Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (9)

*Idi abajọ ree o

Theophilous Akindele ko ti i pari gbolohun to n sọ lọwọ nigba ti ilẹkun ṣi, ti Ọgbẹni Williams to jẹ akọwe agba fun ileeṣẹ eleto ibanisọrọ (Ministry of Communication) igba naa fi wọle pada, to si lọọ ba ọga ologun, Birigedia Muritala Muhammed, to lanu silẹ, ti ko le pa a de. Bi ọkunrin naa ti wọle ni Muritala ni, “Ọgbẹni Williams, njẹ o jẹ mọ pe bo o ṣe jade tan bayii, eebu buruku ni Ọgbẹni Akindele n bu mi, koda o fẹẹ ba mi ja gan-an ni o!” Ọgbẹni Williams ni, “O ya mi lẹnu lati gbọ eleyii. Mo ti n ṣiṣẹ pẹlu Ọgbẹni Akindele bayii lati bii ọdun mẹrin sẹyin, ko si si ọjọ kan bayii ti a fi ba ara wa jiyan ri, ka ma ti i sọ pe eebu tabi ija!” Muritala wo oju Akindele, o tun wo oju Williams to n sọro, o ni, ‘iyẹn ni pe mo n parọ mọ Ọgbẹni Akindele niyẹn o’. “Williams ni, “Rara, Sa. Mo kan n sọ ohun ti mo mọ nipa Ọgbẹni Akindele ni!”

Akindele ni, “Ẹ ṣeun, Ọgbẹni Williams. Mo n ṣalaye fun ọga lori bi inu mi ṣe maa n dun, ti mo si maa n tẹriba fun gbogbo eeyan ti wọn ba fi ṣe ọga le mi lori ni, ati bi mo ṣe maa n fẹ ki ẹni ti wọn ba fi ṣe ọga le mi lori naa ṣe ẹtọ, ki wọn ṣe deede, ki wọn si fi aanu huwa, ju gbogbo ẹ lọ, ki wọn ba mi sọrọ bii ọmọluabi!” Muritala ko jẹ ki Akindele ba ọrọ rẹ lọ mọ, iwaasu lo jọ loju rẹ, kia lo da a mọ ọn lẹnu. O ni, “O daa, jokoo, Ọgbẹni Williams. Mo fẹẹ ṣepade kekere pẹlu Ọgbẹni Akindele lori faili ati awọn dokumẹnti ti mo fi ranṣẹ si i, mo si fẹ ki o wa nibẹ bii ẹlẹrii mi.” Bo ti sọ bẹẹ tan ni akọwe agba naa tun tọrọ gaafara, o ni ki minisita yii jẹ ki oun sare lọọ gbe faili naa wa gan-an, nitori ọfiisi oun lo wa, nigba ti oun ko si mọ pe lori ẹ ni awọn fẹẹ sọrọ le lori ni ko jẹ ki oun gbe e dani. N lo ba sare bọ sita.

Bi Williams ti bọ sita bayii, Akindele tun dide, o dojukọ Muritala pẹlu ibinu buruku. O ni, “Ojo buruku kan bayii ni ẹ. Oku ojo ni ẹ! O le ma ni apọnle kankan fun mi o, ṣugbọn mi o ni i jẹ ki o sun mi sọ isọkusọ, bẹẹ ni n ko si ni i dakẹ bii ọmọ ojo!” Akindele ṣẹṣẹ fẹẹ maa tu kẹkẹ ọrọ yii ni, ṣugbọn niṣe ni Muritala sare pariwo, o pe akọwe tiẹ, o ni, “Sọ fun Ọgbẹni Williams ko maa sare pada bọ, ni ko ma lọ mọ, ko maa bọ!” Itosi ni akọwe Muritala wa, o si gbọ aṣẹ ti minisita naa n pa. Williams funra ẹ ko ti i rin jinna, lo ba sare pada wọle. Muritala sọ pẹlu ibinu fun un pe, “Ṣe o mọ pe bi o ṣe tun jade yii, niṣe ni Ọgbẹni Akindele ni alafojudi ati ojo minisita ni mi! O ni oku ojo kan bayii ni mi!” Ṣugbọn ko too pari ọrọ rẹ, Akindele ti dide, o si sẹ ọrọ naa jalẹ loju Williams, o ni oun ko ba minisita naa sọ iru ọrọ bẹẹ, nitori oun ki iṣe alariifin.

Akindele mọ ohun ti Muritala fẹ. Gbogbo ohun to n fẹ ni ko ni ẹlẹrii kan ti yoo sọ pe loootọ ni oun ri minisita oun fin, nigba naa ni Muritala yoo lo agbara rẹ gẹgẹ bii minisita, ti yoo si ri i pe iya buruku jẹ Akindele: iya kekere si kọ, nitori wọn le le e danu lẹnu iṣẹ to n ṣe. Niwọn bi ti ko ti ri eleyii ṣe ṣaa, ti Akindele ti sọ pe oun ko sọ ọrọ abuku kan si i, ko si ohun to le ṣe. N lo ba ni ki Williams lo tẹlifoonu to wa lori tabili oun, ko fi pe akọwe ẹ, ko ni ko gbe faili naa wa, ko ma lọ sibi kan mọ, ko ma fi oun ati Akindele silẹ sinu ọfiisi yii, nitori oun ko tun fẹ eebu ati ariwo. O ni, “Nigba yoowu ti mo ba ti fẹẹ ri Ọgbẹni Akindele, mo maa fẹ ko o maa wa nibẹ pẹlu wa. “Ni Akindele naa ba dahun pe ọrọ naa ko le rara, gẹgẹ bi ofin iṣẹ ọba, ohun yoowu to ba fẹẹ ba oun sọ, o le sọ ọ fun akọwe agba, akọwe agba ni yoo si pada sọ foun, ti oun yoo si ṣe ohun ti Muritala gẹgẹ bii minista ba fẹ ki oun ṣe.

Akọwe agba naa jẹrii si i pe bẹẹ gan-an lọrọ ri, ti wọn ba fẹẹ maa tẹle ofin to wa nilẹ. Nigba ti akọwe agba naa si ti jẹrii si i pe bẹẹ ni eto iṣẹ ọba ri yii, Akindele mọ pe ko si bi Muritala yoo ṣe fi ẹsun afojudi kan oun, ti yoo ni oun ri oun fin, nigba ti ko ba jọ si ajọṣe kankan laarin wọn. N lo ba yaa tọrọ aaye, o ni “Pẹlu alaye yii, Sa, mo nigbagbọ pe ẹ le jẹ ki n maa lọ!”  N lo ba ko iwe tiẹ, o si jade ni ọfiisi Muritala, minisita naa si n wo o bo ti n lọ, oun naa ko le wi kinni kan. Akindele ro pe ibẹ ni ọrọ ileeṣẹ ITT yii yoo de duro ni, pe oun ko tun ni i gbọ kinni kan nipa rẹ mọ, oun ko mọ pe ọrọ naa ṣẹṣẹ bẹrẹ, tabi pe ija ṣẹṣẹ bẹrẹ gan-an ni, nitori ohun ti Muritala n gba lero ki i ṣe kekere, oun si mọ pe ẹgbẹrun Akindele ko le da oun duro, oun ṣaa ni minisita, ohun to ba si wu oun loun le ṣe nileeṣẹ ti wọn ti fi oun ṣe olori ẹ.

Ahesọ ọrọ lo kọkọ bẹrẹ, ti wọn si n gbe kinni naa kaakiri pe ọga agba pata nileeṣẹ eleto ibanisọrọ ko le ba minisita ẹ ṣiṣẹ papọ, wọn n ja lojoojumọ, minisita naa si ti sọ pe ki wọn gbe e kuro lọdọ oun, eyi ni pe Akindele ti ko ẹru ẹ, ko wọ mọto lo ku, ọmọkunrin n lọ bi a ti kọwe rẹ! Kia lawọn eeyan bẹrẹ si i sa fun un, awọn darẹkitọ ti wọn jẹ ọmọlẹyin rẹ ko de ọdọ rẹ mọ, nitori ẹni yoowu ti wọn ba ri to n rin mọ ọn yoo di ẹni apati ni. Oun ko mọ pe ni gbogbo asiko yẹn, akọwe agba, ati ọkan ninu awọn darẹkitọ to wa labẹ oun ti n kọ iwe iṣẹ ITT yii, wọn n mura lati gbe e lọ siwaju igbimọ apaṣẹ ologun ti yoo fi aṣẹ si kọntiraati naa fun ITT. Nigbẹyin, Akindele gbọ pe wọn yoo gbe iwe iṣẹ ITT yii lọ sibi ipade igbimọ yii ti inu oṣu kẹsan-an, ọdun 1974. Olori ijọba ologun funra ẹ ni alaga ipade yii, akọwe agba ati Akindele funra ẹ yoo wa nibẹ, ṣugbọn bii oluworan lasan ni, wọn ko le sọrọ, afi ti wọn ba pe wọn lati da si i.

Nigba ti wọn depade, Akindele ri i pe ninu awọn ohun ti wọn yoo jiroro le lori ni ọrọ iṣẹ agbaṣe pajawiri ti ileeṣẹ onitẹlifoonu nilo, ipo kẹta si ni kinni naa wa ninu eto ijiroro ipade wọn. Nigba ti ijiroro lori ọrọ yii bẹrẹ, minisita funra rẹ, iyẹn Muritala, ṣalaye bi iṣẹ naa ṣe ṣe pataki to, ati bi wọn ṣe gbọdọ ṣe e lẹsẹkẹsẹ. Awọn kọmiṣanna to ku nibẹ da si i, wọn ni ọrọ naa daa, awọn si fara mọ eto naa. Ọrọ naa ti da bii pe o fẹẹ yanju tan, afi bi Yakubu Gowon to jẹ alaga igbimọ yii ṣe kọju si Akindele, lo ba ni, “Ọga agba eto ibanisọrọ, ṣe ẹ mọ nipa iṣẹ tuntun yii o!” Akindele ko raaye ronu lori ọrọ yii, nitori kinni naa ba a lojiji. Lo ba dide fuu, o ni, “Ọlọla wa, emi ko mọ kinni kan nipa iṣẹ yii, koda, aarọ yii ni mo ri i bi awọn to ku ti n ri i!” Niṣe ni gbogbo ipade naa dakẹ lọ mini mini, ko sẹni to le gbin. Gowon doju kọ Muritala, o ni, “Ṣe loootọ ni?”

Muritala, gẹgẹ bii iṣe rẹ, ni, “Ootọ ni. Ọkunrin yii ko fọwọ sowo pọ pẹlu wa ni. Mi o si le jẹ ko da iṣẹ ti mo fẹẹ ṣe duro. Ka kuku tiẹ sọ ọ, o ti pẹ ju nibi to wa yẹn, ko wulo kankan nibẹ mọ!” N lawọn to ku ba gbẹrin, ṣugbọn Gowon gẹgẹ bii alaga ipade ko rẹrin-in, kaka bẹẹ, o ni, ‘Kọmiṣanna, awọn oṣiṣẹ ijọba wa ni igi lẹyin ọgba fun wa. Awọn ni oludamọran wa, bi a ba fẹẹ ṣe ohunkohun, wọn ki i ṣe ẹni arifin, tabi ẹni asọrọ si rara. Bi nnkan ba daru, awọn lara ilu yoo bu, nitori ẹ lo fi jẹ amọran yoowu ti wọn ba fun wa, a gbọdọ gba pẹlu apọnle ni!” Inu Muritala ko dun, oun naa kọju si Gowon, o ni, “Nigba ti ẹ fẹẹ fi mi ṣe kọmiṣanna (Minisita), mo sọ pe afi ti ẹ ba maa jẹ ki n ṣe iṣẹ naa bo ṣe wu mi. Ko ye mi bayii mọ o, pe ẹni kan to ti sọ ara ẹ di Ọlọrun lo maa da iṣẹ pataki bayii duro. Ẹ kan n faaye gba a lati di ilọsiwaju ilu lọwọ ni!”

Inu bi Gowon, ṣugbọn ko sọrọ ibinu, o kan dakẹ jẹẹ ni. Nigba ti yoo sọrọ, o ni ki Akindele ko gbogbo iwe naa, ko pada lọọ ṣiṣẹ lori rẹ, ko si gbe e pada wa fun igbimọ laarin ogunjọ pere. O sọ fun un pe gbogbo iru iṣẹ olowo nla bayii ki i ṣe iṣẹ ti eeyan n kanju ṣe, afi ki wọn yẹ ẹ wo finnifinni. N nipade ba tuka, ibinu Muritala ko si ṣee royin, afi bi ibinu ina! Itiju Williams ti i ṣe akọwe agba naa gàgaàrá, o doju bolẹ lai le gbin! Ṣugbọn ija yii ko ti i tan, o ṣẹṣẹ n fẹju bọ ni. Nitori ITT si ni, ileeṣẹ awọn MKO Abiọla.

Leave a Reply