Ninu gbogbo awọn oludije sipo aarẹ, emi ni mo kun oju oṣuwọn ju-Amaechi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Minisita feto igbokegbodo ọkọ nilẹ wa, Rotimi Amaechi, ti ni ninu gbogbo awọn oludije sipo aarẹ ti yoo waye lọdun to n bọ, oun loun kun oju oṣuwọn ju lati di ipo naa mu.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo sọrọ naa lasiko to ṣabẹwo saafin Ọọni Ileefẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, lati fi erongba rẹ lati dupo aarẹ Naijiria ninu ibo ọdun to n bọ to o leti.
Amaechi ni oun pinnu lati bẹrẹ abẹwo ati ifọrọlọni lori erongba oun lati dupo aarẹ niluu Ileefẹ, nitori pe ibẹ ni orisun Yoruba. O ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii aala laarin awọn ọdọ ode iwoyi ati awọn agbalagba.
Ọkunrin naa ni lai deena pẹnu, lai si ṣe igberaga si ẹgbẹ APC, PDp tabi awọn ẹgbẹ miiran, oun loun kun oju oṣuwọn ju laarin awọn ẹgbẹ oṣelu to wa nilẹ yii lati di aarẹ Naijiria, oun si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani to fun oun.
Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ yii ni bi wọn ba ti fibo gbe oun wọle gẹgẹ bii aarẹ Naijiria, oun yoo jokoo papọ pẹlu awọn aṣofin lati ri i pe awọn wa ojuṣe fun awọn ọba ninu eto ioṣelu. O ni o ṣe pataki lati maa gba imọran lọdọ awọn ọba alaye yii lati mu eto ijọba awa-ara-wa de ẹsẹ kuku.
Nigba to n fesi si ọrọ rẹ, Ọọni Ogunwusi ṣapejuwe Amaechi gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oloṣelu ilẹ yii to ni anfaani ju lọ. O rọ ọ lati lo anfaani naa lati mu igbe aye rere ba awọn ọmọ orileede Naijiria.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: