Ni asiko ti wọn n pariwo pe ki wọn fi Awolọwọ silẹ lọgba ẹwọn yii, iṣẹlẹ kan waye ni Naijiria, ohun to ko idunnu ayeraye ba awọn kan, to si fi ọkan wọn balẹ ni, ṣugbọn ọrọ to ko ọkan awọn mi-in soke, ti ko fi wọn lọkan balẹ rara ni. Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu keji, ọdun1965 ni, ọjọ naa jẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ Aje. Ọjọ yii ni wọn kede ọmọ Naijiria kan ti yoo di olori ṣọja nilẹ wa. Ṣe titi di ọjọ kẹrinla, oṣu keji, 1965 yii, ọkunrin oyinbo kan lolori ṣọja nilẹ yii tẹlẹ, Ọgagun agba, E. C Edvard, lorukọ oyinbo naa, o si ti fi ọdun mẹrin ṣe olori awọn ṣọja ilẹ wa. Ṣugbọn akoko adehun to wa laarin oun ati ijọba Naijiria ti pe, o si ti to asiko fun un lati lọ. Ṣugbọn ohun ti ijọba Naijiria ko tete mọ ni boya ki wọn jẹ ko maa lọ ni, ki wọn gba ẹlomi-in rọpo rẹ lati ilu oyinbo yii kan naa, lati fi rọpo rẹ, tabi ki wọn mu ọmọ Naijiria kan lati maa ṣe olori awọn ṣọja naa lọ.
Ni gbogbo asiko yii, ọmọ Naijiria ni olori awọn ọlọpaa, orukọ rẹ si ni Louis Edet, wọn si ti yan Joseph Wey, gẹgẹ bii olori awọn ọmọ ogun oju omi. Ṣugbọn gbogbo eeyan lo mọ pe nibi ti iṣẹ wa gan-an ni lati yan olori awọn ṣọja, nigba to jẹ ninu awọn ologun gbogbo yii, ṣọja lo lagbara ju. Ọrọ naa n di ti awọn oloṣelu, nitori awọn oloṣelu ilẹ Hausa ko fẹ rara ko tun jẹ eeyan lati iha Guusu Naijiria ni yoo di olori awọn ṣọja. Olori awọn ọlọpaa ati olori Nefi ti wa lati Guusu, wọn n reti pe ki olori awọn ṣọja wa ti Ariwa ni, wọn ni ohun to le dara ju, ti yoo si mu ki gbogbo nnkan ṣe deede niyẹn. Ṣugbọn ko si ṣọja to kun oju oṣuwọn to ninu gbogbo awọn sọja to wa ni Naijiria ju ọkunrin kan ti oun jẹ ọmọ Ibo lọ, oun ni ipo rẹ ga ju ninu gbogbo awọn ṣọja, Mejọ-Jẹnẹra si ni oye rẹ nigba to lọọ jagun ni Kongo, nibi ti agbara ati ipo ọkunrin naa ga de.
John Thomas Umunakwe Aguiyi Ironsi lorukọ rẹ, ṣugbọn Aguiyi Ironsi lawọn ti wọn mọ ọn n pe e, ọjọ oun naa si ti pẹ ninu ologun. Ọdun 1942 lo ti wọ iṣẹ ṣọja, nigba to si lo ọdun meje ninu iṣẹ ọhun lo di ọọfisa ni 1949, nibẹ ni agbega oriṣiirisii ti n ba a. Ṣugbọn ni ọdun 1956 gan-an ni orukọ ọkunrin naa kọkọ jade sita, gẹgẹ bii ṣọja nla ti Naijiria ni. Nigba naa ni Ọbabinrin ilu Oyinbo ti wọn n pe ni Queen Elizabeth ṣe abẹwo silẹ wa. Ṣe lọjọ naa lọhun-un, ọba ilu oyinbo yii ni olori Naijiria, nitori abẹ awọn oyinbo la wa, oun ni ẹni to ni Naijiria, gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ kan jẹ bii iranṣe fun un lasan ni. Ni 1956 yii paapaa, ki i ṣe ọmọ Naijiria ni olori ijọba ilẹ wa, oyinbo ni olori, awọn ni wọn n sẹjọba. Awọn oyinbo ti wọn jẹ olori Naijiria yii naa ni wọn gbalejo ọbabinrin yii, iyẹn nigba to waa ṣe abẹwo silẹ wa.
Nigba to n bọ, ẹni ti wọn mu nigba naa pe yoo maa ṣọ Queen Elizabeth, pe yoo maa tẹle e kaakiri ibi yoowu to ba fẹẹ lọ, pe ẹni yoowu ti yoo ba ri ọbabinrin yii, ọkunrin ṣọja naa ni yoo kọkọ ri, Aguiyi Ironsi. Ironsi ni olori awọn ẹṣọ ti wọn n ṣọ Ọbabinrin yii ni gbogbo igba to fi wa nilẹ wa. O ba a duro l’Ekoo, wọn jọ lọ si Ibadan ati Enugu ni, bẹẹ lo jẹ wọn jọ de Kano, wọn si jọ de Kaduna ati Sokoto ni. Nibi yii ni gbogbo agbaye ti kọkọ gbọ orukọ Ironsi, nitori bo ti n kiri yii, bẹẹ naa ni awọn oniroyin agbaye gbogbo n gbe e, ṣe nigba naa, ọpọlọpọ orilẹ-ede lo jẹ Ọbabinrin Elizabeth ni olori wọn, oun lo ni wọn, wọn kan fi awọn oyinbo lati ilu wọn lọhun-un ranṣẹ si awọn orilẹ-ede wọnyi ki wọn maa ṣejọba wọn ni. Gbogbo ibi ti obinrin naa ba si n lọ, bii ẹni pe Ọba gbogbo aye lo n lọ ni, bẹẹ lawọn orilẹ-ede gbogbo yoo si maa royin ibi to ba de lojumọ kọọkan. Nidii eyi, bi wọn ti n darukọ Queen, bẹẹ ni wọn n darukọ Ironsi to n ṣọ ọ.
Lẹyin ti ọba ilu oyinbo lọ, agbega tun bẹrẹ fun Ironsi ninu iṣẹ ologun. Paripari rẹ waa ni pe ni ọdun1960, ogun agbaye kan bẹrẹ ni orilẹ-ede Kongo, ogun ẹni ba laya ko wọ ọ ni, nitori awọn ṣọja kaakiri origun mẹrẹẹrin agbaye ni wọn wa nibẹ, ogun jija si ni iṣẹ ti wọn n lọọ ṣe. Nigba ti wọn waa de oju ogun yii, ti wọn mu ẹni ti yoo ṣe olori ogun gbogbo fun awọn ṣọja agbaye yii, Ironsi to jẹ ṣọja lati Naijiria ni wọn mu, wọn si fun un ni oye tuntun, wọn pe e ni Mejọ-Jẹnẹra loju ogun naa. Lẹyin ti wọn pada ti oju ogun naa de, wọn da a pada si oye Brigedia, nitori pe ẹni to jẹ olori awọn ọmọ ogun pata ni Naijiria nigba naa, oyinbo loun, Mejọ-Jenẹra loye oun naa, ọga meji ko si le wa ninu ọkọ, Mejo-Jenẹra meji ko ni i wa ninu iṣẹ ologun lẹẹkan naa nigba yẹn. Ohun ti wọn ṣe da Ironsi pada sẹyin ree, ti wọn si gbe iṣẹ nla mi-in fun un ko maa ṣe.
Nigba ti oyinbo to waa jẹ olori awọn ṣọja Naijiria n palẹmọ yii, ohun ti awọn ṣọja ati awọn alaṣẹ ilu oyinbo sọ ni pe Naijiria ko ti i ni agbara ati imọ to kun to lati fi ọmọ orilẹ-ede naa ṣe olori ologun, wọn n fẹ ko jẹ oyinbo mi-in ni yoo tun gba a, oyinbo naa yoo si tun ṣe olori ṣọja fun ọdun 1969 si 1970, Naijiria yoo ti dagba to lati ni olori awọn ṣọja ti yoo jẹ ọmọ orilẹ-ede wa gan-an. Nibi yii ni awọn ti wọn n ṣejọba ni Naijiria ti yari nigba naa, awọnTafawa Balewa ti wọn jọ jẹ olori ijọba si sọ pe ko si idi kan ti ọmọ Naijiria ko fi le di olori ologun ilẹ wa. Wọn ni pupọ ninu awọn eeyan yii, ilu oyinbo lawọn naa ti kọṣẹ ologun yii, bẹẹ ni awọn mi-in si ti kawe daadaa ninu wọn. Ati pe ko si bi ọbọ ti ṣe ori ti inaki ko ṣe, pe ko si asiko mi-in to dara ju fun ọmọ Naijiria lati ṣe olori awọn ṣọja tiwa ju asiko yii lọ.
Wọn ni Naijiria ti di ilu olominira, ko si si idi ti ajoji yoo fi tun maa ṣe olori ilẹ wa. Loootọ si ni, ko too di pe a gba ominira ni ọdun 1960, awọn ọga ṣọja ti a ni, bi wọn ba ko mẹwaa kalẹ, awọn ọgọta ni yoo jẹ oyinbo, nitori awọn ọga wọnyi pọ ninu iṣẹ ologun ilẹ wa. Niluu oyinbo ni wọn ti n wa, awọn ni wọn si n kọ awọn ọmọ Naijiria ni iṣẹ ologun. Ṣugbọn lẹyin ominira, wọn din kinni naa ku, to si di pe bi wọn ba ko awọn ọga ṣọja mẹwaa kalẹ, mẹrin pere ni yoo jẹ oyinbo ninu wọn. Diẹdiẹ bẹẹ ni wọn si n ja kinni naa silẹ, ko too waa di ọdun 1965, ti ẹni to jẹ ọga pata fawọn ṣọja n lọ siluu rẹ pada, ti wọn tun waa ni boya Naijiria yoo tun gba oyinbo mi-in ko tun dari awọn ṣọja wọn fun igba diẹ si i. Eleyii ni wọn lawọn ko gba. Ọmọ ilẹ Naijiria lawọn fẹ, awọn ko fẹ oyinbo tuntun mọ. Eleyii lo mu wọn maa wa ẹni ti wọn yoo gbe ipo naa fun laarin wọn.
Diẹ lo ku ki awọn oyinbo yii tun da ija silẹ, ọrọ naa si fẹẹ di ti awọn oloṣelu. Ironsi lo jẹ olori pata fawọn ṣọja, nitori oun ni ipo rẹ ga ju lọ. Ṣugbọn awọn oyinbo kan kilọ fun awọn olori ilẹ Hausa ti wọn n ṣejọba pe eeyan wọn ni ki wọn jẹ ko pọ nibẹ, bi wọn ko ba fi awọn eeyan wọn si i, o le nira diẹ lati paṣẹ bi wahala ba de. Wọn ni ko yẹ ko jẹ ọmọ agbegbe Ibo ni yoo tun di olori ologun, nigba to jẹ awọn ni olori ọlọpaa ati Nefi. Nidii eyi, awọn eeyan yii fi ọgbọn gbe ọmọ Hausa ti oye rẹ ga ju lọ, Maimalari, soke, wọn si ni ko waa di ipo naa mu. Sardauna ni Sokoto ati ọmọ Yoruba kan to wa lọdọ rẹ ti wọn ti jọ mọ ọwọ ara wọn, Ọgagun Ademulẹgun, lawọn fọwọ si i. Ṣugbọn nigbẹyin, awọn ti wọn mọ nipa iṣẹ ologun ati bi awọn ṣọja ti i huwa, ni bi awọn ba fẹ alaafia tootọ, afi ki wọn fi Ironsi ṣe ọga le gbogbo wọn lori.
Bẹẹ ni wọn fa ọrọ naa lọ ti wọn fa a bọ, nigba to si di ọjọ kẹẹẹdogun osu keji ọdun 1965 yii, wọn kede ọkunrin naa gẹgẹ bii olori awọn ṣọja pata. Oun lo gba ipo lọwọ oyinbo, oun si ni ọmọ Naijiria akọkọ ti wọn yoo ni ko waa ṣe olori awọn ṣọja ilẹ wa.