Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn afurasi ajinigbe meji kan, Malami Muhammad ati Babuga, niluu Ileefẹ. Ọwọ tẹ awọn eeyan naa lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lẹyin ti wọn ji ọkunrin kan gbe ni Gaa Fulani to wa ni Erefe, lagbegbe Ondo Road, niluu Ileefẹ.
Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe awọn eeyan ọkunrin ti wọn ji gbe ọhun, Muhammes Gembu, ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa ‘C’ Division ni Aganhun, Ileefẹ leti, ti awọn yẹn naa si bẹrẹ igbesẹ kiakia.
Pẹlu ifọwọsowọpọ awọn figilante ti wọn jẹ Fulani lagbegbe naa, ọwọ tẹ Malami ati Babuga lẹyin ti wọn doju ibọn kọ awọn ọlọpaa atawọn figilante.
Ọpalọla ṣalaye pe Babuga fara pa yannayanna lasiko ti ija ibọn nlọ lọwọ, bẹẹ ni wọn ri ẹni ti wọn ji gbe gba silẹ lai fara pa.