Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (7)

*Idi abajọ ree o

Bo ba ṣe pe ko si nnkan kan nibẹ tẹlẹ, ti wọn ba gbe ọga tuntun wa sibi iṣẹ eeyan, inu oluwarẹ yoo maa dun, yoo si maa reti nnkan ayọ ti yoo jade nibẹ ni. Ṣugbọn lati gbe Birigedia Muritala Muhammed wa si ileeṣẹ eleto ibanisọrọ gẹgẹ bii Kọmiṣanna (minisita) ibẹ ki i ṣe ohun ti yoo tẹ Theophilus Akindele lọrun, nitori awọn mejeeji ti jọ pade lẹẹmeji, ija ni wọn fi tuka, ohun kan naa to si n fa ija wọn ni ọrọ ileeṣẹ ITT, ileeṣẹ to n ta awọn ohun eelo ibanisọrọ lagbaaye, ti wọn si ni ẹka wọn ni Naijiria, nibi ti Moshood Abiọla ti jẹ olori wọn. Ṣugbọn gbogbo agbara, ọwọ ijọba lo wa, ijọba lo ni ileeṣẹ eto ibanisọrọ, ẹni yoowu ti wọn ba fẹ ni wọn si le fi ṣe minisita ibẹ, ti ko si ohun ti oṣiṣẹ kan yoo ṣe. Oṣiṣẹ ijọba lasan ni Akindele, ko si le di ijọba ologun lọwọ ki wọn ma fi Muritala ṣe kọmiṣanna nileeṣẹ wọn.

Oun naa mọ pe ọrọ ọhun yoo le diẹ, nitori o mọ pe Muritala ki i ṣe ẹni kan ti i fẹ ki ẹnikẹni beere aṣẹ ti oun ba pa, tabi ko ma tẹle aṣẹ naa, boya aṣẹ ọhun daa tabi ko daa. Akindele si ree, bi wọn yoo pa a bayii, yoo taku pe afi ti oun ba wi ti ẹnu oun ni. Igba wo ni ija ko waa ni i de. Ko si ohun to le ja oṣiṣẹ ijọba kan laya ju ki wọn waa fi ọta tabi alatako rẹ ṣe ọga fun un lẹnu iṣẹ naa lọ. Ohun to ṣẹlẹ si Akindele gan-an niyẹn. Ki oju ma ribi, ẹsẹ ni oogun rẹ, ko ma di pe ọrọ yoo di wahala soun lọrun, o yaa sare ko ẹru rẹ niluu oyinbo to wa, o n gba ile lọ lẹlẹẹlẹ. Ṣugbọn nnkan mi-in ti ko ro n duro de e. Bo ṣe de inu ẹronpileeni ti yoo gbe e wale bayii, pẹki-n-rẹki loun ati ọrẹ rẹ kan jọ ṣe, iyẹn Jide Ọṣuntokun. Njẹ ki wọn kira bi wọn ti maa n ṣe ki wọn si dapaara, oju ti yoo ta kan-an bayii lẹgbẹẹ Ọṣuntokun, Muritala lo wa nibẹ, to jokoo tepọn.

Eyi ni pe Muritala ati Ọṣuntokun ni wọn jọ jokoo lori aga ẹlẹni-meji to wa ninu eronpileeni, bo tilẹ jẹ pe Muritala ko wọ aṣọ ologun. Lẹgbẹẹ wọn ọtun, lori aga ẹlẹni-meji mi-in, nibẹ ni aaye ti Akindele wa, eyi ni pe wọn jọ fẹgbẹ kan ẹgbẹ ninu ẹronpileeni naa ni. Ni gbara ti Akindele ri Muritala lo ki i daadaa, o yọ mọ ọn, o si ki i ku oriire ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an si. Ṣugbọn Muritala kan fi imu da a lohun ni, o si dorikodo sibẹ, o n ka iwe rẹ to n ka lọ. Akindele tubọ waa ri i wayi pe bi oun ti n ro ọrọ naa lọkan gan-an lo ri, Muritala yoo ba oun mu nnkan nilẹ nigba to ba debi iṣẹ. Bẹẹ naa lo si ri nigba ti Muritala wọ iṣẹ gẹgẹ bii minisita fun ileeṣẹ eto ibanisọrọ lọjọ Aje, Mọnde, to tẹle e. Muritala ko jẹ ki ẹnikẹni mọ pe oun ti wọle, o kan de laaarọ naa ni, o si gba ọfiisi rẹ lọ. Nibẹ lo ti ranṣẹ si akọwe agba ileeṣẹ naa.

Nigba naa, bi wọn ba ti mu minisita, akọwe agba ni yoo kan, ṣugbọn awọn ileeṣẹ mi-in wa ti wọn yoo ni akọwe agba meji tabi mẹta, ti ipo wọn yoo jọ jẹ bakan naa, ṣugbọn ti orukọ wọn yoo yatọ sira. Ipo ti Akindele wa, bii ti akọwe agba naa ni, ṣugbọn adari agba (Director General) ni wọn n pe oun. Oun loun jẹ akọṣẹmọṣẹ to mọ nipa oṣiṣẹ gbogbo ni ileeṣẹ ibanisọrọ, akọwe agba lo mọ nipa eto iwe ati ti awọn oṣiṣẹ ijọba to n ṣiṣẹ nibẹ. Bi minisita kan yoo ba ṣe ohunkohun, awọn ọga mejeeji yii ni yoo mọ si i. To ba tiẹ jẹ lori eto ibanisọrọ ati irinsẹ ni, akọwe-agba le ma mọ, ṣugbọn adari agba ti i ṣe Akindele gbọdọ mọ ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe nitori iṣẹ tirẹ niyẹn. Awọn darẹkitọ loriṣiiriṣii lo wa labẹ Akindele, ṣugbọn oun lọga fun gbogbo wọn, ko si si ohun ti ẹnikẹni yoo ṣe, tabi gbọdọ ṣe lẹyin rẹ.

Ṣugbọn ni gbara ti Muritala n bọ, ko pe Akindele rara sipade, ko tilẹ sọ fun un pe oun ti de. Kaka bẹẹ, o pe akọwe agba, o si sọ fun akọwe agba ki o pe awọn darẹkitọ mẹrẹẹrin ti wọn wa ni abẹ Akindele, ki wọn waa ba oun ṣepade. Bẹẹ ni gbogbo ọjọ Mọnde yii, Akindele a maa ṣe ipade pẹlu awọn darẹkitọ rẹ mẹrẹẹrin, nitori ọjọ naa ni wọn yoo pin gbogbo iṣẹ ti wọn fẹẹ ṣe fun ọsẹ naa, ti wọn yoo si ṣe ayẹwo awọn eyi ti wọn ti ṣe lọsẹ to kọja. Akindele jokoo, o n reti awọn darẹkitọ rẹ ki wọn waa ba oun ṣepade, oun ko mọ pe Muritala ti pe wọn sọdọ, o n ṣepade pẹlu wọn. Nigba to pẹ ni akọwe agba yọju si ọọfiisi Akindele, lo ba ni minisita ti wa lori ijokoo ẹ, o fẹẹ ri i. Ni Akindele ba gba ọọfiisi Muritala lọ, ẹnu si ya a nigba to ba gbogbo awọn darẹkitọ to ti n reti ni ọọfiisi rẹ lọdọ ọkunrin ṣọja naa, ti wọn jọ n dọwẹẹkẹ.

Inu bi i pupọ, nitori ohun to ṣẹlẹ naa ko ba ofin iṣẹ ọba mu: Minisita ko lẹtọọ lati pe awọn ọmọọṣẹ ọga agba lẹyin rẹ, koda, ko lẹtọọ lati ba wọn ṣepade kankan lai jẹ pe ọga agba yii mọ si i. Akindele ko si mọ si ipade naa, ẹyin ẹ ni Muritala ti pe awọn darẹkitọ to jẹ abẹ oun Akindele ni wọn wa. Ohun to fa ibinu rẹ gan-an ree, nitori o ni oun ko ri iru rẹ ri lati ọjọ ti oun ti wa lẹnu iṣẹ ijọba. Ṣugbọn o gbe ibinu naa mi, o si bẹrẹ si i sọrọ lati ki Muritala kaabọ si ileeṣẹ wọn. “Ẹ kaarọ, Ọlọla julọ. Inu mi dun pupọ lati ki yin kaabọ si ileeṣẹ eleto ibanisọrọ, P and T (Posts and Telecommunications) nibi ti mo ti jẹ olori wọn. Mo ri i pe ẹyin funra yin ti fi ọrọ jomitoro ọrọ pẹlu awọn oṣiṣẹ abẹ mi, ati ….” Nibi yi lọkunrin naa sọrọ de ti Muritala fi da a mọ ọn lẹnu, pẹlu ifiniwọlẹ si ni. O ni:

“Ma wulẹ ro ẹjo wẹwẹ kan fun wa mọ. Mo ti ṣepade pẹlu awọn olori ẹka gbogbo nileeṣẹ yii, ohun ti mo si le sọ ni pe mo lero pe gbogbo yin pata lẹ ti gbọ bayii pe wọn ti yan mi ni minisita fun ileeṣẹ yii. Mo fẹẹ sọ ọ ni asọye pe niwọn igba ti mo ba ṣi wa lori aga yii o, mi o ni i fẹ ki ẹnikẹni di mi lọwọ, tabi ko yi awọn aṣẹ ti mo ba pa pada. Aṣẹ yoowu ti mo pa, ti mo ba ti fi ranṣẹ si ẹni ti ọrọ kan, tabi si gbogbo yin lapapọ, loju ẹsẹ lẹ gbọdọ ṣe ohun ti mo ba ni kẹ ẹ ṣe naa. Mo ti gbọ ti wọn ti n sọ ọ kaakiri pe ẹni kan wa nileeṣẹ yii to n ri ara ẹ bii alagba pata nibi, to jẹ oun lo maa n paṣẹ, to si maa n ro pe gbogbo aṣẹ oun ofin ni, ẹnikan ko gbọdọ yẹ ẹ wo, ki tọhun mọ bayii pe oun ko si ni ipo lati paṣẹ mọ, aṣẹ ti emi ba pa nikan ni oun naa gbọdọ tẹle pẹlu awọn to ku ẹ. Ohun ti mo ṣi fẹẹ sọ bayii niyẹn, ẹ maa lọ!”

Akindele ki i ṣe ẹni ti eeyan yoo sọ bẹẹ fun ti ko ni i sọrọ, ti yoo kan maa lọ loootọ. Bo ṣe tun fẹẹ sọrọ ni Muritala ni oun ko fẹ ọrọ kankan mọ, ṣugbọn Akindele fi ohun gooro sọrọ, ko si dakẹ mọ. “Bi a ṣe gba yin lalejo loni-in yii, ati bi ẹ ṣe sọ awọn ohun ti ẹ fẹ fun wa, ko ni i boju mu ki awa naa ma fesi, iwa ifiniwọlẹ ni yoo jẹ. Mo fẹẹ sọ fun yin pe gbogbo ọna lawa naa yoo fi ṣe iṣẹ yoowu ti ẹ ba ti gbe fun wa, emi ti mo si jẹ ọga agba n ṣeleri bayii pe niwọn igba ti ẹ ba ti kọ ofin tabi aṣẹ kan sinu iwe pe ka ṣe bẹẹ, loju ẹsẹ ni n oo ni ki wọn ṣe e. Nipa ti pe gbogbo ohun ti ẹ ba fẹ la gbọdọ tẹle, bẹẹ naa ni yoo ri, ṣugbọn iru itẹle bẹẹ ko ni i jẹ bii ti omugọ, tabi ti ẹrú. Ojuṣe temi nibi ni lati gba yin nimọran lori ohun yoowu ti ẹ ba fẹẹ ṣe, ṣugbọn iyẹn ko sọ emi tabi ẹnikẹni ninu awọn darẹkitọ wọnyi di ẹru, alajọṣiṣẹpọ yin la jẹ!”

Inu ti n bi Muritala ni gbogbo akoko yii, ṣugbọn inu ti bi Akindele naa, Muritala si mọ pe oun ko le da a duro mọ. Akindele naa o si duro, o n ba ọrọ rẹ lọ ni: “Eyi ti mo tun fẹẹ sọ ni pe ko dara pe ki ẹ pe awọn darẹkitọ mi lati wa ba yin ṣepade lẹyin mi, ofin iṣẹ ijọba ko gba bẹẹ rara, ipade yoowu ti ẹ ba fẹẹ ni pẹlu awọn darekitọ mi, afi ki n ti gbọ, ki n si pe wọn funra mi lati jọ wa nibẹ, ki i ṣe ki i ẹ pe wọn sipade kan lẹyin mi …” Inu bi Muritala pata wayi, o si lọgun sọrọ: “Oju gbogbo wa ni iyẹn maa ṣe! Bo ba ṣe wu mi ni mo le pe wọn, ẹni yoowu to ba wu mi ni mo le pe, koda ko jẹ mẹsenja!” Bo ti sọ bẹẹ lo ni ki wọn maa lọ. Bẹẹ ni ipade akọkọ ti Muritala ati Akindele tun ni gẹge bii ọga agba ati oludamọran rẹ tun pari si ija. Gbogbo eleyii naa ko si jẹ nitori ohun meji, nitori ITT, ileeṣẹ awọn Abiọla ni.

2 thoughts on “Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (7)

Leave a Reply