N’Ileefẹ, Muideen fi oogun oorun sinu ounjẹ fawọn ọmọbinrin mẹrin, ilu Kano ni wọn ti laju

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Muideen Adebisi, yoo rojọ, ẹnu rẹ yoo fẹrẹ bo lagọọ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun to wa bayii, lori iwa laabi kan to hu, ti wọn si tori rẹ mu un. Ẹsun pe o fẹẹ lọọ fi awọn ọdọmọbinrin mẹrin kan ṣowo ẹru lorileede Libya ni wọn fi kan an. Niṣe lo si fi oogun orun sinu ounjẹ fawọn mẹrin ọhun, ni wọn ba sun lọ fọnfọn, wọn ko si mọ ohunkohun ti wọn fi ba ara wọn niluu Kano, nipinlẹ Kano.

Ayẹyẹ ọjọọbi ni Muideen sọ fun awọn ọdọbinrin naa pe oun n ṣe ninu ile rẹ niluu Ileefẹ, to si ni ki awọn ọmọ naa waa ba oun ṣajọyọ. Nigba ti wọn debẹ, o gbe ounjẹ ati nnkan mimu fun wọn, lai mọ pe o ti fi oogun oorun sinu ẹ.

ALAROYE gbọ pe nibi kan niluu Kano, ni iye awọn ọmọ naa too ṣi, ti wọn si laju saye, lasiko yii ni wọn ri i pe awọn kan ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe gba iwe irinna si orileede Libya fun wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe nigba ti iye awọn ọmọ naa ṣi ni mẹta ninu wọn sa lọ, ti wọn si lọọ fi ohun to ṣẹlẹ si wọn to awọn obi wọn leti lori foonu.

O ni bi awọn ọlọpaa ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn bẹrẹ igbesẹ lai fi falẹ, mẹta ninu awọn ọdọbinrin naa si ti wa lọdọ awọn obi wọn, nigba ti wọn ko ti i mọ bi ẹni kẹrin wọn ṣe rin.

Lasiko ti awọn ọlọpaa n fi ọrọ wa Muideen lẹnu wo lo sọ pe oun ko fipa mu awọn ọmọ naa, ṣe ni wọn finnu-findọ sọ pe awọn fẹẹ lọ si orileede Libya lati ṣiṣẹ.

Muideen ni oun ni ẹgbọn kan lorileede naa to ni anfaani iṣẹ wa fun awọn obinrin toun ba ri, ati pe ẹni yẹn lo sọ pe ki oun ko awọn ọmọ naa lọ sọdọ ẹnikan niluu Kano, lati le ba wọn ṣeto irinajo naa.

O ni koda, aimọye awọn ọmọbinrin lawọn ba ninu ile naa nigba ti awọn de Kano, to si jẹ pe eto irinajo si Libya yii naa ni wọn n ba gbogbo wọn ṣe lọwọ.

Amọ ṣa, Ọpalọla sọ pe Muideen yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.

Leave a Reply