N’Ileefẹ, Kọla to fi ibọn halẹ mọ alapata ẹran ti dero kootu

Florence Babaṣọla

Kọla Adekunle, ẹni ogoji ọdun, ti foju bale-ẹjọ lori ẹsun pe o dunkooko mọ ẹmi alapata ẹran kan, Isiaka Giwa, lagbegbe Oke-Ogbo, niluu Ileefẹ.

A gbọ pe lọjọ keji, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni Kọla pade Isiaka laago mejila ọsan, o si sọ fun un pe ti ko ba fun oun ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000), oun yoo yin in nibọn pa.

Inspẹkitọ Emmanuel Abdullahi sọ fun kootu pe Kọla fun Isiaka ni akanti ileefowopamọ Polaris to ni nọmba 3052592304, o si paṣẹ fun un pe ko sanwo naa sibẹ.

Abdullahi fi kun ọrọ rẹ pe iwa ti Kọla hu le da wahala silẹ laarin ilu, o si nijiya labẹ abala ikẹrindinlaaadọrun-un (86) ati ọtalelugba o din mọkanla (249) ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun n lo.

Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan an ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti naa, A. I. Oyebadejọ, fun un ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ati oniduuro meji ni iye kan naa. O sọ pe awọn oniduuro naa gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ, ki wọn si maa gbe lagbegbe kootu.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lo ni ki Kọla pada wa si kootu.

Ninu iroyin mi-in, beeli miliọnu marun-un naira ni adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo fun Uche Chukwuma, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o lu ileeṣẹ Stanley Ginika of Quantum Intervention Limited ni jibiti owo nla.

Inspẹkitọ Elisha Oluṣẹgun sọ fun kootu pe laarin oṣu kejila, ọdun 2018, si oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ni Uche huwa naa niluu Oṣogbo.

Miliọnu mẹfa ataabọ naira (#6.5m) la gbọ pe Uche kọkọ gba nileesẹ naa, pẹlu ele idamẹwaa ninu ida ọgọrun-un to n gun owo naa loṣooṣu, o ti le ni miliọnu lọna ọgọrun-un naira (#102, 575, 000) bayii.

Agbefọba ṣalaye pe Uche ti figba kan sọ pe oun yoo pa Stanley Ginika ko ma baa san owo yẹn mọ, bakan naa lo tun ti figba kan fun Stanley ni ayederu sẹẹki miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna igba naira to jẹ ti ileefowopamọ Stanbic.

Uche sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, agbẹjọro rẹ, Adeyẹmi Adedeji, si ba a bẹ ile-ẹjọ lati fun un ni beeli.

Onidaajọ Ishọla Omiṣade fun olujẹjọ ni beeli pẹlu miliọnu marun-un naira ati oniduuro meji, o si sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii.

About admin

Check Also

Wọn ti tu Oriyọmi Hamzat silẹ lahaamọ

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi …

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: