa waa gbọ ohun tawọn eeyan n sọ soun Tarka. Nigba ti Akindele gbọ ọrọ naa, to si gbọ ẹni to sọ ọ, o ni ki Tarka pe Abiọla ati Daboh sipade, ki awọn jọ koju ara awọn.

Tarka pe Abiọla loootọ, oun naa si wa sipade, nitori ko kuku mọ ohun ti ipade naa da le lori. Nigba ti wọn de ipade yii, Akindele beere loju gbogbo awọn ti wọn jọ wa nipade pe ki lo de to lọọ sọ nita pe oun ki i ṣe ọrẹ oun, nigba to jẹ gbogbo igba lo maa n wa nile oun. O ni ki Abiọla ja oun bi ki i baa ṣe ootọ lo n wa sile oun lojoojumọ lati igba ti ọṣẹ ti awọn wa ninu rẹ yii ti bẹrẹ, to n fi dandan le e pe oun loun yoo maa fi mọto gbe awọn ọmọ oun lọ sileewe ni gbogbo ọsẹ yii. Nigba ti Abiọla sọ loju Tarka ati Daboh pe gbogbo ohun ti Akindele sọ, ootọ ni, Akindele binu dide, o si sọ fun Tarka pe ko ma maa pe oun si iru ipade bẹẹ, ipade to ba ti jẹ nitori ọrọ ahesọ ati irọ tawọn eeyan n pa kiri ni. Nibẹ lọrọ ti di wo-mi-n-wo-ọ, ti ipade naa ko si fori ti sibi kan. Ṣugbọn kinni kan waa ṣẹlẹ laipẹ sigba naa rara.

Akindele wa niluu oyinbo ni, ni kutukutu owurọ ni tẹlifoonu yara to wa ninu otẹẹli deede dun. Bo ṣe gbe e lo gbohun Abiọla, ‘Ẹgbọn, ẹ kaaarọ! Ẹgbọn, ṣe ẹyin naa ri i bi aye ṣe ri. Lati igba ti ẹ ti di ọga ileeṣẹ tẹlifoonu wa, ẹ o jẹ ki wọn gbe iṣẹ kankan fun mi ri. Ki lẹ waa fẹẹ ṣe bayii o, nitori wọn ti fi ọrẹ mi pataki rọpo Tarka o, wọn ti sọ ọrẹ mi di kọmiṣanna fun eto ibanisọrọ, ọrẹ mi lọga yin bayii o!” Akindele ko ti i gbọ tẹlẹ, ko mọ pe Yakubu Gowon yoo yọ Tarka bẹẹ nigba to jẹ ọmọ adugbo kan naa ni wọn. N lo ba beere lọwọ Abiọla pe “Ọrẹ ẹ wo ni wọn waa fi ṣe minisita bayii o!” Ni Abiọla ba rẹrin-in lori foonu lọhun-un, ‘Iyẹn ni pe ẹ o ti i gbọ! Ọrẹ mi Birigedia Muritala Muhammed ni o!” Muritala Muhammed kẹ! Idi Akindele domi nibi to wa!

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply