N’Ijan-Ekiti, ọkọ akoyọyọ kọ lu ọmọ iya mẹta, ọkan ku, meji fara pa

 Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

Iku ọmọdekunrin ẹni ọdun mejilaatwọn meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa, to jẹ ọmọ ileewe girama Ayọ Daramọla, to wa ni Ijan-Ekiti, nijọba ibilẹ Gbonyin, nipinlẹ Ekiti, ti da wahala silẹ.

Iṣẹlẹ to waye laaarọ jọbọ, Wesidee, ni deedee aago mẹsan-an aabọ ọhun lo bi awọn ẹgbẹ mọdekunrin to wa ni kilaasi keji nileewe naa ati mlẹbi rẹ ninu ti wọn fi gun le iwọde kan, eyi to da igbokegbodo ọkọ duro loju ọna naa, eyi to fa a ti ọpọlọpọ awn to n rin irinajo ati awọn to n lọ sibi iẹ ko e ri aaye kọja.

Ijamba yii ṣẹlẹ niwaju oko kan ti wọn n pe ni Agọ, ki wọn too de ilu Ijan-Ekitilojuko kan ti ko dara loju ọna naa.

nikan tọrọ naa ṣoju rẹ, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe mdekunrin ti ọkọ akoyọyọ pa yii atawọn meji to ku ti wọn farapa yii je olugbe Agọ, ni oko kan to wa loju na naa, wọn n lọ sileewe laaarọ j iṣẹlẹ yii ni.

O ṣalaye pe ọmọkunrin ti ọkọ akoyọyọ pa yii ati awọn meji yooku ti wn fara pa yii jẹ ọmọ iya kan naa. O ni bi wọn e ri ọkọ akoyọyọ to ko yeepẹ yii ni wọn wọ si pe ko aanu awọn, ko gbe awọn siwaju.

Bi wọn ṣe n lọ ninu irinajo naa ni dẹrẹba ọkọ yii fẹ yẹra fun koto kan to wa loju ọna naa, eyi o mu ki ọkọ akoyọyọ yii takiti, to si ṣubu lojiji.

kan lara awọn ọmọ ileewe yii ni ori rẹ fọka, to si ku lojiji, nigba twọn ko awọn meji to ku lọ silewwosan fun itọju.

Nigba to n sọrọ lori ọrọ naa, Alukoro ajọ ẹṣọ oju popo nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Taiwo Ojo, sọ pe loootọ niṣẹlẹ oun ṣẹlẹ.

O ṣalaye pe awọn meji to ku ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ni wọn ti ge ẹsẹ wọn mejeeji nileewosan ijọba nipinlẹ Ekiti.

Alukoro ajọ oju popo naa sọ pe awọn ẹṣọ oju popo lo l si ojuko naa lati lọ doola mi awọn ọmọleewe yii. Bakan naa lo ni wọn ti gbe oku ẹni kan to ku ninu ijamba naa lọ si ile igbokuu- pam si.

O rọ gbogbo awakọ pe ki wọn maa fi suru wakọ ni gbogbo igba ti wọn ba wa ni oju popo.

Leave a Reply