Nibo ni agbara Yoruba wa: Njẹ Yoruba tiẹ lagbara kankan mọ

Nigba ti ibo ọdun to kọja yii n bọ lọna, emi ati ọrẹ mi kan ja, ija naa ko pari titi di ẹnu ọjọ mẹta yii. Ọrọ kekere kan lo si fa ija naa lasiko ti ibo ọhun ku si dẹdẹ. Nibi ti wọn ti n sọrọ ẹni ti wọn maa dibo fun, ti ọrẹ mi ni ko sohun meji toun aa fi dibo fun Buhari ju nitori Yẹmi lọ. O ni Yẹmi ni igbakeji Buhari, ọmọ Yoruba ni, ati pe to ba wa ninu ijọba naa, kinni kan ko ni i ṣe Yoruba laelae. O ni nigba ti Ọlọrun kuku tiẹ waa ṣe e, lọọya to mọ’we ofin gidi ni Yẹmi, ohunkohun ti wọn ba gbe wa, ofin lo maa fi yanju ẹ. Mo ṣalaye kan fun ọrẹ mi yii nijọ naa. Mo ni baba kan bi ọmọ mẹta, ẹyọ kan lo kawe, awọn meji ya tọọgi. Ni wọn ba n ja si ile kan ṣoṣo ti baba wọn kọ. Ọkan yọ ọbẹ alaṣooro ninu awọn tọọgi yii, ekeji yọ daga, eyi to kawe waa yọ biro, o loun aa fi gege pari wọn. Mo ni ṣebi nigba to ba raaye jade kuro nile ọhun lalaafia ni. Tabi ibi ti wọn ti yọbẹ ati daga si i naa lo ti maa yanju wọn.

Mo ṣalaye fun ọrẹ mi pe ni awujọ awọn ọmọwe ni Yẹmi ti le wulo, ti gbogbo ofin to mọ aa ti ṣiṣẹ, ṣugbọn awujọ to n lọ yii, awujọ awọn Fulani ni. Wọn ko mọwe, iwa pupọ ninu wọn ko si yatọ si ti ẹranko. Lati rufin ko jẹ kinni kan loju wọn, wọn ko si ni i tẹle ofin ti wọn ba ti ri i pe ki i ṣe ohun ti awọn fẹ lo wa nibẹ. Mo sọ pe ibo ti wọn fẹẹ di ti wọn ni Yẹmi lawọn fẹẹ di i fun yii, ki i ṣe Yẹmi ni wọn n dibo fun, koda ki i ṣe APC, Fulani ni wọn fẹẹ dibo fun, Fulani aa si foju wọn ri mabo. Ohun to bi ọrẹ mi ninu niyi. O ni kin ni mo miini, pe nibi ti Aṣiwaju wa, mo mọ pe Bọla lo n sọ yẹn, ti Baba Akande wa, mọ si mọ pe Bisi lo n sọ bakan naa. O ni wọn o bi  Buhari daadaa ko gbe ọwọkọwọ kan, ati pe ikọkukọ ti emi n kọ fawọn Alaroye lo ti ko si mi lori.

Ọrọ yii dun mi gan-an, nitori pe ọkan ninu awọn ọjọgbọn wa lo n sọ bayii fun mi. Ọmọwe gan-an ni, purofẹsọ to si ti gba oriṣiiriṣii oye ni. Nitori bẹẹ lo ṣe dun mi. Bo ba ṣe awọn ti ko fi bẹẹ kawe, tabi ti iriri aye ko ye, tabi awọn ti wọn ko kuro loju kan, ni wọn n ba mi jiyan lori ọrọ Fulani, koda ki wọn bu mi, ko ni i jẹ kinni kan loju mi. Ṣugbọn ọrẹ mi yii, ọjọgbọn ni laaye ara rẹ, agbalagba si ni lọjọ ori. Ni mo ba dọgbọn yẹra, latigba naa n o jẹ sọrọ to jẹ mọ ti oṣelu, tabi ti Buhari ati awọn Fulani ẹ. Nigba ti Buhari wọle lẹẹkeji tawọn Fulani bẹrẹ si i paayan, ti wọn n ji awọn eeyan wa gbe, bi emi ati ọrẹ mi pade a ko jẹ sọrọ debẹ, kaluku n pẹ ọrọ naa silẹ ni, bẹẹ a n sọrọ. Ṣugbọn lọjọ ti awọn Fulani pa Funkẹ, ọmọ aṣaaju wa, Faṣọranti, lọna Akurẹ, ọrẹ mi ko le mu kinni naa mọra mọ.

Nigba to ri mi, ti mo yọ sibi ti a ti lọọ ba baba daro, niṣe lo fi awọn ti wọn jọ duro tẹlẹ silẹ, to waa so mọ mi, to si n fi agbalagba ara ja omije si mi lara. Emi naa fẹrẹ le sunkun, nitori mo ri i pe ki i ṣe ọrẹ mi yii nikan ni nnkan bajẹ fun, gbogbo Yoruba ni. Tabi nibo ni agbara Yoruba wa, nibo ni agbara wa ku si. Bi ẹni kan ba n pariwo lori redio tabi lori ẹrọ ayelujara, tabi to n kọ oriṣiriiṣii ọrọ jade lori intanẹeti pe Yoruba ni baba, agbara wa pọ ju, ṣe ki i ṣe pe a n tan ara wa jẹ ni! Nibo ni agbara ọhun wa. Ṣe agbara kan wa lọwọ Yẹmi to jẹ igbakeji Buhari ni! Wọn ni wọn jọ n ṣejọba, ọjọ wo lo ri Buhari gbẹyin, ṣebi awọn ọmọ ọdọ lasan ni wọn n ran si i; ẹni to ba si laya ninu awọn ti wọn ran niṣẹ yii ko ni i jiṣẹ ti wọn ran an, iṣẹ tara ẹ lo maa jẹ, ohun ti wọn ba fẹ ki Yẹmi ṣe lo maa ṣe.

Tabi agbara wo ni Yẹmi ni, aṣẹ wo lo le pa! Ta ni fẹẹ paṣẹ ọhun fun. Bọla ti gbogbo eeyan ti ro pe oun lo maa dari wọn l’Abuja, oun ni yoo jẹ baba-isalẹ fun Buhari paapaa, ọjọ meloo lo gba wọn ti wọn fi le e sẹyin. Ẹ ma da awọn oloṣelu wa nibi lohun o, awọn ti wọn maa ti Abuja de ti wọn aa maa ko agbada kiri guọguọ, ti wọn aa maa lo mọto ọlọpaa, ti mọto aa maa ke ‘yaa-fun-un yaa-fun-un’ niwaju ati lẹyin wọn, ariwo lasan ni wọn n pa, ilẹ Yoruba nikan ni ihalẹ wọn mọ. Gbogbo wọn pata, mo tun sọ ọ, mo tun un sọ, gbogbo wọn pata, lati ori ọga de ọmọọṣẹ, ko sẹni ti wọn bi daa to n lo mọto ‘yaa-fun-un yaa-fun-un’ lAbuja ninu wọn. Eko ati ilẹ Yoruba nikan ni wọn ti n fi eyi halẹ mọ araalu, nibi ti iṣoro wa si wa gan-an niyẹn. Kaka ki wọn sọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ, won aa maa ti ọwọ to n dun wọn sabẹ aṣọ.

Nibo ni agbara Yoruba ku si ni Naijiria yii. Odidi ọba alaye ni wọn pa bii ẹni pa aja lasan yii. Odidi aṣaaju ọba nilẹ Yoruba. Odidi Olufọn! Ẹru ko ba wọn, aya ko si ko wọn, won pa odidi ọba laarin wa! Fulani! Ṣugbọn ki lo fẹẹ ba wọn lẹru! Ṣe lati ọjọ ti wọn ti pa ọba yii, ṣe Buhari lo sọ pe oun gbọ ni, abi awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ. Ta ni wọn ri mu! Ṣe ọlọpaa n wa ẹni kan kiri ni! Bi ọlọpaa si ri Fulani mu, kin ni wọn yoo fi i ṣe. Awọn ti wọn ti mu tẹlẹ, nibo ni wọn wa, ati ibo ni wọn ba ẹjọ wọn de. Ṣebi wọn kan n paayan lapagbe ni tiwọn ni! Bo ba ṣe pe oloṣelu ilẹ Yoruba kan lagbara ni, ṣebi asiko ti wọn iba lo agbara naa ti gbogbo aye iba ri i ree! Bi ẹni kan ba wa ti awọn ijọba Buhari n bẹru nilẹ Yoruba, tabi ti wọn ro pe tọhun le ṣe ohunkohun, ṣebi asiko to yẹ ki tọhun jade ko ṣe atilẹyin fun wa niyi.

Ṣugbọn ko si agbara lọwọ ẹni kan ninu awọn eeyan wa yii, wọn kan n janu lasan ni. Awọn ti wọn ni awọn loogun ko ri oogun lo, awọn ti wọn ni awọn ni ajẹsara kankan a ko gburoo wọn. Awọn ọmọ wa ti a ni lọlọpaa, awọn ti a ni ni ṣọja, awọn ti a ni nidii oṣelu, awọn ti a ni nidii iṣẹ ijọba apapọ, gbogbo wọn kan wa nibẹ ni, wọn ti gba wọn sẹgbẹẹ kan, a ko si gbohun ẹni kan. Abi gbogbo bi nnkan ti n lọ yi, ka ma tiẹ rẹni kan jade ninu awọn ti a n fi oju eeyan nla wo, ko jade, ko ni ohun tawọn Fulani n ṣe yii ko dara. Yatọ si awọn ajijagbara, Afẹnifẹre ati awọn onileeṣẹ adani diẹ ti wọn n fọhun labẹlẹ pe ki wọn ma sọ Yoruba di ẹru, ko sẹni to gbohun ẹni yoowu to ni nnkan kan i ṣe pẹlu ijọba Buhari. Bi o tiẹ ri awọn oloṣelu wa, wọn aa ni APC lawọn, ohun ti Buhari n ṣe lo daa.

Bẹẹ, njẹ o yẹ ki a tori oṣelu ta iran ẹni nu bi? O yẹ ki awọn oloṣelu tori pe awọn jọ n ṣe ẹgbẹ kan naa ati Buhari, ki won jẹ ki Yoruba di ẹru Fulani titi aye ni. Tiwa naa wa lara wa o! Ṣugbọn ki eeyan le akata lọ ko too fabọ ba adiẹ ni. Odidi ọba ni wọn pa yii. Bi o ba ri wọn laafin, awọn naa ni wọn aa maa foyinbo, ti wọn aa lawọn o gbọ Yoruba, awọn ni wọn aa ni oloṣelu kan lawọn n tẹle, awọn naa ni wọn aa lawọn ki i ṣe aboriṣa, awọn o si fẹran nnkan abalaye Yoruba nitori nnkan oriṣa ni. Bẹẹ, eyi Islaamu, wọn ko ṣe e daadaa; eyi Kristẹni, won ko ṣe e yanju, wọn kan wa gbu-n-duku ni. Awọn ọba ko ri bii awọn ọba wa ti ri latijọ mọ. Ṣugbọn iyẹn ko fun awọn Fulani laṣẹ lati maa pa awọn ọba ati awọn eeyan wa nipakupa bayii, bo ba  ṣe pe Yoruba lagbara kankan nile ijọba ni.

Nibo lawọn ọmọ  Yoruba wa! Nibo ni agbara Yoruba ku si! Ẹyin ọmọ Yoruba, ẹ dide; nnkan ma n bajẹ lọ o!

3 thoughts on “Nibo ni agbara Yoruba wa: Njẹ Yoruba tiẹ lagbara kankan mọ

  1. Enibasole nu o so apo iya ko . Latigbati ati esin ba nkan nsembaye awon babawa je. Ti atisowipe kokinse nkan dada . Latigbayen ni awon irunmole tiwonojeki ogun ojawa nile yoruba koti ri tiwano ro mo dada. Etititori esin ajoji ba ti babanlaku yinje. Ona dori apatapin. Eje pada si ese aro kaberesini be awon alale ile yoruba ati gbogbo awon irunmole tiwonti binu salo kiwon padawa ki alebolowo awon amunisin yi. Mosibo na

  2. Ki awon tiwon nbo ogun kiwonpe ogun ni oruko ti ogun nje ki ogun ledide. Awon tiwon nbo Sango kiwon pe sango ni oruko tounje. Awon tiwon nbo oya kiwon pe oya ni oruko tounje. Awon oni sapana kiwon sapana lowe si gbogbo awon tiwon nda ile yoruba lamu. Ki awon babalawo wa dide kiwonfi ebo ati etutu jagun. Kabale ni isinmi nilewa o . Amoran Temi niyen o

Leave a Reply