Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (8)

*Idi abajọ ree o

Ko ju oṣu meji ti Ọgagun Muritala Muhammed gba iṣẹ gẹgẹ bii minisita fun eto ibanisọrọ ti ija nla de laarin oun ati ọga agba pata fun ka to n ṣeto ibanisọrọ nileeṣ naa, Theophilus Akindele, ija naa ki i ṣe kekere rara. Akọkọ ohun to ṣẹlẹ ni pe lati igba ti Muritala ti de, iṣoro pata ni fun un lati ba Akindele ṣiṣẹ, ki i fẹẹ gbe iṣẹ kankan fun ọkunrin naa ṣe, bo tilẹ jẹ pe oun ni ọga to yẹ ko sun mọ ọn ju lọ. Kaka bẹẹ, akọwe agba ileeṣẹ naa lo maa n ran si i, yoo si ti sọ fun tọhun pe oun ko fẹ Akindele lọdọ oun, ki wọn jọ yanju ọrọ yoowu laarin ara wọn. Akindele naa ki i fi akoko ṣofo, bi wọn ba ti gbe iṣẹ kan fun un to jẹ eyi to ba ofin ati ilana mu, kia ni yoo ti ṣiṣẹ lori rẹ, tiṣẹ naa yoo si di ṣiṣe. Ṣugbọn to ba jẹ iṣẹ to lodi sofin ati ilana ileeṣẹ naa ni, yoo sọ pe ko ṣee ṣe, yoo si kọ iwe gbọọrọ lati fi ṣalaye idi ti ko fi ṣee ṣe.

Dajudaju, eleyii ko tẹ Muritala lọrun, nitori olori ologun loun. Bẹẹ awọn ṣọja ki i gbọ ko ṣee ṣe, gbogbo ohun ti wọn ba dawọ le, ko di ṣiṣe loju ẹsẹ ni ni tiwọn. Ṣugbọn Akindele naa ko ni i gba, ohun ti ko ba ti ba ofin ati ilana mu, ko ṣee ṣe lọdọ toun naa ni. Bayii lo jẹ ọrẹ ologbo ati ekute ni wọn jọ n ba ara wọn ṣe; saaba de saaba, bi aja ti n saaba ẹkun, bẹẹ ni ẹkun n saaba aja. Ṣugbọn lọjọ kan, kinni naa burẹkẹ, ija de lojiji, ko si sẹni to le ri nnkan kan ṣe si i, afigba tija naa ja gbangba. Lọjọ kan ni Muritala fi faili dẹnku kan ranṣẹ si Akindele, to si kọ iwe pelebe le e lori. Ohun to kọ sinu iwe naa ni pe, “Darẹkitọ, mo fẹ ki o yẹ iwe yii ati awọn dokumẹnti ti mo ko pẹlu ẹ wo, ki o le lo wọn lati fi kọwe lori kọntiraati ti a fẹẹ gbe fun awọn ileeṣẹ yii, ki igbimọ apaṣẹ ologun le ba wa fọwọ si i nibi ipade wọn lọjọ Wẹsidee to n bọ yii!”

Muritala Muhammed funra ẹ lo fọwọ si iwe naa ki Akindele le mọ pe ki i ṣe lati ibomi-in niwe ti wa, lati ọdọ oun olori-oko ni. Akindele yẹ iwe bii meji mẹta wo ninu ẹru iwe ti wọn ko jọ yii, ṣugbọn ko wo o jinna to ti mọ pe ohun ti yoo mu wahala wa ni. Idi ni pe ohun to wa ninu iwe yii ni awọn irinṣẹ kan ti wọn fẹẹ ra lọwọ ileeṣẹ kan yii naa ni, ileeṣẹ ITT ti i ṣe ileeṣẹ awọn MKO Abiọla. Wọn ti ṣeto irinṣẹ naa, wọn si ti kọ owo rẹ jade, owo naa si jẹ owo to pọ, bẹẹ ni wọn si ti sọ iru irinṣẹ ti ITT yoo ta fun awọn ileeṣẹ eleto ibanisọrọ yii, ohun ti Muritala si fẹ ki Akindele ṣe ni ko kọ idi ti awọn fi nilo iru irinṣẹ bẹẹ, ati idi ti awọn fi gbọdọ ra irinṣẹ naa lọwọ ileeṣẹ ITT. Bi Akindele ba fẹẹ kọ iwe yii, yoo ṣalaye ohun ti wọn yoo fi irinṣẹ naa ṣe, yoo si ṣalaye bi owo irinṣẹ naa ṣe rọju to lọdọ ileeṣẹ awọn Abiọla. Aaye iwadii kan ko si si, nitori Muritala ti kọ ọ sinu iwe ẹ pe loju ẹsẹ ni ki Akindele ṣe iṣẹ ti oun gbe fun un.

Theophilus Akindele

Ṣugbọn ki i ṣe iyẹn nikan ni iṣoro to wa niwaju Akindele nidii iṣẹ ti minisita to jẹ ọga rẹ yii gbe fun un. Gbogbo ofin, eto ati ilana ti wọn fi n ra iru irinṣẹ bayii ni Muritala ko tẹle rara, koda ko tilẹ ṣe bii ẹni pe oun ri wọn. Akọkọ ni pe ki wọn too le ra iru irinṣẹ bayii, ẹka to ba nilo irinṣẹ naa ni yoo kọwe si awọn ẹka abaniraja ni ileeṣẹ wọn yii, ẹẹkan naa ni yoo ṣi ṣalaye ohun ti awọn fẹẹ lo irinṣẹ naa fun, ati idi ti awọn fi fẹ ẹ. Ẹka ti wọn kọwe si yii ni yoo ba wọn ṣewadii lori irinṣẹ ti awọn tọhun fẹẹ ra, lẹyin ti wọn ba si ti mọ pe loootọ ni wọn nilo ẹ, wọn yoo kọwe sita fun awọn ileeṣẹ to maa n ta irinṣẹ fun wọn, kaluku ileeṣẹ wọnyi yoo si sọ iye ti ọja naa yoo jẹ, lẹyin eyi ni wọn yoo ṣi iwe ti wọn kọ yii wo lati mọ ti ẹni ti owo rẹ rọju ju lọ. Igba ti wọn ba ṣe gbogbo eyi, ti wọn si ti mọ iye ẹ ni wọn yoo too gbe e lọ si ọdọ igbimọ ti Muritala wi yii, ti yoo si fọwọ si i fun wọn.

Gbogbo eleyii ni ọga tuntun yii ko tẹle, koda, Muritala ko sọ fẹnikan pe oun fẹẹ ra irinṣẹ kankan, ko si faaye gba awọn ileeṣẹ mi-in lati dije, bẹẹ ni ko sẹni to mọ awọn ti wọn fẹẹ lo irinṣẹ ti wọn fẹẹ ra yii. Bẹẹ ni Muritala ko fi aaye alaye silẹ, aṣẹ lo pa, o si ti sọ tẹlẹ pe ti oun ba ti paṣẹ, ẹni yoowu ti oun ba pa aṣẹ naa fun gbọdọ tẹle e lai ba oun jiyan ni. Ṣugbọn ọrọ to delẹ yii, ọba ran ni niṣẹ, odo Ọba kun ni o: iṣẹ ọba ko ṣee ma jẹ, bẹẹ ni odo Ọba ko ṣee fibinu kọlu. Akindele ronu ọrọ naa titi, ko ye e, ohun kan ṣoṣo naa to ye e ni pe ọrọ ti Abiọla sọ foun lọjọ kin-in-ni pe ọrẹ oun ti gbajọba, ki oun ti oun ko si gbe iṣẹ fun ileeṣẹ ITT oun mọ bi oun yoo ti ṣe ara oun si ni. Akindele mọ pe ti oun ko ba ṣe ohun ti Muritala wi yii, ija ni yoo da silẹ, bẹẹ ni ko le ṣe e nitori ohun ti ko ba ofin ati ilana ileeṣẹ wọn mu ni.

Ọgbọn ki i tan laye ki a wa a lọ sọrun. Akindele naa mu iwe, o kọ ọ si akọwe agba ileeṣẹ wọn nibẹ, ohun ti oun naa si kọ niyi: “Akọwe agba, iwe pelebe oke yii ati awọn dokumẹnti to wa ninu faili yii ni mo ri gba lati ọdọ minisita wa. N ko mọ asiko ti ẹka P&T kọwe jade pe awọn nilo irinṣẹ wọnyi. Ati paapaa, ileeṣẹ kan pere, iyẹn ileeṣẹ ITT, lo kọwe lori irinṣẹ naa, awọn yii nikan naa ni wọn si sọ iye ti wọn yoo ta a fun wa. Inu mi yoo dun gan-an bi ẹ ba le ṣalaye fun minisita nipa ilana ti a fi maa n gbe kọntiraati fun awọn ti yoo ba wa ṣe e nileeṣẹ wa nibi, ki ẹ si jẹ ko ye e pe ẹka yoowu to ba nilo irinṣẹ kan ni yoo kọwe jade pe oun n fẹ irinṣẹ bayii, ti yoo si pin iwe to ba kọ naa fun gbogbo ẹka to ku, ti wọn yoo si wo iwe naa lati kọwe si gbogbo awọn ti wọn n taja fun wa ki onikaluku le mu iye ti oun yoo ta tirẹ wa, ko ma jẹ ẹni kan ni yoo da kinni naa ṣe. Nigbakigba ti minisita ba fẹẹ ri mi lori ọrọ yii fun alaye si i, inu mi yoo dun lati ri i.”

MKO Abiọla

Bi Akindele ti kọwe rẹ niyi, oun naa si fi i ranṣẹ si akọwe agba ileeṣẹ naa, ṣe oun lo wa laarin awọn mejeeji, iyẹn laarin Muritala ati Akindele. Boya lo ju ọgbọn iṣẹju ti Akindele fiwe ranṣẹ si akọwe agba naa ti wahala fi bẹ. Minisita funra rẹ lo pe e lori aago pe ko maa bọ lọọfiisi oun kiakia, lai sọsẹ. Aarẹ n pe ọ o n difa, bi Ifa fọ’re, bi aarẹ ko fọ’re nkọ! Ko si aaye iduro mọ, Akindele sare paapaapa, o di ọọfiisi Muritala, nibi ti oun naa ti mọ pe gọngọ yoo sọ. Nigba ti yoo fi debẹ paapaa, akọwe agba naa ti wa nibẹ, o kawọ sẹyin to duro. Muritala paapaa dorikodo nibẹ, ibinu ti mu oju ẹ yatọ, o pọn koko! Bi Akindele ti wọle bayii, ọkunrin ṣọja naa kọ lu u ni: “Sọ fun mi, iru eeyan wo lo ro pe o ja mọ na! Ki lo ro pe o jẹ! Ta ni ẹ gan-an! Ṣebi mo ti sọ fun ẹ tẹle pe ofin ti mo ba ṣe, ko o ma yi i pada! Abi mi o sọ fun ẹ ni … !”

Bo ti n sọ awọn ọrọ yii, bẹẹ lo n mi pokanpokan, ibinu to ru bo o loju kọja afẹnusọ. Ṣugbọn ibinu ti Akindele paapaa ti ju tiẹ lọ lasiko naa, oun naa ti wule kẹkẹ, ko kan ti i ribi bẹ ni! Muritala paapaa ko si ti i sinmi, o n tu bii ejo lọ ni! Akoko ti ọrọ su Akindele to fẹẹ bẹ gan-an ni nnkan kan ṣẹlẹ. Akọwe agba to ti duro sibẹ to n gbọ ọrọ yii pẹlu aibalẹ ara ni ki Muritala jọwọ, oun sare fẹẹ lọọ gbe faili kan wa lọọfiisi oun, n lo ba sare jade ni tiẹ. Bo ṣe jade to tilẹkun ni Akindele bẹ, o doju kọ Muritala, o si sọ fun un pe : ‘Ṣe o ro pe nitori ti wọn fi ẹ ṣe minisita, o kan le maa sọrọ si gbogbo eeyan kaṣakaṣa ni, ko o maa sọrọ, ko o maa ṣe bii ẹni pe iwọ lo ko gbogbo aye jọ! Njẹ o tiẹ mọ pe eyi to o n ṣe yii ko ni i jẹ ka le jọ ṣiṣẹ pọ laelae! Ma tori pe ẹyin ṣọja lẹ n ṣejọba lọwọ bayii ko o ba ọmọluabi ẹ jẹ nao! Ko o kan maa sọrọ si gbogbo eeyan laulau. Ni temi o, emi o ni i fara mọ ko o maa sọrọ si mi bo ba ṣe wu ẹ, ko o dẹ mọ pe ….”

Muritala lanu ko le pa a de, o da bii pe ko ri iru ẹ ri lati ọjọ to ti n rin kiri. Odidi Birigedia ninu iṣẹ ṣọja. Wahala l’Akindele fa lẹsẹ yii o! Bẹẹ, nitori MKO Abiọla ati ileeṣe rẹ, ITT, yii naa ni!

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply