Nikẹ  fi mọto paayan meji nibi ti wọn ti n ṣewọde SARS l’Ekoo

Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti sọ pe eeyan meji ni wọn ti padanu ẹmi wọn bayii lagbegbe Alagbado, lasiko tawọn ọdọ kan n ṣewọde tako awọn ẹṣọ agbofinro SARS l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, lo ṣalaye ọrọ naa fawọn oniroyin. O ni ere buruku ti obinrin yii, Nikẹ Lawal, ba wọ agbegbe Ikọla, ni Alagbado, lo mu un fi mọto ẹ pa awọn ọdọmọkunrin meji yii, Ojo Azeez, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Yusuf Sodia, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.

Nike to paayan yii, Nọmba 30, Anjọrin, lo n gbe ni agbagbe Aminkanlẹ, l’Ekoo.

Leave a Reply