Nipa adura gbigba nikan ni Naijiria ko fi ni i lọ soko iparun- Ọṣilẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta           

 Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo, ti rọ awọn eeyan orilẹ-ede yii lati maa gbadura gidi, nitori adura nikan lo le gba Naijiria kuro loko iparun pẹlu awọn iṣoro to n koju awọn eeyan kiri orilẹ-ede yii.

Ilu Abẹokuta ni Ọṣilẹ ti sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa ayẹyẹ ọdun kejilelọgbọn to de ori aleefa ọba.

Kabiyesi sọ pe, ‘A ti mu’nu bi Ọlọrun pupọ, to bẹẹ to jẹ ko bikita nipa wa mọ, nitori a ti kuna. Ṣugbọn ti a ba le gbiyanju, ti a pada sọdọ Ọlọrun, nnkan  yoo daa fun wa pada.

‘’Bi nnkan ṣe n lọ yii, Ọlọrun nikan  lo le ran wa lọwọ nipasẹ adura ti a ba n gba si i. A ko tẹle ilana Ọlọrun ninu awọn ohun ti a n ṣe, ohun to n fa iṣoro niyẹn. Ṣugbọn nipa adura gbigba nikan ni Naijiria ko fi ni i lọ soko iparun’’

Leave a Reply