Nilẹ Zambia, eeyan mejidinlọgbọn ko Koronafairọọsi ni kilọọbu kan

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ṣe lawọn alaṣẹ liigi ilẹ Zambia to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ana, sun ifẹsẹwọnsẹ si oni, Sannde, lẹyin tawọn agbabọọlu ati oṣiṣẹ mejidinlọgbọn lati Kilọọbu Forest Rangers ko arun Koronafairọọsi.

Forest Rangers to wa nipo kin-in-ni ni liigi ilẹ naa lo yẹ ko figagbaga pẹlu Zanaco ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ lẹyin ti idaduro ba awọn ifẹsẹwọnsẹ saa yii latari Koronafairọọsi.

Gbogbo kilọọbu mejidinlogun to wa ni liigi naa ni wọn ṣayẹwo, ṣugbọn Forest Rangers ni nnkan yiwọ fun nitori eeyan ọgbọn pere ni ko ni Koronafairọọsi ninu awọn agbabọọlu ati oṣiṣẹ mejidinlọgọta.

Lọwọlọwọ bayii, awọn to ni arun naa nilẹ Zambia din diẹ ni ẹgbẹrun mẹta, nigba tawọn ọgọfa ti dagbere faye.

Nigba ti liigi naa ba bẹrẹ lonii, awọn oluworan yoo lanfaani lati kopa, Zambia ati Tanzania nikan ni wọn si gba eyi laaye.

Tẹ o ba gbagbe, Burundi nikan ni orilẹ-ede Afrika ti ko da awọn ifẹsẹwọnsẹ rẹ duro nitori ajakalẹ arun Koronafairọọsi.

Leave a Reply