N’Ileefẹ, awọn Musulumi atawọn Olórò kọju ija sira wọn, eeyan mẹfa lo fara pa

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

K’onifa o bọ’fa  rẹ, ki Musulumi o sin Ọlọrun rẹ, k’Onigbagbọ o re ṣọọṣi, ẹsin o faja… lorin tawọn baba wa maa n kọ laye atijọ, ṣugbọn o da bii orin ti yipada, ilu naa si ti yipada bayii, pẹlu bi awọn Musulumi niluu Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun, ṣe fẹhonu han lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, lorii bi wọn ṣe ni awọn oloro (Oro Adherents) ṣe kọ lu mọṣạlaaṣi kan to wa lagbegbe Ìlàrẹ́, ti awọn olujọsin mẹfa si fara pa yannayanna.

Gẹgẹ bi awọn Musulumi naa ṣe sọ, wọn ni nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn oloro naa wọnu mọṣalaaṣi ọhun ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ, ti wọn si fiya jẹ awọn ti wọn ba nibẹ.

Yatọ si Imaamu mọṣalaaṣi naa, Abdul-lateef Adediran, ti wọn ṣe lẹse, awọn olujọsin marun-un mi-in tun fara kaasa ikọlu yii.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣalaye pe lasiko ti awọn Musulumi naa n kirun lọwọ ni awọn oloro ya wọnu mọṣalaaṣi naa.

O ni, “Loootọ la mọ pe wọn yoo gbe Oro kaakiri, ṣugbọn a ko da si wọn. Wọn ti kọkọ kọja lagbegbe yẹn ki wọn tun too pada waa ba wa ninu mọṣalaaṣi.

“Baba Imaamu kan tiẹ n beere ohun ti wọn fẹ, ṣugbọn wọn ko jẹ ki ẹnikẹni sọrọ ti wọn fi bẹrẹ si i lu gbogbo wa. Eeyan mẹfa ni wọn gun (stab) ni nnkan, ileewosan kan niluu Ileefẹ la ko gbogbo wọn lọ.”

Laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ti awọn olufẹhonu han naa de aafin Ọọni Ifẹ, wọn sọ fun wọn pe kabiesi ko si nile. Ohun ti awọn Musulumi naa si n tẹnu mọ ni pe gbogbo awọn ti wọn wa nidii iṣẹlẹ naa lawọn agbofinro gbọdọ fi pampẹ ọba mu.

Agbẹnusọ awọn ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe alaafia ti pada sagbegbe naa, iwadii si ti bẹrẹ lati mọ ohun to fa wahala yii.

Bakan naa, Akọwe iroyin fun Ọọni, Ọtunba Moses Ọlafare, ṣalaye pe igbimọ awọn lọbalọba niluu Ileefẹ pẹlu awọn adari ẹsin Musulumi ti da sọrọ naa.

O ni igbe aye irẹpọ ati ifẹ ni awọn Musulumi, Kirisitẹni atawọn elẹsin ibilẹ niluu Ileefẹ maa n gbe lati ọdun to ti pẹ.

Ọlafare ni, “Baba Ọọni n fi asiko yii pe gbogbo awọn ti ọrọ kan lati gba alaafia laaye, ipade ti n lọ lọwọ laarin awọn agbaagba ẹsin lati le yanju ọrọ naa.”

Leave a Reply