Nigba t’Abiọla atawọn eeyan rẹ kọju ija si Awolọwọ ni 1979 (Apa Kẹfa)

*Idi abajọ ree o

Olori ijọba ologun igba naa, Ọgagun agba Yakubu Gowon, lo ni ki akọwe ijọba wọn kọwe fesi si Theophilous Akindele ti i ṣe ọga agba pata fun ileeṣẹ eleto ibanisọrọ ilẹ wa ni 1973 yii, lori iṣẹ pataki kan ti ijọba fẹẹ ṣe ni. Ijọba fẹẹ ri awọn irinṣẹ ibanisọrọ kan mọlẹ, eyi ti wọn yoo fi le maa mọ ohun gbogbo to ba n lọ ni idakọnkọ, tawọn eeyan ko si ni i mọ pe wọn mọ ohun to n lọ yii gan-an. Iṣẹ awo ni iṣẹ naa, iṣẹ ti aṣiri rẹ ko gbọdọ lu sita ni. Nigba to jẹ ijọba ologun lo wa lori aga, awọn ologun ni yoo ṣeto naa funra wọn, ṣugbọn awọn ileeṣẹ eleto ibanisọrọ yii ni yoo lana ẹ fun wọn, awọn ni wọn yoo sọ ibi to dara ati irinṣẹ to dara ti wọn yoo lo lati ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe naa. Lọrọ kan, bo tilẹ jẹ pe awọn ologun lo n ṣiṣẹ yii, amọran ti ileeṣẹ eleto ibanisọrọ ba fun wọn ni wọn gbọdọ maa tẹle ki wọn too ṣe e.

Nidii eyi, bi ọga ileeṣẹ ibanisọrọ ti ṣe lagbara lori iṣẹ yii, bẹẹ naa ni ọga ẹka awọn ologun to n ri si eto ibanisọrọ tiwọn naa lagbara lori ohun ti wọn fẹẹ ṣe. Bi wọn ti gbe iwe eto yii ranṣẹ si Akindele naa ni wọn gbe e ranṣẹ si Muritala Muhammed, awọn mejeeji ko kan mọ pe awọn naa lawọn yoo tun jọ ṣiṣẹ pọ ni. Afi nigba ti Akindele pe ọga awọn oloogun to n ri si eto ibanisọrọ yii, nigba to jẹ oun ni wọn yoo jọọ ṣepade, lo ba tun di Muritala, ẹni ti oye rẹ ti kuro ni Kọnẹẹli nigba ti wọn kọkọ pade nijọsi, o ti di Birigedia, ọga awọn ologun. Lọrọ kan, awọn mejeeji jọ sọrọ, wọn jọ ṣe bii ẹni pe ko sija, bo tilẹ jẹ wọn ko fi taratara yọ mọ ara wọn. Ni wọn ba jọ fipade si teṣan ileeṣẹ “P and T” to wa ni Falọmọ, wọn ni ki wọn pade ni aago kan ọsan geere. Akoko ti Muritala sọ pe yoo dara ju lọ niyẹn.

MKO Abiọla

Nigba ti Akindele n lọ, gẹgẹ bii aṣẹ tawọn ti wọn gbeṣẹ fun un pa, o mu akọwe agba ileeṣẹ eleto ibanisọrọ ijọba apapọ yii, S. O. Williams, dani, bakan naa lo si ranṣẹ si alakooso eto ibanisọrọ fun gbogbo agbegbe Eko, nitori labẹ akoso rẹ ni wọn yoo ti pada ṣe iranlọwọ lori iṣẹ naa fawọn ologun. Ni deede aago kan ku iṣẹju marun-un, Akindele debi ipade naa ni Falọmọ, oun ati akọwe agba ti wọn jọ wa. Ṣugbọn Muritala ko de ni aago kan, ko de laago kan kọja iṣẹju mẹwaa paapaa. Aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdọgbọn lo too de. Ni gbogbo asiko yii, ibinu Akindele ti n ru soke, pe iru idaduro wo leleyii nitori Ọlọrun. Nigba ti Muritala tun waa de, oun ko tọrọ gaafara, bẹẹ ni ko tọrọ aforijin kan fun pe o da awọn eeyan yii duro, o kan wọle, o si bẹrẹ si i sọ ohun to fẹ ki wọn ṣe fun wọn ni. O ni:

“Ẹyin eeyan, nnkan ti mo fẹ niyi. Ẹ tu gbogbo awọn waya yin to wa ni adugbo yii ka, ki ẹ ri i pe awọn opo to wa nibẹ ko ni kinni kan lori mọ, igba yẹn ni mo too le ṣe ohun ti mo fẹẹ ṣe. Ṣe ọrọ mi ye yin bẹẹ yẹn.” Nitori ija to ti wa nilẹ tẹlẹ, Muritala ko kọju si Akindele, bẹẹ ni ko tilẹ ṣe bii ẹni to ri awọn to ku, Williams ti i ṣe akọwe agba lo kọju si, to n ro gbogbo ẹjọ to wa lọkan rẹ fun un. Ṣugbọn akọwe agba yii ko ni esi ti yoo fun Muritala, nitori bẹẹ, esi to le fun un naa ni pe, ‘Oludari agba ileeṣẹ ibanisọrọ lo maa mọ gbogbo ohun ti ẹ n beere yii, oun lo le sọ bi yoo ti ri, ati bi yoo ṣee ṣe tabi ko ni i ṣee ṣe!” Ni Akindele ba sọrọ, bo si tilẹ jẹ pe ibinu ẹ ti ga soke bayii, oun saa ṣe suuru debi to le ṣe e de, o fi ohun tutu diẹ sọrọ, bo tilẹ jẹ inira lo jẹ fun un. O kọju si Muritala, o si sọ fun un pe:

“Birigedia, idi ipade ti a waa ṣe yii ni lati mọ ọna to dara ju lọ ti a fi le ṣe irimọlẹ awọn irinṣẹ ti a fẹẹ lo fun iṣẹ yii, n ko si lero pe o wa ni aaye kankan lati le paṣẹ lori bi iṣẹ naa yoo ti ṣe lọ si. Emi ni mo le fun ọ nimọran lori ohun ti ẹ fẹẹ ṣe yii, ati ọna ti kinni naa yoo fi daa. Mo ti wo gbogbo agbekalẹ eto naa ati bi irinṣẹ naa ti ri, ẹ ko le ri i mọlẹ ni apa ibi yii, afi ki ẹ wa ibi ti ero ko pọ si, ibi yii ki i ṣe ibi ti o ba iru iṣẹ bẹẹ mu.” Muritala ko jẹ ki Akindele pari ọrọ rẹ nigba to fa ibinu yọ, o sọ pe, “Ọgẹni Darekitọ, ohun to gbe mi wa sibi yii ni lati paṣẹ ohun ti mo fẹ ko o ṣe fun ẹ, mi o wa sibi ki o waa fun mi ni idanilẹkọọ rara.” Akindele ta ku. O ni, “Emi ni mo le paṣẹ kinni yii, nitori emi ni mo ni imọ lori bo ṣe le ṣee ṣe ati ọna to dara ju lọ lati gba ṣe e! Mo wa sibi lati gba ọ nimọran lori iṣẹ naa ni, nitori iṣẹ tẹ ẹ fẹẹ ṣe yii ki i ṣe iṣẹ ti awọn eeyan n ri ni gbangba, iṣẹ to gbọdọ wa ni kọrọ patapata ni.”

Yakubu Gowon

Eleyii tun bi Muritala ninu. O ni, “Bawo ni iwọ sifilian lasanlasan ṣe mọ iru iṣẹ ti awa ologun fẹẹ ṣe! Abi iru palapala wo tiẹ leleyii” Akindele naa tun dahun, “Mi o le ṣe ki n ma mọ ọn, nitori emi ni mo ṣe agbakalẹ ẹ, emi ni mo pilaani gbogbo ohun ti ẹ fẹẹ ṣe yii. Mi o ni i sọ ju bẹẹ lọ!” Pẹlu oju pipọn ati ibinu gidi, Muritala kọju si alakooso eto ibanisọrọ fun gbogbo agbegbe Eko to wa nibẹ, Ọgbẹni Uzoigwe, o ni ṣe gbogbo ohun ti oun wi yẹn yoo ṣee ṣe laarin ọsẹ kan pere. Niyẹn ba fi ọgbọn da a lohun pe ọga oun agba, iyẹn Akindele, nikan lo le mọ bi yoo ṣee ṣe tabi ko ni i ṣee ṣe. Nigba ti iyẹn tun sọ bayii, ibinu Muritala ko ṣee pa mọra mọ, o binu, lo n da ilẹ laamu, lo n fara ya rẹkẹrẹkẹ. Nigba ti Akindele naa si ri i pe ibinu toun naa ti fẹẹ doju gẹngẹto, o yaa ko faili rẹ mọlẹ, n lo ba fi Muritala ati awọn akọwe ijọba to ku silẹ nibẹ, o jade lọ!

Nigba ti Akindele de ọọfiisi rẹ, o pe akọwe ijọba apapọ, o si ṣalaye ohun to ṣelẹ fun un pe Muritala ko jẹ ki awọn jọ jokoo ronu o, kaka bẹẹ, niṣe lo n bu oun atawọn oṣiṣẹ oun, to si n sọrọ alufanṣa oriṣiiriṣii sawọn. Akọwe ijọba apapọ gbe ọrọ naa paa, o di ọdọ Gowon, ọrọ yii si ka olori ijọba ologun ana lara gan-an. Nigbẹyin, lẹyin ti wọn ti gbe ọrọ naa wo sọtun-un sosi, ohun ti Akindele sọ naa ni wọn pada waa tẹle, nitori gbogbo ọrọ to sọ pata lori iṣẹ naa lo ye awọn ọmọ igbimọ apaṣẹ ologun to ku, ti wọn si ni bo ṣe yẹ ko jẹ gan-an niyẹn. Nitori rẹ, wọn fi Falọmọ ti Muritala ni oun fẹẹ lo, ti Akindele sọ pe ko daa, silẹ, wọn wa ibomi-in ti awọn Akindele yii kan naa wa fun wọn lati ri irinṣẹ naa si, o si dara bi wọn ti ṣe e. Ṣugbọn ọrọ naa ka Muritala lara de gongo, pe iru Akindele, sifilian lasan, ni yoo maa kọ aṣẹ oun olori ologun.

Idi niyi to fi jẹ nigba ti MKO Abiọla pe Akindele ni aarọ kutuktu ọjọ yii pe wọn ti fi ọrẹ oun, Birigedia Muritala, ṣe kọmiṣanna (minisita) fun eto ibanisọrọ, eyi to sọ ọ di ọga Akindele pata, idi ọkunrin naa domi. Oun naa ranti gbogbo ohun to ti re kọja laarin awọn mejeeji, ko si si onifa ti yoo ṣẹṣẹ sọ fun un pe Muritala ko fẹran rẹ, gbogbo ohun to ti n wa lati ọjọ yii ni ọna ti yoo gba mu un. Ni bayii, ọna naa ti ṣi silẹ gbayau, Muritala ti di ọga, oun si ti di ẹni keji rẹ ti awọn yoo jọ maa rira lojoojumọ, ti awọn yoo jọ maa ṣeto ibanisọrọ bayii. Ko si ki ọrọ naa ma di ariwo ati wahala, Akindele naa si mọ pe ni bayii, bi ariwo kan ba le ṣelẹ, Muritala ni yoo jare, nitori oun ṣaa lọga oun.  Loootọ ni Akindele ju Muritala lọ lọjọ ori, ṣugbọn ipo to wa yii ju tirẹ lọ. Ati pe nigba to ranti ohun to wa laarin oun ati Abiọla tẹlẹ, lori ọrọ ileeṣẹ ITT, o mọ pe nnkan naa ko ni i rọgbọ.

Kia lo palẹ ẹru ẹ mọ niluu oyinbo to wa, ile ya! Oun ati Muritala gbọdọ koju ara wọn!

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply