N’Ikorodu, adigunjale pa baba ọlọdẹ to n ṣọ otẹẹli

Faith Adebọla, Eko

Igbẹ la a fẹ’we, oko la a wa nnkan ọbẹ lọrọ da nigba tawọn afurasi adigunjale kan ya bo otẹẹli Mambillah, to wa niluu Owutu, lagbegbe Ikorodu, loru mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un yii, wọn yinbọn pa Peter, baba ọlọdẹ ẹni ogoji ọdun, to n ṣọ otẹẹli ọhun, wọn tun ṣe awọn oṣiṣẹ ajọ JAMB to gba yara mọju lotẹẹli ọhun leṣe, wọn si ko ọpọ owo ati dukia lọ.
Ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹta ku iṣẹju diẹ lọganjọ oru lawọn igaara ọlọṣa naa de sotẹẹli ọhun, nigba tawọn aladuugbo atawọn alejo to gba yara sotẹẹli naa ti sun fọnfọn.
Ko sẹni to le sọ pato bi wọn ṣe wọle, boya wọn fibọn ja geeti wọle ni o, tabi baba ọlọdẹ naa lo ṣilẹkun fun wọn to ro pe arinrin-ajo ni wọn.
Wọn ni gẹrẹ ti wọn wọle ni wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn si bẹrẹ si i wọ yara kọọkan to wa ninu otẹẹli ọhun, wọn n ji awọn alejo to gba yara sibẹ, wọn n gba dukia ati owo wọn.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ, ṣugbọn ti ori ko yọ, sọ lori ikanni ayelujara Instagiraamu ẹ pe “Aa, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to ko mi yọ o, ẹ wo bi wọn ṣe ba awọn ilẹkun jẹ, ẹ wo bi wọn ṣe fibọn fọ ilẹkun, ẹ wo gbogbo ara ogiri, ko sibi ti wọn o wọ, lati yara kan si ekeji ni wọn wọle, gbogbo eeyan ni wọn ka mọ, ti wọn si gba dukia wa.”
Fidio naa ṣafihan ọkan lara awọn oṣiṣẹ JAMB naa ati awọn mi-in ti wọn fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii. Lara dukia tawọn apamọlẹkun-jaye ẹda naa ji ko ni awọn tẹlifiṣan igbalode ti wọn lẹ mọ ara ogiri, kọmputa agbeletan, owo, goolu ọrun, foonu alagbeeka ati aago ọwọ.
A gbọ pe lati ọjọ meji sẹyin lawọn oṣiṣẹ ajọ JAMB mẹta kan ti gba yara si otẹẹli naa, latari idanwo aṣewọle-si-fasiti to n lọ lọwọ lagbegbe ọhun, eyi ti wọn n mojuto.
Ohun ta a gbọ ni pe bawọn adigunjale naa ṣe ko awọn dukia ti wọn ji ọhun sinu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn gbe wa, ti wọn si fẹẹ maa lọ, baba ọlọdẹ naa gbiyanju lati ṣediwọ fun wọn, ko tete ṣi geeti otẹẹli naa, ni wọn ba tawọ ibọn si i, o si ṣubu lulẹ.
Lẹyin ti wọn ti lọ, awọn oṣiṣẹ otẹẹli naa sare du ẹmi baba ọlọdẹ naa, wọn gbe e digbadigba lọ si ọsibitu aladaani kan to wa nitosi, amọ ko pẹ ti wọn gbe e de’bẹ lo dagbere faye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lọganjọ oru ti iṣẹlẹ naa waye l’Ojule ọgọta, opopona Ọmọdisu, ni Asọlọ-Owutu, n’Ikorodu, lẹnikan ti ta awọn lolobo, bawọn si ṣe n bọ lawọn adigunjale naa bẹ sinu ọko Lexus ti wọn gbe wa, ti wọn fi sa lọ.
“Wọn ja oṣiṣẹ ajọ Joint Admission and Matriculation Board (JAMB) kan, Ọjọgbọn Ọdunsi, to wa ninu otẹẹli naa lole, foonu ẹ meji, kọmputa agbeletan ẹ ati ẹgbẹrun lọna ogun Naira ni wọn ji lọ.
“Wọn tun ji aago, ṣeeni ọrun ati owo awọn oṣiṣẹ JAMB meji mi-in ti wọn jẹ obinrin.
O lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un, ọwọ yoo ba awọn amookunṣika ẹda naa laipẹ.

Leave a Reply